Ọmọ Fúlàní, Dangote, ni àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá tún ti ṣe ìkìlọ̀ fún o, tí wọ́n sì sọ fun wípé, ọ̀nà méjì ni àwọn oríṣiríṣi ohun tí àwọn nri, tí ó nṣe l’orí ilẹ̀ Yorùbá já sí.

L’ọnà kíní, gbogbo àdé’hùn k’adéhùn tí ó bá ṣe pẹ̀lú Nigeria l’orí ilẹ̀ Yorùbá, l’ẹhìn ogúnjọ́ oṣù kọ́kànlá, ọdún 2022, òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀ ni o! Òfo l’ó já sí, tí kò sì l’ẹsẹ̀ nlẹ̀ rárá!

Yoruba Nation warns dangote of Nigeria. Democratic republic of the Yoruba

Ka Ìròyìn: The Democratic Republic of the Yoruba is Sacrosanct

Ọ̀nà kéjì, gbogbo irúfẹ́ àdéhùn bẹ́ẹ̀ l’orí ilẹ̀ Yorùbá, l’ati ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin, 2024 yí, ọ̀ràn dídá ni’yẹn o!

Ẹ rántí wípé ni ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin, 2024 ni Orílẹ̀-èdè Yorùbá gba agbára ìjọba Olómìnira ara rẹ, ti o si ní àṣẹ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá. Orílẹ̀-èdè Yorùbá ki ńṣe Nigeria mọ; fun idi eyi, ẹni’létí ko gbọ! 

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ka Ìròyìn: The Geographical Map of YorubaLand – The Democratic Republic of Yoruba