ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

ÀṢẸ Èdùmàrè

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀ èdè olórí ire lónìí, iwájú ní orílẹ̀ èdè Niger wà látàrí àwọn ìgbésẹ̀ akin tí wọ́n ń gbé láti bíi ọdún mélòó kan sẹ́yìn.

Ìròyìn tí a tún gbọ́ báyìí ni wípé, Orílẹ̀ èdè náà tún ti pá láṣẹ kí àwọn ọmọ ológun orílẹ̀ Germani ó kúrò lórí ilẹ̀ wọn ní wàrà-ǹ-sesà!

Omi kìí sàn kò tún bojúw’ẹ̀yìn ní àwọn ọmọ ológun orílẹ̀ èdè Niger fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ò, ní bí wọ́n ṣe dúró gbáná-gbáná lẹ́yìn àwọn ọmọ ológun orílẹ̀ èdè Germani títí tí wọ́n fi wọ inú ọkọ̀ bààlúù wọn.

Àwa ọmọ orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) kí ẹyin ọmọ orílẹ̀ èdè Niger kú oríire o, nítorí irú àwọn ìgbésẹ̀ òmìnira lọ́wọ́ amúnisìn bí eléyìí ni inú àwa náà máa ń dùn sí, ìdí nìyí tí àwa ọmọ Orílẹ̀ èdè D.R.Y náà ṣe kéde òmìnira tiwa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Olódùmarè nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè fi iṣẹ́ náà rán.

Láìpẹ́, láìjìnnà, ní orílẹ̀ èdè D.R.Y náà yóò lé àwọn jẹgúdújẹrá olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí wọ́n ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa kúrò, ẹ̀sín tiwọn yóò wá burú ju ti àwọn ọmọ ológun Germani wọ̀nyí lọ nítorí pé, púpọ̀ nínú àwọn aláyé bàjẹ́ yí kò ní leè dúró mú ṣòkòtò nígbà tí àkókò náà bá dé,ojú yóò sì ti gbogbo wọn àti àwọn agbódegbà wọn.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ka Ìròyìn Síwájú si: