Ọmọ àlùfáà Adébóyè, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Adéolú Adébóyè, ni ìròhìn tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní yàjóyàjó pé ó jí bílíọ̀nù mẹ́jọ owó náírà ní Nàìjíríà, látàrí pé ó ti gba owó yí sápò, fún iṣẹ́ pópónà ní Ìpínlẹ̀ Kaduna wọn lọ́hun, gẹ́gẹ́bí agbaṣẹ́ṣe.

Lẹ́hìn tí ó ti gba òbítíbitì owó yí, ìròhìn náà sọ pé kò wá yà síbi tó ti nṣeṣẹ́ náà mọ́!

Èyí ni ó wá mú kí àjọ wọn ní Nàìjíríà tí npẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìkówójẹ àti bíba ọrọ̀-ajé ìlú jẹ́ (EFCC), kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá Adéolú Adébóyè kiri o.

Ṣùgbọ́n ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ nísiìyí sọ pé Adéolú Adèbóyè ti sá lọ sí ilé-ẹjọ́ ní ìlú Èkó ní Democratic Republic of the Yoruba wa yí, níbi tí Nàìjíríà ti nfi’pá jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, pé kí ilé-ẹjọ́ náà ó dẹ́kun EFCC, Ọ̀gá-Ọlọ́pa Nàìjíríà, Ìgbá-kéji ọ̀gá-ọlọ́pa wọn, ọ̀gá-ọlọ́pa Nàìjíríà tó jẹgàba sí ìpínlẹ̀ Èkó, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kaduna ní Nàìjíríà wọn lọ́hun, àti Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin wọn ní Ìpínlẹ̀ Kaduna náà, pé kí ilé-ẹjọ́ ó bá òun dẹ́kun wọn, kí wọ́n máṣe máa tẹ ẹ̀tọ́ òun gẹ́gẹ́bí ọmọ-ènìyàn lójú.

A ò wá mọ̀ bóyá ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni o, láti gba bílíọ̀nù mẹ́jọ náírà fún iṣẹ́ tó sọ pé òun máa ṣe fún Ìpínlẹ̀ Kaduna wọn, tó dẹ̀ kúrò ní’di iṣẹ́ náà, tí kò ṣeé, gẹ́gẹ́bí ìròhìn náà ṣe sọ.

Pastor Adeboye's son after 8 billion Naira stolen public fund

Èyí tí ó ti ẹ kàn wá ni pé ṣé ẹni tó pe’ra rẹ̀ ní ọmọ Yorùbá ni eléyi ṣá? Èkejì nií pé, kí wọ́n tilẹ̀ kó gbogbo bó ṣe nṣe wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), kí wọ́n lọ pe ẹjọ́ wọn sí Nàìjíríà.

Pabambarì tí àwọn ènìyàn ní tiwọn ti ẹ̀ nsọ ni pé ṣebí bàbá Adéolú Adébóyè yí sọ pé ogun ẹ̀mí ni ó njà wọ́n ní Nàìjíríà? Á fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ọmọ rẹ̀ gan-an gan ni ogun-ẹ̀mí ọ̀ún!

Tí ó bá jẹ́ ogun ẹ̀mí ló nja Nàìjíríà, ó yẹ kí Adébóyè ó lè wá nkan ṣe si! Báwo ni ọmọ tirẹ̀ ṣe wá kó owó láìṣeṣẹ́? Ṣé ogun-ẹmí ja ọmọ náà ni?

Ó pẹ́ tí wọ́n ti máa nsọ fún wa, pé, àwọn tí ó pera wọn ní ìránṣẹ́ ọlọ́run wọ̀nyí ni àwọn òyìnbó amúnisìn máa nlò láti tẹ orí ará-ìlú ba, kí wọ́n máṣe lè sọ̀rọ̀ tàbí gbé ìgbésẹ̀ nígbàtí wọ́n bá nfi ìyà jẹ wọ́n!

Ojú olè rèé! Àwọn tí wọ́n pera wọn ní ojíṣẹ́ ọlọ́run pẹ̀lú àwọn tí òyìnbó nlò láti fi àwọn ènìyàn sábẹ́ amúnisìn wọ̀nyí! Ìránṣẹ́ òyìnbó ni wọ́n!

Pastor Adeboye son with N8billion stolen fund - Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!