Newest Nation in the world, Youngest nation in africa - the democratic republic of the Yoruba

Èkínní, ó ní kí o gba Ìtàn wọn kúrò l’ọwọ́ wọn, kí wọn mọ́ ṣe mọ Ìtàn ìran wọn mọ́!

Èkéjì, ó ní kí o gba Èdè wọn l’ọwọ́ wọn; kí wọn má ṣe lè lo èdè wọn mọ́!

Ẹ̀kẹ́ta, ó ní kí o gba Ìronú làákàyè wọn l’ọwọ́ wọn.

Ó tún wá sọ wípé, Ìrònú làákàyè wọn yi tún pín sí ọ̀nà mẹ́ta o; ó ní, Èkínní, àwọn àṣà tí ó gbé ìran náà ró; Èkéjì, àwọn ohun tí ó jẹ wọ́n l’ogún gẹ́gẹ́bí ìran; àti Ẹ̀kẹ́ta, àwọn Ètò Ìlàná fún Ìgbé Ayé wọn gẹ́gẹ́bí Ìran.

Ó ní tí o bá ti gba àwọn nkan wọ̀nyí l’ọwọ́ wọn, ìwọ wá fi Ìtàn tìrẹ rọ́’pò tiwọn; kí o sì fi èdè tìrẹ rọ́’pò tiwọn, bẹ́ẹ̀ náà ni kí o fi àṣà rẹ, àti ohun tí ó jẹ ìran tìrẹ l’ogún, pẹ̀lú ètò ìlànà fún ìgbé ayé ìran tìrẹ, kí o fi rọ́’pò tiwọn, kí o sì mú wọn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó jẹ́ ti ìran tìrẹ wọ̀nyí, kí wọn má ṣe ṣe ohun tí ó jẹ́ ti ìran tiwọn mọ́.

Related News: Ẹrù ìjọ̀gbọ̀n ni ó nwọ’lé sí Ìlẹ̀ Yorùbá yío, Ẹ ṣọ́’ra
Related News: Ọmọ Yorùbá, Ẹ Ṣọ́’ra! àwọn ọmọ Ígbò ntú ní ọ̀pọ̀ yanturu wa sí ìlú Èkó

O ní, tí o bá ti lè ṣe àwọn nkan wọ̀nyí, kò sí ọ̀nà tí àwọn ìran yẹn lè gbé e gbà o, ẹrú rẹ ni wọn ó máa ṣe.

Ọmọ Yorùbá, njẹ́ nkan tí Màmá, Onítirí-Abíọ́lá ti nsọ fún ìran Yorùbá l’ati ìgbà dé ìgbà kọ́ ni eléyi?

Ẹ jẹ́ kí á mú ara wa kúrò nínú oko ẹrú pátápátá; ẹ jẹ́ kí á mọ òtítọ́ Ìtàn Ìran Yorùbá; kí á sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lo èdè wa láì tún b’ojú wo ibi míran. Bẹ́ẹ̀ náà ni o, ẹ jẹ́ kí á dìrọ̀ mọ́ àṣà wa, àṣà ìran Yorùbá, kí àwọn ohun tí ó jẹ ìran Yorùbá l’ogún ó jẹ́ ohun tí ó máa jẹ́ ìfẹ́ ti wa bákannáà; kí Ètò Ìlànà àdáyébá fún Ìgbé Ayé Ìran Yorùbá ó sì jẹ́ ohun tí a mọ́ ọ fà mọ́’ra gidi fún ìgbélé’kè ìràn wa! A kò ní ọ̀nà míràn mọ́ o!