A rí ìròyìn kan tí ó jáde lori ẹ̀rọ ayélujára pe, ọwọ́ àwọn agbófinró tí ìlú arufin Nàìjíríà tí wọ́n taku sí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Ogun, ti tẹ ògbóńtagìrì elẹ́gbẹ́ òkùnkùn kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adekunle Adebanjo, tí wọ́n máa ń pè ní “Kunle Polly“, fún pé ó lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn ipànìyàn kan, ìyẹn tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn míràn tí wọ́n jọ ń ta kàǹgbọ̀n ní Ìjẹ̀bú Òde. Ṣùgbọ́n báwo ní ìlú arúfin ṣe fẹ́ ṣe ìdájọ arúfin? Ṣẹ̀bí àwọn náà ni wọn sọ àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí di ìdàkudà.

A ṣe àkíyèsí pé ìpínlẹ̀ Ogun ni àwọn ògbóǹtagìrì elẹ́gbẹ́ òkùnkùn àti àwọn agbéni pa’wó fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ sí jùlọ nínú àwọn ìpínlẹ̀ meje tí ó jẹ́ ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.

Dapọ Abiọdun, ìkìlọ nlá rèé fún ìwọ ati àwọn tí ẹ̀ jọ ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, kí ẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa báyìí, nítorí, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kìí ṣe ará Nàìjíríà rárá, ẹ fi àyè sílẹ̀ kí àwọn Olórí Adelé wa àti àwọn Adelé wa yókù lè tètè tèsíwájú láti máa ṣe àtúnṣe gbogbo nkan tí ẹ ti bàjẹ́ láti àìmọye ọdún yìí wá.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Tí a bá ní kí a wòó ní ọ̀nà míràn, a máa rí wípé, ọwọ́ tí ó di’lẹ̀ ni sátánì máa ń bẹ̀ ni’ṣẹ́, ẹyin ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí ẹ takú sí orí ilẹ̀ wa, ẹ ó ní ẹnu ọ̀rọ̀ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́, nítorí, ẹ ò rí iṣẹ́ fún wọn ṣe fún àìmọye ọdún sẹ́yìn.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ fi olú ilé-iṣẹ́ wa sí’lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ méjèèje tí ó jẹ́ ti Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, kí ẹ tó ba ayé àwọn ọ̀dọ̀ wa jẹ́ tán.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: AGBÉSÙNMỌ̀MÍ S’ỌṢẸ́ FÚN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ

 Màmá wa, Olóyè  Ìyá Àfin Modupeola Onitirí-Abiola máa ń sọ fún wa wípé, gbogbo àwa ọmọ Aládé ni a ní ògo, tí a sì máa rí ògo náà lò, nítorí náà, àwa Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P.), ẹ jẹ́ kí á dúró de àsìkò oríire wa tí a ti tò sí ẹnu ìlẹ̀kùn láti máa wọlé lọ́kòòkan kí á sì máa gba ẹ̀tọ́ wa.

Gbogbo irú àwọn ìwà ọ̀daràn bí irú èyí tí a ń sọ yìí kò ní lè bá  wa gbé orí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y.), ẹ jẹ́ kí oníkálukú lọ ki ọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ aṣọ o.