Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́lọ́wọ́, ní jàjójàyó, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Yorùbá, fi hàn, gbangba wípé, àwọn ọlọ́pá nàìjíríà, àti ìlú agbésùnmọ̀mí wọn tí ó rán wọ́n níṣẹ́, ti tún bẹ̀rẹ̀ ìwà ipá lórí ilẹ̀ Yorùbá lọ́nà míì o.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ìròhìn tí àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wa fi tó wá létí, sọ wípé, káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, báyi, nṣe ni àwọn ọlọ́pa ìlú agbésùnmọ̀mí, Nàìjíríà, nṣe ìbẹ̀wọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ (telephone) tí àwọn ènìyàn bá mú dání láarin ìgboro, wọ́n á sì máa wá ohun tí ó bá jọ mọ́ ìrìnàjò àti òmìnira orílẹ̀-èdè Yorùbá. Tí wọ́n bá ti wá rí irúfẹ́ ohun bẹ́ẹ̀, nṣe ni wọ́n á wá mú ẹni náà lọ sí ibi tí a kò mọ̀! bóyá nṣe ni wọ́n nlọ ṣe’kú pa wọ́n ni, a kò mọ̀ o!

Democratic republic of the yoruba todays news

Nítorí eléyi, ẹ jọ̀wọ́, àṣẹ ti jáde o, wípé, gbogbo ọmọ Yorùbá, ibikíbi tí ẹ bá ti rí àwọn ọlọ́pa Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè Yorùbá, nípàtàkì, ibi tí wọ́n ṣùpọ̀ sí, ẹ máa bá wa ya fọ́tò wọn – a fẹ́ rí ojú wọn gan-gan, kí ẹ sì fi ránṣẹ́ sí àwọn tí ó wà ní ojúṣe iṣẹ́ fún orílẹ̀-èdè Yorùbá.

Ẹ jọ̀wọ́, kí ẹ ri wípé ẹ gbé ojú àwọn ọlọ́pa náà síta nínú fọ́tò ọ̀ún; kí ẹ sì jẹ́ kí á mọ̀ ìpínlẹ̀ Yorùbá tí ẹ ti rí wọn, àti agbègbè ibẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà, àti ojọ́ pẹ̀lú oṣù tí ẹ ya fọ́tò náà.

Bẹ́ẹ̀ náà ni a tún gbọ́ wípé, ohun tí ìjọba náìjíríà tún nṣe ní orílẹ̀-èdè Yorùbá báyi ni wípé, wọ́n ti da àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tiwọn síta o! Wọ́n á ṣe bíi kòjẹ́ wèrè, kò jẹ́ oní  báárà, wọ́n wà káàkiri àwọn àdúgbò ní ilẹ̀ Yorùbá. Wọ́n ti’lẹ̀ le máa béèrè lọ́wọ́ yín wípé báwo ni ọ̀rọ̀ orílẹ̀ èdè Yorùbá ṣe nlọ lọ́wọ́ báyi? tàbí kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa fi dá ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè Yorùbá, sílẹ̀.

Iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ni wọ́n nṣe fún Nàìjíríà. Ẹ ṣọ́ra fún irúfẹ́ wọn. Kí ẹ sì tètè jẹ́ kí àwọn olórí wa kí ó mọ̀ – ibi tí ẹ ti rí irúfẹ́ àwọn bẹ́ẹ̀. Tí ẹ bá ṣọ́ wọn dáradára, ẹ̀ẹ́ ri wípé, tó bá ti ndi wípé ilẹ̀ nṣú, ọkọ̀ “pick-up” máa nlọ káàkiri, tí ọkọ̀ náà á sì máa gbé àwọn ènìyàn wọ̀nyí káàkiri ibi tí wọ́n wà.

Ẹ má ṣe fi ara sílẹ̀, rárárárá, ọmọ Yorùbá.