Gbọ Audio Ìròyìn Òmìnira
Ó pẹ́ tí a ti máa ń sọ pé àwọn ọmọ Íbò gọ̀, wọ́n nf’ẹnu họ’ra. Ṣé láìpẹ́ yí ni ìkan nínú wọn tún bọ́ sórí ẹ̀rọ ayélujára tó sì ń wí pé, àwọn Yorùbá ń bẹ̀rù láti kúrò nínú Nàìjíríà.
Ẹ jọ̀wọ́ ẹ bá wa béèrè lọ́wọ́ alákọrí rẹ̀ bóyá ihò-ilẹ̀ ló ń gbé, tí kò fi mọ̀ pé Yorùbá ti kúrò lára Nàìjíríà ó tí di ọdún kan àti oṣù mẹ́san báyìí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ṣì ń ṣorí kunkun, ṣùgbọ́n tí a mọ̀ pé Olódùmarè máa ṣí wọn ní’díì kúrò lórí ilẹ̀ wa láìpẹ́.
Ṣùgbọ́n àrùn kan tí ó nṣe àwọn af’ẹnuhọ’ra Íbò wọ̀nyí ni pé, ẹni tí kò bá tíì máa làágùn, kí ó máa ṣe hílà-hílo káàkiri ìgboro, ọpọlọ wọn ò gbà pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ nṣiṣẹ́.
Ọpọlọ ni Yorùbá fi ń jà; ṣùgbọ́n àwọn Íbò kò gbà pé ìjà ọpọlọ ni ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yí, eré kí àwọn ṣáà máa fẹ̀’fun kiri títì ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ ìjàǹgbara.
Ojú wọn ló máa ṣe, nígbàti ìjọba Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) bá wọlé sí àwọn oríkò ilé-iṣẹ́-ìjọba wa gbogbo; àá wá wo ibi tí gbogbo àwọn òmùgọ̀ yí máa fojú sí nígbà náà.
Gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn wa kan ti ṣe àfihàn ọ̀rọ̀ tí ọmọ Íbò yí nsọ; ó pèé ní ‘Gàlègàlè àwọn ẹlẹ́nu mímú j’abẹlọ ọmọ Íbò.’ Ọ̀rọ̀ gidi tó ṣe àpèjúwe òmùgọ̀ ọmọ Íbò ọ̀hún nì yẹn.
Ó tún sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ dé bi wí pé, òun ò ní fara mọ́ kí ọmọ Yorùbá ó ṣe olórí Nàìjíríà mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí èyí tó kàn wá nípa ìyẹn, ó fi hàn gedegbe pé àwọn òpònú Íbò wọ̀nyí kò mọ ń kan tí wọ́n fẹ́ gan-an gan.
Apá kan ẹnu wọn á máa sọ̀rọ̀ ipò wọn ní ìlú Nàìjíríà, apá kejì á máa sọ̀rọ̀ pínpínyà kúrò ní Nàìjíríà, nígbà tí wọ́n kò mọ èyí tó kàn.
A dúpẹ́ pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ti jẹ́ orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.
Pẹ̀lú àṣẹ Èdùmàrè, ní àìpẹ́ yí ni a máa rẹ́yìn Nàìjíríà tí wọ́n sì máa sá kúrò lórí ilẹ̀ wa.