Ní ìlú tí ó fi ẹ̀gbẹ̀ ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà, ọ̀kan lára àwọn omọ ẹgbẹ ìgbìmọ̀ ọrọ̀ ajé ti ààrẹ wọn, Tinubu gbékalẹ̀ sọ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe àgbéwọlé epo lati ìlú Malta, Russia ní ọ̀nà àìtọ́ lọ sí ìlú wọn, Naijiria. Olórí ìlú Naíiìrìa.
Ọ̀gbẹ́ni Bọ́lá Tinubu ya ìgárá ọlọ́ṣà tí ó ń kó owó epo jẹ, tí ó sì ń fi ìyà jẹ àwọn ará ìlú wọn, nígbàtí Aliko Dangóte kó wọn sìta bí ọmọ-tuntun pẹ̀lú ọ̀gá ilé-epo, Mẹlẹ Kiyari ni àwọn àṣírí ń tú.
Ohun tí a fi ń sọ̀rọ̀ nípa ìlú yìí ni bí wọ́n ṣe ń tẹ̀síwájú láti máa jẹ gàba lórí orílẹ̀-èdè wa, èyí sì lòdì sí òfin àgbáyé, bìòtijẹ́ ó hàn sí wọn gbangba pé gbogbo àgbáyé mọ̀ pé ilẹ̀ Yorùbá tí kúrò lára ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà yìí láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun tí a sì ti búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wa ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣèjọba orílẹ̀-èdè wa láti ọjọ́ náà.
Ìjọ̀ba ilẹ̀ Yorùbá kò ní fi ojú rere wo iru àwọn ìwà olè jíjí ohun àlùmọ́nì àti owó ará ìlú báyìí ní Orílè Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, òfin tó múná d’óko, tí kò ṣe ojúsàájú enikan kan ni òfin wa, láì pẹ́ jọjọ, a ó palẹ̀mọ́ àwọn olè, agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, ìtura yíò wá dé fún gbogbo wa ní D.R.Y.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- DAPO ABIODUN Ń FI ÀRÉKÉREKÈ TA ILẸ̀ D.R.Y.
- ỌMỌ YORÙBÁ, Ẹ KÍYÈSÁRA!
- BILL GATES, ÒṢÌṢẸ́ ÀṢÌTÁÁNÌ
- ÒGO ỌLỌ́RUN NÍNÚ ỌMỌ YORÙBÁ
- ỌWỌ́ TI TẸ KUNLE POLLY