Orí ẹ̀rọ ayélujára ni a ti rí fọ́nrán náà, tí ó sì jẹ́ pé àánú ọmọkùnrin náà ṣe’ni lọ́pọ̀lọpọ̀.

Lóotọ́, áà mọ bí’ṣu ṣe kú, b’ọbẹ ṣe bẹ́, nípa ọmọkùnrin yí, a ṣáà  gbó tó nsọ èdè Yorùbá; tí kò bá ti jẹ́ ẹni tí ó kàn ṣáà gbọ́ èdè wa ni, á jẹ́ pé bóyá ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá – àyẹ̀wò fínní-fínní tí D.R.Y máa ṣe, ní àá fi lè mọ̀ bóyá I.Y.P ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kò ti ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa D.R.Y, wọ́n kàn nfi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò nínú fọ́nrán náà ni.

Ọmọkùnrin yí sọ pé kí wọ́n wo bí ara òun ṣe bu táu-táú. Ìyà njẹẹ́, ó hàn gedegbe. Ó ní tí òun bá rí ẹni tí ó máa yá òun ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún owó nàìjíríà, ó lé díẹ̀, òun mọ ohun tí òun máa ṣe, tí òun á dẹ̀ lè san owó náà padà, lẹ́hìn tí òun bá ti jèrè.

Ó ní tí òun bá ti ẹ̀ rí owó tó tó owó, pé òun á ṣe òwò èlùbọ́. Ó ní èlùbọ́ ni màmá òun máa nta, ọjà oko ni, tó dẹ̀ lówó lórí gẹ́gẹ́bí ó ṣe sọ.

Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó mọ́gbọ́n dání gidi. Ó dárúkọ iye owó kan, ó ní tí òun bá rí ẹni tí ó lè yá òun, tí òun á dẹ̀ ní ànfààni ọdún-kan-àbọ̀ kí òun ó tó bẹ̀rẹ̀ sí dáwó padà, ó ní ó ti di ṣíṣé, àti pé òun ò ní da gbogbo owó yẹn lé òwò náà, nítorí àwọn ìnáwó lórí nkan pẹ́pẹ̀pẹ́ tí ó máa máa jẹyọ, bíi pé kí ẹ̀rọ èlùbó ó nílò àtúnṣe, àti bẹ́ẹ̀.

Ó ti lẹ̀ tún sọ pé, iṣẹ́ gbẹ́nà-gbẹ́nà igi ni òun kọ́, tí eléyí náà á tún ṣeé dá sílẹ̀ níjọ́ iwájú.

Àsẹ̀hìn wá, àsẹ̀hìnbọ̀, a rí ọpọlọ pípé lórí ọmọkùnrin yí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrísí rẹ̀, ní ti ara, kò wu’ni rárá, ìyà njẹẹ́ ní ti gidi.

Ó wá mú’ni rántí pé, ara irúfẹ́ ìdí tí Olódùmarè ṣe gbé Ìyá wa díde, Olùgbàlà Ọmọ Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, nìyí; ògo gbogbo wa dẹ̀ máa búyọ; ìgbà díẹ̀ báyi ló kù!

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!