Yorùbá bọ̀, wọ́n ní “Orúkọ ọmọ ni ìjá’nu ọmọ.” Òwe Yorùbá

Oríṣiríṣi orúkọ l’ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn Yorùbá kìí dédé fún ọmọ l’orúkọ láì ní ìdí pàtàkì. Ìdí ni’yí tí wọ́n fi np’òwe wípé “Ilé l’a nwò, kí á tó s’ọmọ l’orúkọ.”

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
Orúkọ Àmútọ̀runwá Nílẹ̀ Yorùbá

Orúkọ Àmútọ̀runwá

Èyí jẹ́ àwọn orúkọ tí a nsọ àwọn ọmọ tí a bí pẹ̀lú àkíyèsí tàbí àmì àmút’ọ̀runwá kan tàbí òmíràn l’ara wọn.

Gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ:

1. Òjó

Ọmọ’kùnrin tí a bí, tí olubi ọmọ lọ́ má a l’ọrùn nígbatí ó njá’de nínú ìyá rẹ̀.

2. Àìná

Ọmọ’bìnrin tí a bí, ti olubi rẹ̀ lọ́ má a l’ọrùn nígbàtí ó já’de nínú ìyá rẹ̀.

3. Àjàyí

Ọmọ tí ó d’ojú bo’lẹ̀ ní’gbà tí a bi. Ìyẹn ni wípé, ní’gbà tí ó nja’de nínú ìyá rẹ̀.

4. Ọ̀kẹ́

Ọmọ tí ó ṣì wà nínú àpò ọmọ l’ati inú ìyá rẹ̀ wá ní’gbà tí ó nja’de nínú ìyá náà.

5. Ìgè

Ọmọ tí ó fi ẹsẹ̀ já’de l’ati inú ìyá rẹ̀. Tàbí ọmọ tí ó kọ́ yọ ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ ní’gbà tí ìyá rẹ̀ kún’lẹ̀ l’ati bi.

Ká Ìròyìn: Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá

6. Táíwò

Èyí tú’mọ̀ si ọmọ tí ó kọ́kọ́ “tọ́ ayé wò” nínú ọmọ ìb’ejì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìyẹn ni wípé ọmọ tí ó kọ́kọ́ já’de nínú ìyá rẹ̀, nínú àwọn ìb’ejì.

7. Kẹ́hìndé

Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Táíwò ní ọjọ́ kannáà l’ati inú ìyá kannáà.

8. Ìdòwú

Ọmọ tí a bí tẹ̀lé àwọn ìbejì ní’gbàti ìyá tún l’oyún ẹ̀ẹ̀ míì.

9. Àlàbá

Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Ìdòwú.

10. Ìdògbé

Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Àlàbá.

11. Ìdòhá

Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Ìdògbé.

Ká Ìròyìn: Má Ṣe Gb’ara Lé Ọmọ Íbò, Ẹni ibi Ọ̀dàlẹ̀ Ìran Níwọ̀n

12. Ẹ̀taòkò

Ọmọ́ tí a bí ní’jọ́ kannáà pẹ̀lú Táíwò àtí Kẹ́hìndé, tí ó jẹ́ ìkẹ́ta nínú àwọn ìb’ẹta (ọmọ mẹ́ta tí a bí ní’jọ́ kannáà l’ati inú ìyá kannáà).

13. Òní

Ọmọ tí ó kéré ní’gbà tí a bi; tí ó sì nké tatata t’ọ̀sán t’òru.

14. Ọ̀la

Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Òni.

15. Ọ̀túnla

Ọmọ tí a bí tẹ̀lé Ọ̀la.

16. Dàda

Ọmọ tí irun rẹ̀ bá ta’kókó tàbí tí ó hunjọ.

17. Olúgbòdi

Ọmọ tí ó ní ìka ọwọ́ mẹ́fà tàbí ìka ẹsẹ̀ mẹ́fà.

18. Abíọ́nà

Ọmọ tí a bí sí ojú ọ̀nà, yálà ní’gbà tí ìyá rẹ̀ nrin ìrìn àjò, tàbí tí ó nlọ ibi kan; ìbáà ṣe ọ̀nà oko, ọ̀nà ọjà, ọ̀nà ilé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

19. Abíọ́dún

Ọmọ tí a bí ní àsìkò ọdún; ọdún èyík’eyí tíì y’óò wù k’ó jẹ́.

20. Babátúndé tàbí Babárìndé

Ọmọ’kùnrin tí a bí l’ẹhìn ikú bàbá àgbà (èyíinì, bàbá t’ó bí bàbá ọmọ náà).

Yétúndé tàbí Ìyábọ̀dé tàbí Yéwandé tàbí Yéjídé tàbí Yésìdé

Ọmọ’bìnrin tí a bí l’ẹhìn ikú ìyá bàbá ọmọ náà.