Tí a bá ń sọ̀rọ̀ orílẹ̀ èdè tí Olódùmarè kẹ́ pẹ̀lú ohun àlùmọ́ọ́nì lórísirísi ní àgbáyé, ipò kíní ni orílẹ̀ èdè Congo wà, ṣé láìpẹ́ yìí ni a rí fọ́nrán kan lórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí a ti rí ọkùnrin òyìnbó kan pẹ̀lú àwọn òkúta kan tí ó ń ṣe àyẹ̀wò rẹ̀, bí arákùnrin yìí sì ti ń fi òkúta méjì kan ara wọn bẹ́ẹ̀ ni iná sì ń jáde níbẹ̀, ọkùnrin náà tún tẹ̀síwájú nípa fífi okùn amúnáwá kan ara òkúta náà ni iná sì ń tàn lára gílóòbù tí ó fi ń ṣe àyẹ̀wò ọ̀hún.
Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú pé, bí orílẹ̀ èdè Congo ṣe ní oríṣiríṣi ohun àlùmọ́ọ́nì tó, bẹ́ẹ̀ni ìṣẹ́ àti ìyà ń báwọn fínra, nítorí pé àwọn amúnisìn ni wọ́n ń ṣe àkóso orílẹ̀ èdè wọn.
Ṣèbí bí Olódùmarè ṣe kẹ́ Orílẹ̀ èdè Congo yí náà ló ṣe kẹ́ àwa náà ni ilẹ̀ Yorùbá pẹ̀lú oríṣiríṣi ohun àlùmọ́ọ́nì ṣùgbọ́n tí àwọn amúnisìn àti àwọn olóṣèlú apanilẹ́kún jayé ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà tí a ti jáde kúrò ń kó gbogbo rẹ̀ tí wọ́n sì ń pin láàárín ara wọn, tí wọ́n wá ń fi ebi pa àwọn ará ìlú.
Àwọn ni wọ́n ń fún àwọn orílẹ̀ èdè tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wọ́n ní iná mọ̀nàmọ́ná, ṣùgbọ́n àwọn ará ìlú wọn kò rí iná lò. Ìlú tí owó oṣù òṣìṣẹ́ kò lè ra àpò ìrẹsì kan, tí àwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì ń kú ikú àìtọ́jọ́ látàrí àìrí ẹ̀tọ́ wọn gbà láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn, mélòó la fẹ́ kà nínú eyín adépèlé ìlú Nàìjíríà.
Ṣùgbọ́n àwa ọmọ Yorùbá dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìran Yorùbá fún ìfẹ́ ìran wọn tí wọ́n ní, ti wọ́n sì lo oore ọ̀fẹ́ tí Olódùmarè fún wọn láti gba ìran wọn kúrò lóko ẹrú.
Nítorí náà, gbogbo àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a fi ọkàn wa balẹ̀, Olódùmarè ti gbà wá ní àgbàtán kúrò nínú oko ẹrú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà, ìran Yorùbá kò sì ní padà sẹ́yìn mọ́ láíláí.