Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá l’ọwọ́ sọ wípé wọ́n ti rí obìnrin ọmọ Íbò kan o, pẹ̀lú àwọn ọmọdé l’ọdọ̀ rẹ̀, tí ó jígbé. Ó ní òun máa nta ìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọ tí òun bá jígbé, ní àádọ́ta ẹgbẹ̀rún owó naira. Ọmọ márun ni wọ́n bá l’ọwọ́ obìnrin Íbò náà. 

Democractic Republic of the Yorùbá newest nation in the world - Òmìnira daily news updates.

 

Bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé, Ìjọrá l’ó sọ wípé òun tí jí àwọn ọmọ náà, Ìsàlẹ̀-Èkó, ní ojú’rówò, l’ọdọ̀ àwọn Fọ̀’lúmọ́, ni ìròhìn náà sọ wípé obìnrin náà wà, ní àkókò ìròhìn náà. Ẹnik’ẹni tí ó bá mọ ẹni t’ó ní ọmọ tí wọ́n nwá ní agbègbè Ìjọrá, kí wọ́n lọ sí ojú’rówò ní Ìsàlẹ̀-Èkó, l’ọdọ̀ àwọn Fọ̀’lúmọ́.