Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá káàkiri ìpínlẹ̀ méjèèje Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti gba ìkìlọ̀ l’orí àwọn irúgbìn ayédèrú tí ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí ó ngàba lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi lorí ilẹ̀ wa, npín fún wọn!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí.Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè… Share on X
Yoruba Warn africa of danger in gmo seeds
Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ wípé àwọn ìrúgbìn ayédèrú wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ síí tà, lówó pọ́ọ́kú fún àwọn ènìyàn wa ní ìpínlẹ̀ Ìbàdàn (èyí tí Nàìjíríà npè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́); bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti npín irúgbìn ayédèrú wọ̀nyí fún wọn ní apákan Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ (Old Ọ̀yọ́ Empire) [èyítí agbésùmọ̀mí Nàìjíríà npè ní ìpínlẹ̀ Kwara].

 

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá: Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá Gba Ìkìlọ̀!

 

A gbọ́ wípé lára àwọn irúgbìn tí wọ́n nfún àwọn ènìyàn wa yí, ni ọkà bàbà, ìrẹsì, àti àgbàdo.

Ìkìlọ ti wá jáde o, wípé, gbogbo ẹni tí ó ti gba irúgbìn wọ̀nyí, kí wọn ó ṣíra dáa padà ní kíákíá!

Lọ́nà kejì, ìkede àti ìkìlọ̀ ti jáde wípé, Ẹ̀sùn nlá ló jẹ́ o, lábẹ́ òfin Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gba irúgbìn wọ̀nyí.

Gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá máa ṣe àyẹ̀wò fínní-fínní fún. Ìdí ni wípé, lákọkọ́, a fẹ́ mọ irúfẹ́ oríṣiríṣi ilẹ̀ tí ó wà ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá; nítorí wípé àwọn ilẹ̀ kan wà, tí ó jẹ́ wípé ó ní irúfẹ́ irúgbìn tí ilẹ̀ náà wúlò fún dáradára. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ilẹ̀ kan wà tí ó jẹ́ wípé wọ́n ti di aṣálẹ̀!

A fẹ́ mọ àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí àti bí a ṣe máa jí wọn padà!

Ìwọ tí o bá gba irúgbin ayédèrú wọ̀nyí lọ́wọ́ ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, Ẹ̀SÙN APÀNÌYÀN ló jẹ́ fún ẹ o! Báwo ló ṣe jẹ́ Ẹ̀sùn Apànìyàn?

Èkíní, gbogbo ẹni tí ó bá gba irúgbìn ayédèrú wọ̀nyí, tí wọ́n sì gbìn-ín, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti ṣe àkóbá nlánlà fún ara wọn, àti fún ọmọ wọn, bákannáà, àtí fún ìdílé wọn, nípa ètò ìwòsàn ní ilẹ̀ Yorùbá! Ẹni a bá wí, Ọba jẹ́ ó gbọ́ o!

Bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ wípé, ibi tí ẹ bá gbin irúgbìn ayédèrú yẹn sí; ọgọ́ta ibùsọ̀ káàkiri ilẹ̀ níbẹ̀, ni irúgbìn ayédèrú yẹn ti ṣe àkóbá fún gbogbo ilẹ̀ náà.

Ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ta ni wípé, kò sí nkan tí ẹ lè gbìn sórí ilẹ̀ yẹn mọ́, tó máa ṣe rere! Èyí túmọ̀ sí wípé ẹni tó bá gbin ìrúgbìn ayédèrú yí, ẹni náà nsọ ilẹ̀ Yorùbá di ilẹ̀ aṣálẹ̀.

Ìdí nìwọ̀nyí tí ó fi jẹ́ wípé ẹ̀sùn apànìyàn ni ọ̀ràn tí ẹni tí ó gbin ayédèrú irúgbìn wọ̀nyí, tí ó da, nítorí tí o bá ti ti ipa gbí gbin ayédèrú irúgbìn, tí o sọ ilẹ̀ Yorùbá di aṣálẹ̀, èyí túmọ̀ sí wípé ìyàn máa mú, á wá di ikú fún ènìyàn.

Ẹ wá ránti o, wípé, nígbàtí àkókò náà bá tó, kò sí “mi ò mọ̀ niì,” lábẹ́ òfin o!

Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) nsọ fún Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P)

Nítorí náà, ọmọ Yorùbá, ọ̀rọ̀ ti jáde o, wípé kí á sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn wa tí wọ́n ti fún ní àwọn irúgbìn ayédèrú wọ̀nyí, ní Ìlọrin, Osí, àti káàkiri agbègbè náà, kí wọ́n má ṣe gbín-ín o! Kí ẹ sì rántí wípé, àwọn tó npin nkan aburú wọ̀nyí kò ní sọ fún yín wípé ayédèrú ni o! Ṣùgbọ́n Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti sọ fún yín o!