OWÓ DỌ́LÀ AMERIKA JẸ́ OHUN ÌJÀ OLÓRÓ FÚN ÌJẸGÀBA LÓRÍ ÀGBÁYÉ

Owó dọ̀là ti ilẹ̀ Amerika ni ohun ìjà tí ó nípọn jù tí orílẹ̀-èdè Amẹrika ńlò láti jẹ gàba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ìyókù.

Wọ́n gbe l’árugẹ, wọ́n sì ṣàpọ́nlè rẹ̀ bí ohun kòṣeémánǐ fún gbogbo àgbáyé pátápátá, ní pàtàkì jùlọ – àwọn orílẹ̀-èdè tí ó  ṣẹ̀ṣẹ̀ ńdàgbà sókè.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Wọ́n gbé owó dọ́là jáde bí ohun èlò ìràlọ́wọ́ fún àwọn orílẹ́-èdè tí kò tíì jẹun k’ánú dáadáa. Wọ́n á sì sọ fún àwọn orílẹ̀-èdè akúùṣẹ̀ẹ́ wọ̀nyí pé àwọn ṣetán láti bá wọn ṣe ojú ònà tí ó yọ̀ kùlùlù, ètò ọrọ̀ ajé tí ó jíire àti àwọn ohun amáyédẹrùn míràn.

Bẹ́ẹ̀ni wọ́n á sì rọ àwọn olórí orílẹ̀-èdè wònyí láti wá yá owó lódò wọn, ṣùgbọ́n olórí ìjọba tí ó bá kọ̀, wọ́n á ṣètò fún ìdìtẹ̀ gbà’jọba lọ́wọ́ rẹ̀. Nínú ṣíṣe èyí wọ́n á dàbí ẹnití ó pé ajá kì ó wá jẹun tí óò sì tún mú ẹgba dání. Ṣé irúfé oúnjẹ béẹ̀ á dùn jẹ f’ájá?

Àwọn ṢÙGBỌ́N ti ó le koko ní wọ́n máa ńgbé sórí irú ẹ̀yáwó béẹ̀. Wọ́n lè sọ pé kí àwọn olùyáwó bẹ́ẹ̀ gbé iṣẹ́ ṣiṣe àwọn ńkan amúlùdúǹn bíi ọ̀nà,, omi, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ fún alágbàṣe ìlú Amerika tàbí Europe nitoripe akọ́ṣẹ́mọ̀ṣẹ́ niwọ́n. Kò tán síbẹ̀ o.

Wọ́n tún ṣe àgbékalẹ̀ Àjọ Báǹnkî Àgbáyé láti máa yá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ńdàgbàsókè lówó ní èlé owó gọbọi ní òdiwọǹ owó dọ́là tí ó sì ṣe bẹ́ sọ owó dọ́là di gbajúgbajà káàkiri àgbáyé.

Wọ́n tún máa ńgbà àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ńdìde ìdàgbàsókè nímọ̀ràn wípé kí wọn sọ awọn ilé iṣẹ́ ọrọ̀ ajé wọn tí ó làmílaka di ti aládàníi, ki wọ́n sì tún yọ ọwọ́ kúrò nínú ìrànwọ́ epo rọ̀bì.

Bẹ́ẹ̀kẹ̀re, èyí túbọ̀ ń tì wọ́n sínú rọ̀foọ̀rọ́fọ̀ ipò òsì sí ní. Ni áfìkúń, wọn í sì tún gbà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti yá lówó níyànjú wípé kí wọn dín iṣẹ́ àgbẹ̀ àrojẹ kù, kí wọ́n sì tẹra mọ́ gbígbin igi owó l’óko ẹgàn bíi kòkó ati kọfí. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ebi á wòlú.

Àwọn ará ìlú á bẹ̀rẹ̀ síí  máa wo ojú àwọn ará òkè òkun fún oúnjẹ.

Gegebi orílẹ̀-èdè, àwa ọmọ Democratic Republic of the Yoruba kò lè ṣe ẹrú l’ábẹ dọ́là nitoripé Ọlọrun tí fún wa ni ọ̀nà àbayo nipa lílo MOA lati gbé ètò ọrọ́ ajé ti a ó fi máa ṣe ohun tí a bá nílò, ti a ó sì máa lo ohun tí a bá ṣe ní orílẹ̀-ède wa láìpẹ́ yìí tí àwọn Adelè wá bá ti wọlé sí ilè iṣẹ́ ìjọba.