Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ọmọ Yorùbá, ẹ jọ̀wọ́, etí yín mélo o! Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ wípé ayédèrú óògùn ara-ríro, paracetamol, ti wà nígboro o! – èyí tí ó sì jẹ́ wípé, nṣe ni ó máa nba àgọ́ ara ènìyàn jẹ́, pátápátá, títí dé gbogbo ibi kọ́lọ́fín ara, tí ẹni náà kò ní le jáde sí àwùjọ, látàrí bí ara rẹ̀ ṣe máa so’kókó, títí dórí ahọ́n, tí ara á ju, títí dé abẹ́, tí kò sì níí ṣeé fi ojú wò rárá: àtọkùnrin àtobìnrin ni ayédèrú paracetamol yí máa ba ìbálòpọ̀ wọn jẹ́, látàrí bí gbogbo ìdí wọn ṣe máa gbàbọ̀dè.

 

Paracetamol Burúkú Wà Níta O! Ẹ Má Ṣe Bá Wọn Lòó!

Ẹ jọ̀wọ́, ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ ṣọ́ra fún ayédèrú paracetamol yí o! Ohun tí wọ́n kọ sí ara èyí tí wọ́n fi àwòrán rẹ̀ ṣọwọ́ sí akọ̀ròyìn wa, lọ báyi: PARACETAMOL TABLETS IP, P-500

Paracetamol Burúkú Wà Níta O! Ẹ Má Ṣe Bá Wọn Lòó!

Ká Ìròyìn Síwájú sí: