Gbọ Audio Ìròyìn Òmìnira

Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára sọ pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, àwọn ológun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì npè fún àwọn ọmọ ìlú àjọṣepọ̀-oko-ẹrú wọn (Commonwealth Citizens) láti wá jẹ́ Ọmọ-Ogun Gẹ̀ẹ́sì!

Ẹ má ṣe yà sí’bẹ̀ o! Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ pé wọ́n nwá àwọn tí wọ́n máa kó lọ ja ogun Wèrè tí wọ́n njà ní Ukraine ni o!

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe nígbà Ogun Agbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì (2nd World War), tí wọ́n kó ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn láti ìwọ̀-óòrùn Áfríkà kí wọ́n lọ ja ìjà tí kò kàn wọ́n!

Yàtọ̀ sí èyí, a ò kìí ṣe àpamọ́wọ́ Gẹ̀ẹ́sì o! Orílẹ̀-Èdè aṣèjọba-ara-ẹni ni wá, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ò kìí ṣe ilẹ̀ tí Commonwealth máà wá kó wàhálà tiwọn wá bá, a ò sí ní àjọ-ẹrú wọn.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ká Ìròyìn Síwájú sí: