Ṣebí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a máa ngba ara wa níyànjú, pé, kí a ṣọ́ra: kó bàá dáa náà ni.

Ìkóríta tí a dé yí, gba àfojúsùn gidi: a kò gbọdọ̀ gbàgbé pé àjèjì ni Nàìjíríà jẹ́ lórí ilẹ̀ wa; agbésùnmọ̀mí ni wọ́n; afipá jẹgàba sórí orílẹ̀-èdè tí kìí ṣe tiwọn ni wọ́n, ọ̀daràn ni wọ́n; apààyàn dẹ̀ ni wọ́n jẹ́ lórí ilẹ̀ wa.

Ọ̀nà míràn tí eléyi tún fi ṣe pàtàkì fún wa láti ṣe àkíyèsí rẹ̀, ni pé, bí wọ́n ṣe njẹgàba lórí ilẹ̀ wa yí, ọ̀rọ̀ ẹni tó fa gbùrù, tí gbùrù fa’gbó ni: àwọn oríṣiríṣi ìwà pálapàla wọn ni a nílati ri pé a ò gbà láyè láti ta bá wa.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

A gbọ́ pé nínú ìwà ìbàjẹ́ wọn, wọ́n á fi owó ránṣẹ sínú àpò ilé-iṣẹ́-ìfowópamọ́ ẹlòmíì, wọ́n á wá sọ pé ó ṣèṣì ni, àti pé kí ẹni náà báwọn dá owó ọ̀ún padà, tí ó sì jẹ́ pé ọ̀nà àti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún owó náà ni (money laundering).

Tí ó bá jẹ́ pé kò sí ajẹgàba nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa ni, ṣèbí tó bá ní ohun tí a fura sí, a máa fi tó àwọn agbófinró orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùba ni – (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y); ṣùgbọ́n níkoríta tí a dé yí, ọ̀tá ni ọlọ́pa nàìjíríà jẹ́ lórí ilẹ̀ wa, wọn ò kì nṣe òṣìṣẹ́ Orílẹ̀-Èdè D.R.Y

Nítorí náà, gbogbo àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ ní sùúrù, àkókò díẹ̀ lókù, ẹ má jẹ̀ẹ́ kí a máa wá owó ní ọ̀nà tí kò tọ́, ìwà tí kò bójú mu ni eléyìí jẹ, nítorí pé ìsèjọba Orílẹ̀ Èdè D.R.Y kò ní gba ìwà ibi láàyè rárá.