Ìlú tí ó f’ẹ̀gbẹ́ tì wá, èyíinì, agbésùnmọ̀mí ìlú, Nàìjíríà, èyí tí ó sì tún jẹ́ wípé, l’ọwọ́l’ọwọ́ báyi, ó nfi ìwà ipá jẹ gàba l’orí ilẹ̀ wa, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè máa ràn wá l’ọwọ́ l’ati lé pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ Yorùbá, ní àìpẹ́ àìjìnnà, òun ni a ti gbọ́ o, wípé, Ìjọba Ìpínlẹ̀ kan tí a mọ̀ sí Ìpínlẹ̀ Sokoto ní’bẹ̀, ti sọ wípé, Sultan ìlú Sokótó ọ̀ún kò ní agbára kankan rárá o, l’ati yan ẹnik’ẹni sí ipò kankan, ìbáàṣe gẹ́gẹ́bí olórí agbègbè tàbí olórí abúlé (baálẹ̀).

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ọ̀rọ̀ yí wá’yé l’atàrí awuyewuye kan tí ó ti nlọ̀ fún ọjọ́ mélo kan, èyí tí àwọn kan tí nfi lé’de wípé, ó dàbí ẹni wípé ìjọba Sókótó ọ̀ún ní ìlú Nàìjíríà fẹ́ yọ Sultan náà fún’ra rẹ̀ kúrò l’orí oyè; ṣùgbọ́n èyí tí ó dá wa l’ojú dáradára ni wípé, gẹ́gẹ́bí ìròhìn tí ó já’de l’orí ayélujá’ra ní ọ̀sẹ̀ tí a wà nínú rẹ̀ yí ṣe sọ, ìjọba ìpínlẹ̀ Ṣókótó náà ní’bẹ̀, ti wá sọ o, báyí, wípé, Sultan ìlú Ṣókótó, ní’bẹ̀, kò ní agbára kankan, rárá, l’abẹ́ òfin ìlú wọn – èyíinì, òfin (Constitution) ìlú Nàìjíríà – Sultan kò ní agbára kankan l’ati fi ẹnik’ẹni sí ipò kankan, àti wípé, òfin (Constitution) ìlú Nàíjíríà, èyíinì, ìlú tí a ti já’de kúrò nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣì nfi ipá dúró s’orí ilẹ̀ wa; wípé òfin Nàìjíríà wọn l’ọhún sọ, gàdàgbà gadagba, ní orí kárun àti ẹsẹ̀ kéjì òfin náà, wípé, agbára l’ati yan’ni sí’pò nínú ìpínlẹ̀ k’ipínlẹ̀ nínú Nàìjíríà, gómìnà ìpínlẹ̀ náà nìkan, l’ayé, ni ó ní agbára bẹ́ẹ̀!

Ṣé, èyí pàápàá, tú’mọ̀ sí wípé, Sultan fún’ra rẹ̀ tí ó jẹ́ ọba ìlú Ṣókótó, abẹ́ gómìnà ni Sultan fún’ra rẹ̀ wà o! àti wípé, ẹnik’ẹni kò lè jẹ oyè Sultan ìlú Ṣókótó tàbí jẹ ohun tí a npè ní Ọba kankan ní ìlú Nàìjíríà, láì ṣe wípé gómìna ìpínlẹ̀ tí ọba náà wà ni ó fi ọba fún’ra rẹ̀ s’orí oyè, àti wípé ọba pàápàá kò tún ní agbara l’ati yan ẹnik’ẹni sí ipò! Gómìnà nìkan ni ó lè yan ènìyàn sí ipò.

Sultan Ìlú Sókótó, Kò Ní Agbára Kankan O, L'áti Fi Ẹnik'ẹni J'oyè: Ìjọba Ìpínlẹ̀ Sókótó Ní Ìlú Nàìjíríà L'ó Sọ Bẹ́ẹ̀!

Kọmíṣánnà fún ètò Ìgbẹ́jọ́ ní ìpínlẹ̀ Ṣókótó ní ìlú t’ó wà l’ẹgbẹ́ wa, èyíinì, Nàìjíríà, Agb’ẹjọ́rò Nasiru Binji, ni ó sọ ọ̀rọ̀ sí’ta l’orí awuyewuye náà, tí ó sì sọ wípé, òfin kan tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ṣókótó fún’ra rẹ̀ ní, èyí tí ó sọ wípé ọba ìlú Ṣókótó, èyíinì, Sultan, lè yan àwọn bí baálẹ̀ l’abẹ́ rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti sọ fún gómìnà kí ó tó fi baálẹ̀ náà sí’pò, tí gómìnà sì ti fi òntẹ̀ lùú wípé kí Sultan ó fi baálẹ̀ náà s’orí oyè, Agb’ẹjrò Binji sọ wípé òfin náà fún’ra rẹ̀ kò l’ẹsẹ̀ nlẹ̀ rárárárá, nítorí wípé ó tako kònkárí òfin Nàìjíríà tí ó sọ wípé gómìnà ìpínlẹ̀ NÌKAN ṢOṢO ni ó ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ilú nàìjíríà láti fi ẹnikẹ́ni sí ipò kankan ní ìpínlẹ̀ náà.

Gbogbo ìwọ̀nyí túmọ̀ sí wípé, láì sí wípé gómìnà fi ènìyàn j’oyè ní nàìjíríà, ẹnikẹ́ni kò leè fi ẹnikẹ́ni s’orí oyè ní ìlú tàbí ìletò kankan ní Nàìjíríà. Àti wípé, èyí túmọ̀ sí wípé, tí gómìnà kò bá fẹ́ fi ẹnikẹ́ni s’orí oyè, ní ìlúk’ilú tí ìbáàwù k’ó jẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà, ẹnik’ẹni kò ní sí l’orí oyè ní ìlú yẹn náà nìyẹn! Kíni gbogbo eléyi túmọ̀ sí? Ó túmọ̀, gedegbe, sí wípé, ní ìlú tí a ti já’de kúrò nínú rẹ̀, èyíinì, Nàìjíríà, kò sí nkankan tí ó njẹ́ Ọba!

say no to gmo foods, seed, crop. yoruba warns african

Tí gómìnà bá kàn wòó wípé ó wu òun gẹ́gẹ́bí ẹnikan, wípé kí wọ́n máa pe ẹnìkan ní ‘ọba’ ní ìlú ibìkan, á fi ẹni tí ó bá fẹ́ sí’bẹ̀; ijọ́ tí ó bá dẹ̀ ti ri wípé òun kò ní’fẹ́ sí wípé kí wọ́n pe ẹnik’ẹni l’ọba ní’bẹ̀, gómìnà náà á tún gbé ìgbésẹ̀ wípé kò sí ọba níbẹ̀!

Èyí tí ó tú’mọ̀ sí wípé, òfin ìlú nàìjíríà kò ní àyè kankan fún ohun t’ó njẹ́ ‘ọba.’ Tí ó bá wu gómìnà, ó lè fi ẹnikẹ́ni sórí oyèk’oyè tàbí sí ipòk’ipò tí ó bá wùú nínú ìlúk’ilú, ó sì lè pèé ní orúkọk’orúkọ t’ó bá wùú; tí kò bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, kò fẹ́ bẹ́ẹ̀ nìyẹn!

Èyí ni ó wá fi hàn wá, gbangba, báyi, wípé, bí ó ṣe rí gan-an ni Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Àbíọ́lá, ìránṣẹ́ Olódùmarè sí ìran Yorùbá, bí ó ṣe rí gan-an ni wọ́n ti máa nsọọ́, wípé, kò sí nkan t’ó njẹ́ ọba kankan ní ìlú nàìjíríà! Nítorí èyí, ẹ bá wa sọ fún gbogbo àwọn t’ó sọ wípé àwọn D.R.Y l’ó yọ ọba; ẹ bá wa sọ fún wọn wípé ẹnu wọn nrùn o! Kò sí nkan t’ó kan D.R.Y nínú yíyọ ọba; D.R.Y kàn fi tó yín l’etí ni, wípé, tẹ́lẹ̀ntẹ́lẹ́rí, kò sí nkan t’o njẹ́ ọba ní ìlú Nàìjíría! Nàìjíríà l’ó yọ yín o! àwa náà ò dẹ̀ fẹ́’yin.