Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ wọn, nìyí:

 

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Olódùmarè, Ọba àjíkẹ́ Ayé, Ọba Àṣàkẹ́ Ọ̀run, Ọba Adẹ́da, òun Aṣẹ̀dá, fún Àánú àti Àbò tó péye, lórí gbogbo ọmọ Yorùbá, nílé, lóko, àti lẹ́yìn odi.

Mo kí gbogbo ẹ̀yin ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, wípé, ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta. Iṣẹ́ ló gbomimu lọ́wọ́ wa. A kò sì dáwọ́ iṣẹ́ dúró rárá. Ẹ má ṣe bínú sí wa.

Mo kí ẹ̀yin ológun wa, tó ní ìkọlù àwọn agbésùnmọ̀mí ìjọba Nàìjíríà, wípé, ẹ kú ìdúró ṣinṣin, ẹ sì kú ọkàn akin. Mo sì tún kí àwọn ẹbí yín wípé, wọ́n  kúu àtìlẹyìn yín.

ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ LÓRÍ AWUYEWUYE ÀTI ÌṢẸ̀LẸ̀ TÓ NṢẸLẸ̀ KÁÀKIRI LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, LÁTI ORÍ NKAN Ọ̀GBÌN OLÓRÓ, ÀTI ÌGBÀLÁÀYÈ ÌBÁLÒPỌ̀ ỌKÙNRIN-SỌ́KÙNRIN, TÀBÍ OBÌNRIN-SÓBÌNRIN, TÍ ÌJỌBA ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ṢAGBÁTẸRÙ RẸ̀, TÍ Ó SÌ NJẸGÀBA… Share on X

Mo wá kí Olóyè, Ìyá-Ààfin wa; Modúpẹ́ Onítrí-Abíọ́lá, ìyá Yorùbá, fún àṣeyọrí iṣẹ́ Ìran Yorùbá, débi tó lààmìlaka, tí iṣẹ́ sì ntẹ̀síwájú, ní gbogbo ìgbà, láì dáwọ́ dúró.

Mo kí gbogbo ẹ̀yin ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wa, fún iṣẹ́ takuntakun, lóní ràbájìgan, tí ẹ nṣe, láti ìgbà dé ìgbà, tí ẹ kò sì dáwọ́ dúró. Gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nkí yín wípé, ẹ ṣeun gidi gan-an.

Olórí Adelé Bá Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, Sọ̀rọ̀, Ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹ́san, Oṣù Kéje, Ọdún 2024

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá àti Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà máa pàdé nílé Ẹjọ́ Àjọ Ìgbìmọ̀ Àgbáyé.

Àwọn ọmọ àlè Yorùbá lọ nkó àwọn àjòjì wọlé, sórí ilẹ̀ Yorùbá, láti máa wa kùsà tó jẹ́ ti Orilẹ̀-Èdè Yorùbá, tí ebi sì npa àwọn èèyàn wa, tí àgbàrá omi òjò sì nya wọ gbogbo ilé ní ilẹ̀ Yorùbá.

Àwọn nkan burúkú nṣẹlẹ̀ káàkiri, bí ìjọba Nàìjíríà ṣe nṣagbátẹrù àwọn nkan burúkú lórílẹ̀-èdè Yorùbá, láti sa gbogbo ipá lòdì sí ìtẹ̀síwájú àti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní sàn-án-sàn-án lórílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Yoruba.

Ìjà Orílẹ̀-Èdè sí Orílẹ̀-Èdè ni èyí jẹ́. Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba máa pàdé Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà ní ilé Ẹjọ́ Àjọ Ìgbìmọ̀ Àgbáyé, láìsí àní-àní kankan.

Ìjọba Nàìjíríà ti sa gbogbo ipá rẹ̀, láti ìta wá; wọ́n sì ti sọ fun wípé ìjọba Democratic Republic of the Yorùbá ti dúró, kò dẹ̀ sí ohun kan tí ẹnìkan lè ṣe si. Nítórí náà ló ṣe ngbé gbogbo ìgbésẹ̀ láti dí wa lọ́wọ́ iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Yorùbá, nípa lílo agbára ìjẹgàba àti agbésùnmọ̀mí lórí ilẹ̀ àwọn Babanlá wa.

Gẹ́gẹ́bí ọmọlúàbí tó lóye, tó lọ́gbọ́n, tó sì tún ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, a kò níí jà, ṣùgbọ́n a máa dáàbò bo ara wa.

Ìpàdé di Ilé-Ẹjọ́ Ìgbìmọ̀ Àjọ Àgbáyé, láarín Orílẹ̀-Èdè D.R.Y àti Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà. Láìpẹ́, láìjìnnà, ijọba Nàìjíríà máa di ohun ìgbàgbé pátápátá. Mo fẹ́ kí gbogbo ẹ̀yin ọmọ Yorùbá àtàtà, lọ fi ọkàn yín ba’lẹ̀. Ìgbà díẹ̀ báyi l’ó kù, tí gbogbo wa máa wá ṣàjọyọ̀ òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, káàkiri ìpínlẹ̀ méjèèje.

Ìjọba ìjẹgàba àti agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ti túbọ̀ lọ kó àwọn ológun wọn, púpọ̀, sí gbogbo ẹnu ibodè tó wọ’lé sí Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, Democratic Republic of the Yoruba, láti dínà wa, kí onjẹ má lè wọlé sí Ilẹ̀ Yorùbá, kí ebi lè lu àwọn ènìyàn pa.

Ìjọba Nàìjíríà tún kó àwọn ọlọ́pa jọ, káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, láti máa dá àwọn ènìyàn wa dúró lọ́nà, tí wọ́n sì máa gba ẹ̀rọ alágbeká wọn, láti máa wá gbogbo ohun tó bá jọ mọ́ Democratic Republic of the Yoruba lórí ẹ̀rọ wọ̀nyí. Látàrí eléyi, wọ́n á sì gbé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ lọ, tó sì máa pòórá, tí kò ní padà mọ́!

Ẹ jọ̀wọ́, mo fẹ́ bẹ gbogbo ẹ̀yin ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá lọ́wẹ̀. Níbikíbi tí ẹ bá ti rí àwọn ológun, tàbí ọlọ́pa Nàìjíríà, lórí ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n kóra jọ, ní méjì-mẹ́ta, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ fi ẹ̀rọ alágbeká yín, kí ẹ fi yàwòrán wọn, kí ẹ sì ṣe fídíò, tó bá ṣèéṣe, kí ẹ sì fi ṣọwọ́ sí wa. Eléyi máa jẹ́ ara àwọn ẹ̀rí máa-jẹ́-mi-nìṣó, nítorí wípé, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Yorùbá máa pàdé ìjọba Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà ní ìlé-ẹjọ́ Ìgbìmọ̀ Àjọ Àgbáyé, tí kò pẹ́ mọ́. 

Gbogbo gómìnà-ìjẹgàba àti agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ní Orílẹ̀-Èdè Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y, pẹ̀lú àwọn Ọba Nàìjíríà, tí wọ́n jọ njẹ ìlú run, ngbé oríṣiríṣi ìgbésẹ̀, káàkiri ìpínlẹ̀ méjèèje ti Yorùbá, láti máa tẹ ọwọ́ bọ ìwé, pẹ̀lú àwọn àjòjì, láti máa ta àwọn àlùmọ́nì ilẹ̀ wa síta. Mo fẹ́ rán ìjọba Nàìjíríà létí wípé, láti ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹ́rin, ọdún 2024, tí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀, ni gbogbo iṣẹ́, òwò, àti gbogbo ohun tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí ilẹ̀ Yorùbá, ló lòdì pátápátá sí òfin Orílẹ̀-Èdè D.R.Y àti òfin Ìgbìmọ̀ Àjọ Àgbáyé.

Ìjà Orílẹ̀-Èdè sí Orílẹ̀-Èdè ni ó wà nílẹ̀ yí. A kò ní jà, ṣùgbọ́n a máa dáàbò bo ara wa. Ìpàdé àwa àti ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà di ilé-Ẹjọ́ ÌGBÌMỌ̀ ÀJỌ ÀGBÁYÉ. Gbogbo ohun tí ó nrùn nílẹ̀ máa tó kúrò nílẹ̀! Mo fẹ́ kí ẹ túbọ̀ ṣe sùúrù díẹ̀ si. A máa tó gbégbá ọpẹ́, láti yin Ọlọ́run Olódùmarè.

Ìkìlọ̀ ré, fún àwọn ọ̀dọ́. Mo fẹ́ bá ẹ̀yin ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀, nítorí wípé, tìtorí tiwa ni Màmá wa, MOA, ṣe dìde, láti jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn sí Ìran Yorùbá.

Ẹ má ṣe ṣe ìkórajọ láti ṣe ìwọ́de kankan ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá. Gbogbo ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Kenya, yàtọ̀ pátápátá sí ìrìn-àjò Orílẹ̀-Èdè Yorùbá. Wọn kò jọra rárá.

Orílẹ̀-Èdè Kenya njà nítorí ìwà àjẹbánu jẹgúdújẹrá olórí Kenya àti ìṣèjọba rẹ̀; ṣùgbọ́n, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá njà nítorí ìjẹgàba àti agbésùnmọ̀mí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà nínú Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Yorùbá, Democratic Republic of the Yoruba. Ìjà ti’wa jẹ́ ìjà Orílẹ̀-Èdè sí Orílẹ̀-Èdè, wípé kí Orílẹ̀-Èdè Nigeria já’de kúrò, pátápátá, nínú Orílẹ̀-Èdè Yorùbá. Ìyàtọ̀ tí ó wà ní’bẹ̀ n’ìyẹn. Nít’orí náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ lọ ṣe sùúrù díẹ̀ si ni.

Ní kòpẹ́kòpẹ́ yí, ẹ máa gbọ́ ìró ayọ̀. Ẹ má ṣe ìwọ́de pẹ̀lú ẹnik’ẹni; kí ẹ máṣe jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀mí yín w’ewu. Ẹ lọ fi ọkàn yín ba’lẹ̀, a ti dé ibi ìṣerere wa. Kíún báyi ni ó kù, tí gbogbo wa máa wá ṣe àjọyọ̀ sí Ọlọ́run, fún òmìnira Orílẹ̀-Èdè Yorùbá.

Olórí Adelé Bá Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, Sọ̀rọ̀, Ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹ́san, Oṣù Kéje, Ọdún 2024

Ìjọba Nàìjíríà, pẹ̀lú àwọn gómìnà rẹ̀, ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, àti àwọn Ọba, àti àjòjì, agbésùnmọ̀mí, tí wọ́n ngbé’ni pa, tí wọ́n sì nfi ẹran wọn jẹ oko ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, ni wọ́n máa parẹ́ l’orí ilẹ̀ wa l’aìpẹ́.

Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo “ilé-ìwòsàn” ikú tí wọ́n kọ́, àti irúgbìn olóró, GMO, àti gbogbo ilé-iṣẹ́ tí àwọn àjójì np’ètep’èrò l’ati dá sí’lẹ̀, títí mọ́ àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó ta’pá l’òdì sí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba, ni ó máa di ohun ìgbàgbé pátápátá, tí a kò ní gbúro wọn mọ́, tí ayé bá njẹ́ ayé, tí ọ̀run bá sì njẹ́ ọ̀run.

Ẹ̀yin ènìyàn, ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a ṣe sùúrù, nítorí wípé sùúrù tó ní ọjọ́ lórí ni. Kò ní pẹ́ mọ́ rárá, tí ipè tí ẹ ti nretí máa dún. Ẹ jẹ́ kí á fi ọkàn ba’lẹ̀.

Mo fẹ́ kí ẹ máa ṣe ìgbáradì àti ìpalẹ̀mọ́ fún àjọyọ̀ t’ó nbọ̀ l’ọnà, tí ipè bá ti dún, tí a sì máa jádé, láti wá ṣe àjọyọ̀ yí ní pápá ìṣeré tó tóbi jùlọ ní ìpínlẹ̀ méjèèje ti Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, Democratic Republic of the Yoruba.

Àjọyọ̀ tí ó lààmìlaka níwájú Ọlọ́run Olódùmarè ni eléyi jẹ́, tí a sì máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wa l’oní-ràbájìgan pẹ̀lú eré lẹ́sẹ̀.

Mo kí wa, lẹ́ẹ̀kan si, wípé, a kú ìfojú sọ́nà ọjọ́ ayọ̀ yí.

Tóò, mo wá dánu dúró ná. Kí Ọlọ́run Olódùmarè kí ó mú ọjọ́ náà ró, kí Ó sì bùkún ẹni’kọ̀ọ̀kan wa gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ti Orílẹ̀-Èdè Tiwantiwa ti Yorùbá, I.Y.P, D.R.Y