Bí ẹ̀mí bá gùn, báà kú, ire gbogbo ni í ṣé ojú ẹni
Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni ọmọ Yorùbá ti jẹ́ ohun ìríra fún Òyìnbó Amúnisìn, tí ó fi jẹ́ pé, lábẹ́ ìṣàkóso àwọn amúnisìn wọ̀nyí, ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe fún àwọn ẹ̀yà tó wà nínú nàìjírà nigbà náà lọ́hun, ti Yorùbá ni wọ́n máa nṣe ní péréte.
Gẹ́gẹ́bí àpẹẹrẹ, ní ẹgbàá ọdún ó dín márun-dín-lọ́gọ́ta, títí lọ bá ẹgbàá ọdún ó dín márun-dín-láadọ́ta, èyí tí ó jẹ́ àkókò ọdún mẹ́wa, iye tí ìjọba amúnisìn fi sílẹ̀ fún ìdàgbàsókè àti ìgbé-ayé-rere ará-ìlú jẹ́ ẹgbẹ̀rún márun pọ́n-ùn ó dín-ní ọ̀ọ́dúnrún ó dín-ní-àádọ́ta fún aríwá ibi tí wọ́n pè ní Nàìjíría, tí èyí tí wọ́n fún ìlà-óòrùn wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó dín-ní-ọ́dúnrún ó dín-ní àádọ́ta pọ́n-ùn, ṣùgbọ́n tí ti ilẹ̀ Yorùbá (èyí tí wọ́n pè ní ìwọ̀-oòrùn nàìjíríà nígbà náà lọ́hun) jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta pọ́n-ùn péré!
Èyí túmọ̀ sí pé iye tí wọ́n fún Yorùbá dà bíi ìdá-mẹ́fà iye tí wọ́n fún Íbò; iye ti wọ́n fún Yorùbá sì jẹ́ bíi ìdá-mẹ́wa iye tí wọ́n fún ilẹ̀ àwọn Hausa.
Kíni a fi ṣe wọ́n gan-an? Ọ̀rọ̀ olófo tó nbínú ológo ni o! Àwọn amúnisìn ọ̀ún kórira ọmọ Yorùbá ṣùgbọ́n wọ́n fi àwọn Hausa ṣe ọ̀rẹ́, tí a dẹ̀ mọ̀ pé àwọn Fúlàní gan-an gan ní wọ́n njẹgàba lé àwọn Hausa lórí; nítorí èyí àwọn Fulani gan ni òyìnbó amúnisìn fi ṣe ọ̀rẹ́ níbi tí wọ́n pè ní Nigeria, pé kí wọ́n máa jẹ gàba lórí ẹni tókù.
Gẹ́gẹ́bí a ṣe gbọ́, tí oyìnbó Harold Smith fún’ra rẹ̀ sọ, ó ní àwọn sọ fún Azikiwe pé àwọn Emir Fulani ni agbara Nigeria máa wà lọ́wọ́ ẹ̀; abájọ tí ó fi jẹ́ pé, kí ọ̀rọ̀ ó tó dé’lẹ̀, àṣìtáánì Sokoto á ti fò fẹ̀rẹ̀ máa bá ọba ìlú Gẹ̀ẹ́sì sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n, irọ́ ni wọ́n npa! A ti jáde báyi kúrò nínú Nàìjíríà!
Èyí tí ó ba ni nínú jẹ́ jù ni pé, Amúnisìn Lugard fún’ra rẹ̀ sọ fún àwọn ọgá rẹ̀ ní ìlú Gẹ̀ẹ́sì nígbà náà l’ọhún, tí ó kó àríwá papọ̀ mọ́ gúùsù, tí ó so irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́, ní àádọ́fà ọdún s’ẹhìn báyi, ó ní òun ṣe eléyi, kí àwọn le lo owó tí wọ́n nrí láti ìsàlẹ̀ (èyí tí ó sì jẹ́ pé lọ́dọ̀ Yorùbá ni wọ́n ti nri), kí àwọn lè fi ṣe ìdàgbàsókè sí àríwá Nàìjíríà ìlú àdàmọ̀dì wọn ọ̀ún! Kíni eléyi túmọ̀ sí?
Ó túmọ̀ sí pé ọ̀dọ̀ wa ní ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti nrí owó tó pọ̀ jù, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ọ̀rọ̀ ìdàgbàsókè àti ìgbé-ayé-rere ará ìlú, iye tí wọ́n á fún agbègbè Íbò á jẹ́ ìlọ́po mẹ́fà iye tí wọ́n á fún àwa Yorùbá; tí iye tí wọ́n á fún àwọn Hausa pẹ̀lú ọ̀gá wọn Fùlàní á sì jẹ́ ìlọ́po mẹ́wa ohun tí wọ́n á fún wa ní ilẹ̀ Yorùbá! Hàà! Kíni ẹ̀ṣẹ̀ wa gan?!
Ṣé ẹ rántí pé, òyìnbó Harold Smith yẹn sọ pé bàbá wa Awólọ́wọ̀ kìí ṣe ẹni tí ó mọ èrú ṣíṣe, ìdí nìyẹn tí wọn ò lè pàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún ìwà amúnisìn wọn, ṣùgbọ́n àwọn lè rí Azikiwe lò torí ó jẹ́ ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ kò mọ́!
Bí àwọn òyìnbó amúnisìn yẹn ṣe ṣe, nígbà náà l’ọhún, tí wọ́n á fún àwọn Hausa pẹ̀lú Fúlàní ọ̀gá wọn ní ìlọ́po MẸ́WA ohun tí wọ́n nfún Yorùbá, tí ó sì jẹ́ pé ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ti nrí èyí tí ó pọ̀jù nínú ọrọ̀ náà, ìyẹn náà ni wọ́n fi lé àwọn ọ̀rẹ́ wọn Fulanió lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé, wọ́n á máa kó ọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n bá ti fẹ́ wá pín owó fún àwọn ìpínlẹ̀, táṣẹ́rẹ́ nínú ohun tí wọ́n tí kó ní ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n máa dá padà fún wa, ṣùgbọ́n wọ́n á ti fún àwọn tó pera wọn ní olóṣèlú ní ilẹ̀ Yorùbá, àti àwọn tí ó pera wọn ní Ọba, ní owó “gbà, má ṣe sọ̀rọ̀,” àwọn yẹn á wá máà tan ọmọ Yorùbá jẹ!
Nítorí náà, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ o! Kí wọ́n máa fi ọwọ́ rọ́ àwa Yorùbá sẹ́hìn, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ rárá: àwọn òyìnbó amúnisìn ló ti fi ìpìlẹ̀ yẹn lélẹ̀, tí àwọn Fulani dẹ̀ ntẹlée, pé kí wọ́n máa lo àwa Yorùbá, kí wọ́n máa gbà lọ́wọ́ wa, láti fi kẹ́ àwọn Hausa-Fulani àti àwọn tó kù!
Ṣùgbọ́n, títí láí, ni a ó máa rántí ọjọ́ náa l’ọhún – ogúnjọ́, oṣù bélú, ẹgbàá ọdún-ó-lé-méjìlélógún, tí Olódùmarè lo Ìyá wa Modúpẹ́ Onítirí aya Abíọ́lá, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, láti kó wá kúrò ní oko ẹrú ọ̀ún, nípasẹ̀ ìkéde Omìnira Yorùbá kúrò nínú ìlú amúnisìn, Nàìjíríà, tí a dẹ̀ ti di Orílẹ̀-Èdè Aṣèjọba-Ara-Ẹni, pẹ̀lú gbígbé Ìjọba wa wọlé ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún tí a wà nínú rẹ̀ yí!
- Ẹ̀KỌ́ PÀTÀKÌ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ ÌLÚ GẸ̀Ẹ́SÌ: ỌMỌ YORÙBÁ, Ẹ MÁA BỌ̀ N’LÉ
- ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN MPOX: OLÓRÍ ÀJỌ ÌWÒSÀN ÀGBÁYÉ SỌ̀RỌ̀ SÍTA
- KÍ NÀÌJÍRÍÀ Ó KÚRÒ LÓRÍ ILẸ̀ YORÙBÁ NI KÓKÓ
- ÈÈMỌ̀ WỌ̀LÚ NÀÌJÍRÍÀ! ÀWỌN Ọ̀DỌ́MỌBÌNRIN ŃTA ẸYIN INÚ WỌN LÁTI RA IRUN ÒYÌNBÓ NÍTORÍ OGE.
Gbogbo àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a máa yọ̀, kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè, kí á sì máa gbáradì fún àjọyọ̀ náà, nígbàti Ọlọ́run bá ti ràn wá lọ́wọ́, ní àìpẹ́, tí a ti rí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá wa, tí wọ́n ti sá kúrò lórí jijẹgàba lé orí ilẹ̀ wa. Ní àìpẹ́ ni o.