Yorùbá ti ṣe orí-ire, èyí tí ó jẹ́ wípé, Olódùmarè tí gbé Àlàkalẹ̀ (BluePrint) èyí tí ó jẹ́ ti ìran Yoùbá, gan-gan fún Ìjọba Tiwantiwa, lé ìránṣẹ́ rẹ̀, Modúpẹ́ Onítirí aya Abíọ́lá, lọ́wọ́, fún ìṣerere ìran Yorùbá, títí ayé!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

 

Òtítọ́ Ọ̀rọ̀: Òyìnbó Kò Ní Ìfẹ́ Adúláwọ̀, Wọ́n Kàn Npa'riwo Ìjọba Tiwantiwa Ni

 

Yorùbá ti ṣe orí-ire, èyí tí ó jẹ́ wípé, Olódùmarè tí gbé Àlàkalẹ̀ (BluePrint) èyí tí ó jẹ́ ti ìran Yoùbá, gan-gan fún Ìjọba Tiwantiwa, lé ìránṣẹ́ rẹ̀, Modúpẹ́ Onítirí aya Abíọ́lá, lọ́wọ́, fún ìṣerere ìran Yorùbá, títí ayé!

Bí kò ṣe èyí ni, àwa náà ìbá máa tẹ̀síwájú, nínú Nàìjíríà àti pẹ̀lú àwọn ìlú Áfríkà tókù, à bá máa tẹ̀síwájú nínú àdàmọ̀dì “ìjọba tiwantiwa” èyítí àwọn òyínbó wọ̀nyí npariwo rẹ̀ káàkiri àgbáyé, tí ó sì jẹ́ wípé democracy irọ́ ni – ìjọba tiwantiwa t’onírọ́dé ni, ṣùgbọ́n tí àwọn òyínbó wọ̀nyí máa máa pariwo rẹ̀ fún àwọn ìlú ní  Afríkà, tí ó sì jẹ́ wípé ọ̀nà àti kó nkan jẹ ní Afríkà ni.

Ìròhìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láìpẹ́ yí ní orí ẹ̀rọ ayélujára ni ó tún wá túbọ̀ ṣe àlàyé ohun tí o nṣẹlẹ̀ gan-gan nígbàtí àwọn òyìnbó bá npariwo democracy, democracy, ní Áfríkà!

Ohun tí ó nṣẹlẹ̀, tí ó dẹ̀ ti nṣẹlẹ̀, láti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún sẹ́hìn ni wípé, ìdí tí àwọn òyìnbó fi npariwo “democracy” (èyíinì, ìjọba “tiwantiwa”) ni wípé, nínú “ìjọba tiwantiwa” yí, àwọn orìlẹ̀-èdè á máa ṣe ìdìbò láti ìgbà-dé-ìgbà, èyí tí wọ́n á fi máa yan àwọn olórí sí orí àlééfà ìjọba tiwantiwa náà.

Ṣùgbọ́n, ohun tí ó máa nṣẹlẹ̀ ni wípé àwọn òyìnbó wọ̀nyí, wọ́n ti mọ bí àwọn ṣe máa lúgọ dè yín làti ri wípé ẹni tí ó máa ṣe ìfẹ́ òyìnbó aláwọ̀ funfun ni ó máa wọ’lé nínú ìdìbò náà.

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Ẹ̀yin á máa rò wípé ẹ̀yin ará ìlú ni ẹ yan ẹni náà sí ipò ààrẹ yín, ṣùgbọ́n irọ́ ni, àwọn òyìnbó wọ̀nyí ti mọ bí àwọn ṣe nṣeé tí ó fi jẹ́ wípé ẹni tí àwọn bá fẹ́ kí ó di ààrẹ ní orílẹ̀-èdè yín ni ó máa wọlé, kí àwọn lè wá rí ẹni náa lò fún ohun tí ó bá wù wọ́n láti ṣe ní orílẹ̀-èdè Áfríkà náà.

Gẹ́gẹ́bí àpẹẹrẹ, ìgbàkúgbà tí ẹ bá ti nri, wípé, olórí ìlú kan ní Áfríkà nfi ìyà jẹ àwọn ara ìlú rẹ̀, tí ohun gbogbo kò lọ dédé, láì dẹ̀ jẹ́ wípé wọn kò ní àlùmọ́ọ́nì ni (nítorí, kò sí ibi tí kò ní àlùmọ́nì ní ilẹ̀ Áfríkà), kí ẹ mọ̀ wípé, olórí ìlú yẹn nṣe ìfẹ́ àwọn òyìnbó t’ó rán-an níṣẹ́ ni! Ohun tí wọ́n ran ni ó nṣe yẹn!

Kí dẹ̀ ni ìdí tí òyìnbó fi nṣe eléyi? Ìdí ni wípé, tí ìyà kò bá jẹ aláwọ̀dúdú, òyínbó kò lè r’ayé wá, nítorí òyìnbó kò sábà ní àlúmọ́nì púpọ̀ ní ìlú ti’wọn bí áwa aláwọ̀dúdú ṣe ní àjántìrẹrẹ àlùmọ́nì ní ilẹ̀ wa; nítórí náà, ọ̀dọ̀ wa ní Áfríkà ní wọ́n ti máa njí àwọn nkan tí wọ́n fi ntún ìlú òyínbó ṣe; tìt’orí eléyi, wọ́n níl’ati máa rí àwọn olórí káàkiri Áfríkà tí ó máa máa ràn wọ́n lọ́wọ́, tí á sì gbà wọ́n láyè, láti máa rí nkan kó ní ìlú Áfríkà náà.

Ìgbàkúgbà tí olórí kan ní Afríkà kò bá ti jẹ́ kí àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí rí nkan kó, nṣe ni àwọn òyìnbó ọ̀ún máa nwá ọ̀nà tí wọ́n á fi yọ olórí náà kúrò lórí oyè. Wọ́n lè gbé ìjọba ológun kan dìde tí ó máa lé olórí ọ̀ún kúrò lórí oyè, ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin ará ìlú kò níí mọ̀ wípé àwọn òyìnbó l’ó wà ní’di ọ̀rọ̀ náà!

Wọ́n á ti’lẹ̀ b’ẹnú àtẹ́ lu ìjọba ológun ọ̀ún ní gbangba, tí kò fi ní hàn sí yín wípé àwọn gan-an ló wà ní’dí ọ̀rọ̀ – bí abunijẹ-fẹ́’yì-sii – bí àwọn òyìnbó wọ̀nyí ṣe máa nṣe gan-an nìyẹn.

Nígbàtí wọ́n bá ti wá pa ọrọ̀ ajé yín l’okú tán, àwọn náà ni wọ́n á tún wá sọ fún olórí ìlú yín wípé kí ó wá yá’wó l’ọdọ̀ àwọn l’ati ṣe àwọn nkan ìdàgbà-s’okè fún ìlú yín; wọ́n ti tì yín sí’nú gbèsè nìyẹn; bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré, wọn kìí yá’yàn ní owó láìsí nkan tí wọ́n á gbà lọ́wó yín yàtọ̀ sí èlé owó fún’ra rẹ̀: inkan tí wọ́n máa rí kó lọ náà ni gbogbo rẹ̀ dálé l’orí!

Tí ó bá wá di wípé owó tí ẹ yá, ẹ ò ri san, pàápàá, nígbà míì tí ó jẹ́ wípé èlé orí ẹ̀ gan, ẹ ò wá ríi san, àwọn òyìnbó yí náà ni wọ́n máa sọ fún yín wípé, ìyẹn ò ṣòro ò, ẹ̀yin ẹ lọ yá’wó ní World Bank (bánkì àgbáyé), tàbí kí ẹ yáwó ní International Monetary Fund (I.M.F), bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré, àwọn òyìnbó wọ̀nyíi náà ni wọ́n ni àti World Bank àti I.M.F ní ìkáwọ́ wọn!

Gbèsè á wá máa yí lu gbèsè láti ọdún dé ọdún! Nígbàtí àwọn I.M.F tàbí World Bank bá dẹ̀ máa yá yín lówó láti fi san gbèsè, àwọn náà á tún wá fún yín ní àwọn ohun tí ẹ gbọ́dọ̀ ṣe; wọ́n lè ní kí ẹ dín òṣùwọ̀n owó orílẹ̀-èdè yín kù! (devaluation of currency!), èyí lá tún wá jẹ́ kí ọ̀wọ́n gógó kí ó wà ní orílẹ̀-èdè yín; tí wọ́n bá tún ti sọ’yẹn tán, wọ́n lè ní kí ẹ fi kún owó petrol ní orílẹ̀-èdè yín, wípé ọ̀nà àbáyọ fún yín n’ìyẹn; wọ́n tún lè wá fi le, wípé kí ẹ sọ àwọn ilé iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti ìjọba, kí ẹ yí wọn padà sí ti aládani – bẹ́ẹ̀ ni, eléyi á mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn pàdánù iṣẹ́ wọn! Oríṣiríṣi ẹrù wíwúwo wọ̀nyí ni wọ́n máa ndì sórí àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀dúdú!

Tí olórí náà kò bá ti wá gbà fún wọn, ọ̀nà bí wọ́n ṣe máa le kúrò lórí oyè ni àwọn òyìnbó wọ̀nyí máa máa wá, ṣùgbọ́n àwọn òpè ará ilú kò ní mọ̀, láyé, pé àwọn òyìnbó wọ̀nyí ni ó wà ní ìdí gbogbo nkan tí ó nṣẹlẹ̀ nínú orílẹ̀-èdè wọn!

Ìdí ni’yí tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí ṣe máa npariwo “democracy, democracy” ní Áfríkà, torí kí àwọn lè máa tọwọ́ bọ èto ìṣèjọba yín, láti ìgbà dé ìgbà, tí ẹ bá ti fẹ́ yan olórí tuntun, wọ́n á tún ti lúgọ dè yín láti ri wípé olórí tí ó máa ṣe ìfẹ́ àwọn òyìnbó amúnisìn yí, náà ni ó máa wọlé, kí àwọn lè máa rí olórí yẹn lò, láti ṣe ìfẹ́ òyìnbó amúnisìn lórí ilẹ̀ Áfríkà!

Ìdí ni èyí, tí ìyá Ìran Yorùbá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe máa nsọ fún wa wípé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá kò ní jẹ gbèsè kankan – a ò ní súnmọ́ nkan tí wọ́n npè ní gbèsè rárárárá, àti wípé, oun tí a bá nílò ni a máa ṣe sí ìgboro ayé wa, oun tí a bá sì ṣe yẹn náà ni a máa lo; aà ní kọjá àyè wa; a ò sì níí jẹ gbèsè kankan!

A ò ní ti oko ẹrú kan bọ́ sí òmíràn; bẹ́ẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé Àlàkalẹ̀ (Blueprint) tí Olódùmarè tí gbé lé Màmá wa, Màmá orílẹ̀-èdè Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí Abíọ́lá, lọ́wọ́. A kò gbọ́dọ̀ gbà, láyé, kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni kí ó mú wa yà kúrò nínú Blueprint yí, Àdéhùn wa pẹ̀lú Olódùmarè n’ìyẹn. Ọmọ Yorùbá kò tún ní lọ sínú oko ẹrú mọ́, láyé!