Ohun tí a npè ní ìṣèjọba-ara-ẹni (Sovereignty) ní agbára púpọ̀ ní gbogbo àgbáyé, àti wípé, l’ati ọjọ́ tí a ti sọ yí, ni orílẹ̀-èdè Yorùbá ti di orílẹ̀-èdè aṣè’jọba-ara-ẹni (Sovereign Nation); èyí tí ó mú kí ọpọ́n ti sún kúrò ní b’ó ṣe wà tẹ́’lẹ̀.

L’ati ọjọ́ kéjìlá oṣù kẹ́rin ọdún yí (2024) ni nàíjíríà kò ti jẹ́ aláṣẹ rárárárá ní ilẹ̀ Yorùbá.

Tẹ́’lẹ̀ tẹ́’lẹ̀, pàápàá, l’ati ogúnjọ́ oṣù kọ́kànlá ọdún 2022 ni wọn kò ti ní àṣẹ mọ́, l’orí ilẹ̀ Yorùbá; ṣùgbọ́n èyí tí ọ̀rọ̀ náà fi túbọ̀ wá yàtọ̀ nísiìyí, ni wípé, l’ati ọjọ́ kéjìlá oṣù kẹ́rin ọdún yí ni a ti wá gbé ìjọba orílẹ̀-èdè Yorùbá kalẹ̀, tí a sì ti fi èyí tó gbogbo àgbáyé l’etí.

 

Ọ̀rọ̀ Ti Di Orílẹ̀-Èdè S’orílẹ̀-Èdè

 

Ṣe bí ajá t’ó bá fẹ́ sọnù ni ọ̀rọ̀ Nàìjíríà; kò ní gbọ́ fèrè ọdẹ náà ni! Ìgbé’raga àti ìwà ipá Nàìjíríà, kò jẹ́ kí wọn gbọ́ fèrè ọdẹ báyi o!

Ṣùgbọ́n ṣá, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ní pàtàkì jùlọ, àwọn tí ó wà l’orí ilẹ̀ Yorùbá, l’ọwọ́l’ọwọ́ báyi, ni kí wọ́n ríi wípé àwọn d’ẹkun àti ṣe ohunk’ohun tí ó bá ti l’òdì sí ohun tí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá nfẹ́; nítorí wípé, àìṣe eléyi, ọ̀ràn nlá gbáà l’ó jẹ́ fún irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀.

L’ọnà kéjì, ṣí ṣe l’òdì sí ohun tí Orílẹ̀-Èdè Yorùbá nfẹ́, tú’mọ̀ sí wípé fí fi ara mọ́ ohun tí Nàìjíríà nṣe, èyí tí ó sì jẹ́ wípé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ nsọ wípé òun kìí ṣe ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nìyẹn.

Wọ́n ní, ààbọ̀ ọ̀rọ̀ ni a máa nsọ fún ọmọlúàbí o! T’ó bá ti dé inú ẹ̀, ni ó máa wá di odindi!