Àkókò ìkìlọ̀ l’a wà yí o! Ẹni a bá wí, Ọba jẹ́ k’ó gbọ́!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ṣé kòì tíì pẹ́ s’ẹhìn, tí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún agb’ẹjọ́rò, Òṣíbàjò, wípé kí ó ṣọ́’ra l’ati má ṣe da’ra pọ̀ pẹ̀lú àwọn Fúlàní Nàìjíríà tí wọ́n fẹ́ lòó l’ati ṣe àtakò ìran Yorùbá, l’atàrí wípé wọ́n fẹ́ fi ipá dá Yorùbá padà sí’nú Nàìjíríà! Èèwọ̀! L’ara àwọn Fúlàní tí orúkọ wọ́n jẹyọ ní àkókò ìgba náà, ni àwọn bíi Sultan ti Ìlú Ṣókótó; Màlàmí, Abdusalam Abubakar, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

 

Yoruba Nation sends out strong warnings to osinbajo

 

Àwọn ọmọ Yorùbá tún ti wá ṣe ìkìlọ̀ míràn fún Òṣíbàjò, báyi, ní ọjọ́ àbámẹ́ta tí ó kọjá yí, wípé, Àwọn Fúlàní wọ̀nyí ṣì mbọ̀ o!

Wọ́n á tún wá ba ẹ l’aìpẹ́ yí, l’ati lò ẹ́ ta dí’nà Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, àti l’ati fẹ́ lò ẹ́ ṣe iṣẹ́ burúkú wípé kí Yorùbá lè padà, ÈÈWỌ̀!!

A wá sọ fún ẹ o, Òṣíbàjò, wípé àwọn Fúlàíní wọ̀nyí áá tún kàn sí ẹ láìpẹ́ sí’bi t’áa wà yí o. Wọ́n níi l’ọkàn wípé, tí o kò bá gbà fún wọn, tàbí o kò dá ‘wọn l’ohùn, wọ́n á gb’ìyànjú l’ati pe ìyàwó ẹ; ní èròngbà àti wọ’lé sí ẹ l’ara nípa’sẹ̀ ìyàwó ẹ!

Tí o kò bá pàpà dá’wọn l’ohùn náà, wọ́n ngbèrò wípé àwọn á gba ọ̀dọ̀ Màmá Tòkunbọ̀ Awólọ́wọ̀-Dòsùnmú wọ’lé sí ẹ l’ara! Ṣé o mọ̀ wípé wọ́n ti npè ẹ́, tí oò dá’wọn l’ohùn; nítorí náà, àwọn ọ̀nà tí wọ́n tún fẹ́ gbà ni’wọ̀nyí o!

A ní k’á sọ fún ẹ ni o! Àò sọ wípé k’oo má ṣe nkan aburú tí wọ́n fẹ́ fi rán ẹ o, ṣùgbọ́n, mọ̀ wípé, t’oo bá tẹ́’rí si, wàá pá l’orí!

 

Yoruba Nation sends strong warning to Osinbajo Yemi

 

Eléyi yàtọ̀ sí àkókò Ṣónẹ́kàn o! Ó dẹ̀ yàtọ̀ sí ìgbà ti Abdusalam àti Abíọ́lá àti Ọbásanjọ́ o! Eléyi yàtọ̀ o! Orílẹ̀-Èdè Yorùbá tí kúrò nínú Nàìjíríà, PÁTÁPÁTÁ!

Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìgbésẹ̀ k’igbésẹ̀ tí ẹnik’ẹni le gbé, tí ó lè dá wa padà sí’nú Nàìjíríà mọ́, l’ayé!

Kò sí nkan t’ó kàn wá pẹ̀lú wípé o jẹ́ àna Awólọ́wọ̀ o! Ìyẹn ò kàn wá rárá! Má ti tẹ́’rí si ni!