Ṣèyí Mákindé, alábọ̀dè ìlú Ìbàdàn, ni àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti wá fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí, wàyí o, fún ṣíṣe rádaràda tí ó nṣe ní ìlú Ìbàdàn àti ní ìpínlẹ̀ Ìbàdàn (èyí tí ìjọba terrosist Nàìjíríà npè ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́).

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ṣé láìpẹ́ yí ni a gbọ́ nípa owó tí bánkì àgbáyé fún àlábọ̀dè ọ̀ún, wípé kí ó fi tún àwọn ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ kan ṣe. Èyí tí a tún gbọ́ láìpẹ́ yi ni wípé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyí, ètò ìrànlọ́wọ́ tí ó ku díẹ̀ k’ó tó mílíọ̀nù márun dọ́là, tilẹ̀ ti wà nílẹ̀, kí ó tó tó àsìkò yí, láti ọ̀dọ̀ Bill Gates Foundation wípé kí wọ́n fi ṣe ètò ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbìn, lábẹ́ ìjọba agbésùnmọ̀mí èyí tí Ṣèyí Mákindé nṣójú fún, báyí, ní ìpínlẹ̀ Ìbàdàn tiwa, ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, èyí tí àwọn ìjọba terrosist Nàìjíríà yí ṣì npè ni ara Nàìjíríà, tí kò sì rí bẹ́ẹ̀.

Àmọ́, àti Bill Gates, òyìnbó apànìyàn nì, àti alábọ̀dè Ṣèyí Mákindé, ni àwọn ọmọ Yorùbá wá fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí, báyi o: Wọ́n ní, Ìwọ Bill Gates, ọmọ Yorùbá kò nílò ìrànlọ́wọ́ kankan o, láti ọ̀dọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni a ò nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, rárárárá. Ní àkọ́kọ́ ná, a fẹ́ kí ìwọ Bill Gates ó mọ̀ wípé, ilẹ̀ Yorùbá ni ìpínlẹ̀ Ìbàdàn jẹ́ o (èyí tí wọ́n npè fún ẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́), àti wípé Yorùbá kò dẹ̀ sí ní abẹ́ Nigeria mọ́, rárárárá! Nítorí èyí, ọmọ Yorùbá sọ fún ìwọ Bill Gates wípé, kí o dẹ́kun gbogbo rádaràda tí o nṣe ní orí ilẹ̀ Yorùbá o!

Orílẹ̀-Èdè aṣèjọba-ara-ẹni ni wá o – Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba), bẹ́ẹ̀ ni a kò sí ní abẹ́ Nàìjíríà mọ́ – nítorí èyí, ìwọ Bill Gates, gbé sàráà ẹ kúrò ní agbègbè ilẹ̀ Yorùbá o! Má sì tẹ̀síwájú nínú àjọṣepọ̀ kankan mọ́, pẹ̀lú ẹnikẹ́ni lórí ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ilẹ̀ Yorùbá.

Ọmọ Yorùbá Ti Ṣe Ìkìlọ̀ Fún Bill Gates, Pẹ̀lú Ṣèyí Mákindé

Ìwọ, Ṣèyí Mákindé, yára mọ̀ báyi o, wípé, gbogbo nkan tí o nṣe, lórí ilẹ̀ Yorùbá, tí o npe’ra rẹ ní gómìnà, tí o sì nka ilẹ̀ Yorùbá mọ́ ìlú Nigeria! – à! tìẹ ti bá ẹ! Mọ̀ báyi wípé ọ̀ràn ni o ndá o, nítorí ilẹ̀ Yorùbá kò sí lára nàìjíríà mọ́ – ìwọ fún’ra rẹ dẹ̀ mọ eléyi dájú!

Gbogbo àwọn nkan tí o nṣe káàkiri – o sọ wípé, o ṣe àgbékalẹ̀ oxygen plant, àti wípé o lọ sí London láti buwọ́ lu ìwé àdéhùn pẹ̀lú Shell Nigeria; ìwọ fún’ra rẹ mọ̀ o, wípé ọ̀nà àti máa tan ará ìlú jẹ ni gbogbo ìwọ̀nyẹn, kí àwọn ará ìlú má ṣe lè dojúkọ ohun tí o jẹ́ ẹ̀tọ wọn gan-gan, àti wípé kí wọ́n má lè kọ’bi ara sí wípé Yorùbá ti di orílẹ̀-èdè, àti wípé a ò sí lábẹ́ Nàìjíríà mọ́! Mọ̀ dájú wípé, Tinubú máa sẹ́ ẹ, tí ó bá ti dójú ẹ̀ o!

Nígbàtí ọwọ́ òfin àgbáyé bá tẹ̀ẹ́, Tinubú á sọ wípé òun ò mọ̀ ẹ́ rí o! Áá sọ wípé òun kọ́ ni òun rán ẹ níṣẹ́ o, àti wípé, òun kò mọ̀ nípa gbogbo rádaràda tí o nṣe ní ìpínlẹ̀ Ìbàdàn ti Democratic Republic of the Yoruba (èyí tí ẹ̀yin ṣì npè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́).

Fún gbogbo ọmọ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á mọ̀ wípé, ohun tí Olódùmarè ṣe sí ilẹ̀ Yorùbá, ó tó ọmọ Yorùbá jẹ o! A ò nílò ìrànlọ́wọ́ kankan láti ọ̀dọ̀ òyìnbó kankan o! Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Gẹ́gẹ́bí ìyá ìran àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ fún wa, a ní ànító láti ṣe ohun tí a nílò, fún’ra wa, láì ṣe ìránṣẹ́ ẹnikẹ́ni – pàápàá, wípé, ohun tí a bá nílò rẹ̀, òun ni a máa ṣe jáde; oun tí a bá sì ṣe jáde, òun náà ni a máa lò!

Ohun tí Olódùmarè fún wa lórí ilẹ̀ wa, ó tó waá jẹ o! oun ọrọ̀ ajé wa ti tó waá jẹ! A ò nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni kí á tó lè gbé ìgbé ayé rere! Gbogbo nkan tí a nílò ni Olódùmarè ti fi sí ilẹ̀ wa. Gbogbo èyí tí Bill Gates nṣe pẹ̀lú Ṣèyí Mákindé, àti irúfẹ́ wọn dede, wọ́n fi ntan ara wọn ni.

Àti Bill Gates àti Ṣèyí Mákindé, àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, sọ wípé, gbogbo èyí tí ẹ nṣe yẹn, á ò fẹ́ o; bẹ́ẹ̀ ni a ò  bẹ̀yín níṣẹ́! Ẹ̀yin, ẹ kọjá sí Nigeria, kí ẹ lọ máa ṣe gbogbo ìwọ̀nyẹn! Ẹ má ṣe dáwọ́lé irúfẹ́ rẹ̀ mọ́ lórí ilẹ̀ Yorùbá! Yorùbá ti dádúró; a ti padà sí bí Elédùmarè ṣe ṣe ẹ̀dá wa!

Ọmọ Yorùbá, iṣẹ́ la máa ṣe o! láti tún ilẹ̀ wa ṣe!