L’ẹhìn ọdún kan àti oṣù mẹ́san tí Ibrahim Traore bọ́ sí ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè Burkina Faso, àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́wa káàkiri àgbá’yé, ní òpin ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá yí, fi àwọn aṣojú tuntun ránṣẹ́ sí ìlú Burkina Faso.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
Orílẹ̀-Èdè Mẹ́wa Fi Aṣ'ojú Wọn Rán'ṣẹ́ Sí Burkina Faso

Gẹ́gẹ́bí ìròhìn kan tí a gbọ́ l’orí ayélujá’ra ṣe sọ, èyí tú’mọ̀ sí wípé àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́wa yí, f’ara mọ́ jíjẹ́ tí Ibrahim Traore jẹ́ ààrẹ ìlú Burkina Faso.

Àwọn ìlú mẹ́wẹ̀wá tí wọ́n fi aṣ’ojú (èyíinì, Ambassador) wọn ránṣẹ́ sí ìlú Burkina Faso, l’ati lọ fi ara wọn hàn ní’wá’jú Ààrẹ Ibrahim Traore, gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó ní àṣẹ l’ati ọ̀dọ̀ ààrẹ orílẹ̀-èdè ti’wọn, l’ati ṣe ojú fún orílẹ̀-èdè náà, tí wọ́n sì mú ìwé àṣẹ ọ̀ún dání, ni Germany, Amẹ́ríkà, Algeria, Russia, pẹ̀lú Rwanda bákannáà. Àwọn t’ó kù ni orílẹ̀-èdè Spain, Guinea Bissau, Venezuela, Poland, àti Pakistan.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn oríṣiríṣi àwọn aṣ’ojú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, ààrẹ Ibrahim Traore sọ wípé inú òun dùn o, pé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí gbá’rùkù ti Burkina Faso, bẹ́ẹ̀ náà ni ó fi dá wọn l’ojú wípé orílẹ̀-èdè Burkina Faso ní àf’orítì sí ríríi dá’jú wípé àwọn mú ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní ọ̀kúnkúndùn.

Ó tún wá sọ wípé, bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ní ìpèní’jà ọ̀rọ̀ ààbò, síbẹ̀, àwọn á ríi wípé ìwọ̀nyí kò ṣe ìdíwọ́ fún ètè Burkina Faso l’ati ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè míràn.

Gẹ́gẹ́bí ìròhìn tí a gbọ́ náà ṣe sọ, bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé ó ṣeé ṣe kí Burkina Faso ó pe gbogbo àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá aṣ’ojú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí sí’nú gbàgede ìpàdé kan náà l’ati wá fi ara wọn hàn ní’wa’jú ààrẹ Ibrahim Traore, rárá o! Nṣe ni Burkina Faso ṣe àpọ́n’lé fún ẹnikọ̀ọ̀kan nínú wọn, àfi bíi pé orílẹ̀-èdè yẹn nìkan ni ó wá l’ati fi aṣ’ojú wọn hàn ní’wá’jú Traore: wọn ò dà’wọ́n pọ̀ bí ẹja sardine nínú agolo.

Orílẹ̀-Èdè Mẹ́wa Fi Aṣ'ojú Wọn Rán'ṣẹ́ Sí Burkina Faso

Nṣe ni ọ̀dọ́’mọdé Traore yí mú sùúrù, tí ó jóko, títí tí ó fi parí ìpàdé pẹ̀lú àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè kan, tí wọ́n sì ti lọ, pẹ̀lú iyì àti ẹ̀yẹ, kí àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè míràn ó tó wọlé.

Ètò náà wú’ni l’orí l’ọpọ̀l’ọpọ̀, àfi bíi pé kí ó máa lọ bẹ́ẹ̀ ni, ní bi Traore àti ìlú Burkina Faso ṣe yẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè àti aṣ’ojú wọ̀nyí sí, láì wọ́ ara tiwọn ní’lẹ̀ rárárárá! Àwọn orílẹ̀-èdè náà, pàápàá, mọ̀ dá’jú wípé Burkina Faso kò fi ara wọn wọ́’lẹ̀ níwájú ẹnik’ẹni.

Ṣé àwa orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá náà, anre’tí ọjọ́ náà tí ó jẹ́ wípé, pẹ̀lú àtìl’ẹhìn Olódùmare, àáti lé àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà kúrò ní orí ilẹ̀ wa, tí àwa náà yíò máa gba àwọn àlejò l’ati orílẹ̀-èdè míràn, l’ọkan-ò-j’ọ̀kan ní àwọn àsìkò t’ó bá yẹ.

Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á gb’aradì, kí á sì ríi wípé, bí ó ti’lẹ̀ ṣe wípé a máa b’ọ̀wọ̀ fún orílẹ̀-èdè míràn; ṣùgbọ́n, láí, a kò ní wọ́ ara wa ní’lẹ̀ fún ẹnik’ẹni. Ìgbà díẹ̀ l’ó kù o!