Ẹnik’ẹni ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) tí ó bá fẹ́ gbé àpótí Ìbò nígbàkúgbà, kí ó mọ̀ báyi wípé kò ní ọ̀rọ̀ owó nínú o.

Màmá Modúpẹ́ Onítirí aya Abíọ́lá sọ wípé ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nìkan ni ó le gbé'gbá ìbò ní D.R.Y. Ibik'ibi tí o bá dẹ̀ ti fẹ́ gbè'gbá ìbò, o ní l'ati jẹ́ olùgbé ibẹ̀! Share on X Kò sí wípé iye owó bái ni o máa fi gba ìwé pé o ní’fẹ́ àti gbé’gbá ìbò, rárá o!

Ẹnik’ẹni tí ó bá sì tìtorí ẹni t’ó fẹ́ gbé’gbá ìbò, tí ó ntìtorí ẹni bẹ́ẹ̀ ná’wó fún ará ìlú, àti ẹni tí ó ná’wó, àti ẹni tí wọ́n t’orí ẹ̀ ná’wó, àwọn méjèèjì máa ṣ’ẹ̀wọ̀n.

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèjì á sì wọ inú ìwé àwọn ẹni burúkú ní ilẹ̀ Yorùbá, títí ayé.

Ka Ìròyìn: Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá S’ọ̀rọ̀ Ní Àyájọ́ June 12
June 12 remember MKO Abiola | Chief Mrs. Modupeola Onitiri-Abiola

L’ọnà kéjì, Màmá Modúpẹ́ Onítirí aya Abíọ́lá sọ wípé ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nìkan ni ó le gbé’gbá ìbò ní D.R.Y. Ibik’ibi tí o bá dẹ̀ ti fẹ́ gbè’gbá ìbò, o ní l’ati jẹ́ olùgbé ibẹ̀!

Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá tún sọ wípé gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe aṣojú ní ìṣèjọba ọmọ Yorùbá níláti bu ọ̀wọ́ lu ìwé àdéhùn.

Ọmọ-Alade Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá Ṣe Àlàyé Nípa Ìbò Dídì Ní Democratic Republic of the Yoruba

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ wípé ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), kò ní sí ìgbìmọ̀ tí ó nbojútó ètò ìdìbò. Kò sì sí ìrírí àti máa lọ sí’lé ẹjọ́ l’ẹhìn ìdìbò. Bẹ́ẹ̀ náà ni kò ní sí wípé a nlọ ka ìbò nínú ilé ọ̀tọ̀ tí ó yàtọ̀ sí’bi tí a ti d’ìbò.

Ẹnik’ẹni tí ó bá fẹ́ gbé’gbá ìbò gbọ́dọ̀ ní iṣẹ́ òòjọ́ tirẹ̀. Kò sí owó oṣù fún ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe òṣèlú ní D.R.Y. Bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí wípé o ò ní jẹ́’jọ́ tí o bá ṣẹ̀.

June 12 - MKO Abiola | Chief Modupeola Onitiri Abiola

Right click to save/download a copy