Ìròyìn tí a gbọ́ l’orí ayélujára X, èyí tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́’lẹ̀, tí ọjọ́ kejìlá oṣù kẹfà ẹgbàá ọdún ó-lé-mérìn-lé-lógún, ni a ti ríi ní’bi tí wọ́n ti ń fi ọ̀rọ̀ wá arákùnrin òyìnbó kan lénu wò, ó wá ń ṣe àlàyé lórí ipa àti àṣeyọrí tí òun àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ kó nínú ìgbìmò tí wọ́n gbé kalẹ̀ nínu ìpàdé àwọn olókoowò àgbáyé (World Economic Forum) tí ó máa ń wá’yé ní ọdọọdún, ṣùgbọ́n èyí ti ó wá’yé ní ọdún 2019 ní ìlú California.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Òyìnbó yí ń ṣe àlàyé bí òun ṣe jé aṣojú àwọn ìgbìmò kan èyí tí ó sì jé pé òun ni ó jẹ́ olórí ìgbìmò náà, ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀rí tí wọ́n ní lórí ọkan nínú àwọn ìpinnu márùn-ún tí wọ́n gbékalè bí ó ṣe wá sí ìmúṣẹ láàárín ọdún márùn-ún láti ọdún 2019.

Ká Ìròyìn: Àwọn Ìkà Èèyàn Fẹ́ Pààrọ̀ Ẹran Dáradára Pẹ̀lú Ẹran Ayédèrú

Ọ̀gbéni òyìnbó náà sọ síwájú pé àwọn ṣ’àdédé gbé orílè-èdè America tàbí Europe kalẹ̀ sì gbàgede gbogbo àgbáyé olọ́dọọdún yìí kí àwọn lè máa ṣe ètò lóríi bí a ṣe ń pò òògùn pọ̀ tí àwọn sì máa yọnda àwọn òògùn náà si àwọn orílè-èdè l’agbáyé.

 

Ọmọ Yorùbá, Ẹ Jẹ́ Kí A Kíyèsíara Nípa Òògùn Lílò

 

Mo mọ, ìbéèrè tí ń ta’wọ́ tá’sẹ̀ nínú ẹni kọọkan wá ni wípé, èrèdi ẹ?.

Ìdí ni pé àwọn pinnu láti dín iye ènìyàn tí ó wà ní gbogbo àgbáyé kú sí ìlàjì. Ipaṣẹ èyí ni àwọn ṣe pinnu oògùn pípò pò àti ibi tí àwọn máa yọnda wọn sí.

Bí ó ṣe ń s’àlàyé yí ló ṣe ń fi ayọ̀ hàn pé àwọn ṣe àṣeyọrí, tí àwọn ènìyàn tó kù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣáa ní àtẹ́wọ́, hmm. A ò wá  mọ nkan tó npa wọ́n l’ayọ̀ o!

 

Democratic republic of the Yoruba ominira news update | Yoruba Nation

 

Ẹ jẹ́ kí àwa náà bojú wo ẹyìn láti ọdún 2019, k’á wo’lẹ̀ ká tun w’ẹnu ọkọ́, kí á wá rántí àwọn orísìírísìí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ti là kọjá, èyí tí ó ti mú ẹ̀mí ọpọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn lọ, fún àpẹẹrẹ ẹ rántí àkókò Covid-19 bí rẹrẹ ṣe run.

Ká Ìròyìn: Àjàkálẹ̀-Àrùn Ún Ṣẹ́ Yọ N’ílùú Ìpínlẹ̀ Èkó, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Yorùbá

Kò tún wá tán s’íbẹ̀ o, ara rẹ̀ náà ni ìròyìn ikilọ tí a kà fún wa ní’gbà kan rí, nípa èso ọ̀gbin tí a pè ní ayédèrú, èyí tí a rí àwọn orílẹ̀-èdè àwọn agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà tí a ti jáde nínú rẹ̀ báyi, ti wón ti tẹ́’wọ́ gbàá, (a rí èyí lórí ayélujára).

Èròngbà àwọn àṣìtáánì òyìnbó wọ̀nyí kò dára rárá. Gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí á mọ̀ wípé orílẹ̀-èdè aṣè’jọba-ara-ẹni ni wá, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.

Nítorí èyí, a kò gbọ́dọ̀ ní ìrònú àwọn ẹrú rárá! A níláti mọ̀ wípé kò s’ẹni t’ó fi àwọn òyìnbó wọ̀nyí jẹ oyè olùda’rí àgbáyé! Wọ́n nlòó fún wa ni, k’awa náà máà dapadà fún wọn!