Oríkì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣà ilẹ̀ Yorùbá.Àwọn Yorùbá fẹ́ràn oríkì púpọ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń mú inú ènìyàn dùn tàbí mú orí ẹni wú.
Kò sí ohun tí àwọn Yorùbá kò ní oríkì fún,bí oríkì se wà fún ènìyàn(ìyẹn ni oríkì ìdílé) bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà fún ẹranko, bẹ́ẹ̀ sì ni oúnjẹ náà ní oríkì tirẹ̀.
Yorùbá fẹ́ràn láti máa ki ènìyàn pàápàá ní àkókò ayẹyẹ, a sì tún máa ń fi pe àwọn míràn gẹ́gẹ́ bíi orúkọ oríkì, bí àpẹẹrẹ Àjàní, Àlàó, Àlàbí, Àkànjí, ìyẹn ni fún orúkọ oríkì ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn obìnrin náà ní orúkọ oríkì bí àpẹẹrẹ Àjọkẹ́, Àjíkẹ́,Àríkẹ́, Àbẹ̀bí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣùgbọ́n àwa ọmọ Yorùbá mélòó ni a tilẹ̀ mọ oríkì ìdílé tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ti jáde mọ́ lónìí, bẹ́ẹ̀ sì ni a ò sọ àwọn ọmọ wa ní orúkọ oríkì mọ̀. Nítorí náà a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó ra ìran Yorùbá padà lọ́wọ́ ìparun nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ìyá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla, nítorí pé màmá wa ti sọ fún wa wípé àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ yóò dá wa padà sí ìpinlẹ̀ṣẹ̀ wa ni. Ayọ̀ ni ti wa!