Ẹ wá wojú àwọn ọlọ́ṣà àti adigun jalè ní pópó, èyí tí ọ̀kan lára àwọn akéde ìlú ajíríyà sọ nípa wọn, ní ti iṣẹ́ ìbí tí wọn fẹ́ ṣe lórí ilẹ̀ olómìnira, ilẹ̀ Yorùbá, DRY, èyí tó sì sọ wípé kí àwọn ọlọ́ṣà dẹgun de àwọn adigunjalè tí wón ń kó wọ orílẹ̀ èdè yorùbá, DRY, bẹ̀rẹ̀ láti olú ìlú ilẹ̀ Yorùbá, ìlú Ìbàdàn, ìpínlè Èkìtì àti ìpínlè Ògùn.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Àwọn wo ni Ọlọ́ṣà? Àwọn wo ni adigunjalè? Àwọn ọlọ́ṣà ni  àwọn ọba tí wọ́n ń pè ní kábíyèsí tówà lórí ilẹ̀ IYP, tí ọ̀kan lára àwa ọmọ òmìnira sọ pé wọn kìí ṣe kábíyèsí, bíkòṣe káfiyèsíi, àti àwọn Gómìnà ìlú ajíríyà tó wà lórí ilẹ̀ IYP lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ìdí tí a fi pè wọ́n ní ọlọ́sà ni wípé, isẹ́ àti ìṣe wọn dàbí ti àwọn babańlá wọn ní àtijọ́, ní ti kíkó àwọn ènìyàn lérú, títa àwọn ènìyàn, títan àwọn ènìyàn jẹ, àti kí kó àwọn ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ Yorùbá tà fún awọ̀n àjèjì.

say no to gmo foods, seed, crop. yoruba warns african

Àwọn wo ni adigunjalè? Àwọn adigunjalè ni àwọn Fúlàní tí wọn ń gbé ní ìlú Ajíríyà, tí wọn ń fi ọwọ́ lalẹ̀ fún àwọn ìlú Ajíríyà, níbi tí Ọlọ́run ọ̀gá ògo jùlọ ti  fi ìwé (documentation) láti ọwọ́ ìyá wa, Olóyè MÓÀ, gba ilẹ̀ Torùbá, DRY, kúro, tí ilẹ̀ DRY ti wá di orílè èdè olómìnira báyìí; àwọn Fúlàní tí wón jẹ́ agbára àti ẹ̀mí Ajíríyà, tí wọ́n fi bàbá wọn, Ólulẹ̀, Akúwárápá, ṣe àrẹ wọn, àwọn ni adigunjalè. Àwọn méjèèjì yìí, ọlọ́ṣà àti adigunjalè, ìlú Ajíríyà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún. Ta ló ń tan tani? Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ màmá wa, ìyá gbogbo Yorùbá, Olóyè MÓÀ, ṣágo ń búgò ni gbogbo wọn pátá.

Democratic republic of the yoruba

Nítorína, àwa ọmọ òmìnira DRY, kí a májẹ kí wọn ó gọ̀ wá o. Kí àwa náà máṣe gọ ara wa. Nítorí, ọ̀kan lára ọmọ Yorùbá, IYP, ti sọ ọ́ lọpọ̀lọpọ̀ ìgbà, lórí agbagbe, wípé, àwọn abenugan ìjọba Ajíríyà, tí a mọ̀ sí Fúlàní, ti ṣe ìpàdé ní abẹ́lẹ̀ láti gba àwọn ọ̀dọ́ sínú ẹgbẹ́ ológun ìlú Ajíríyà, láti kọlu ilẹ̀ olómìnira Yorùbá, kí ó tó di oṣù owẹ́we nínú ọdún ẹgbàá kan ó lé mérìnlélógún tí a wà nínú rè yìí. Kí àwa ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá kíyèsára láti má bọ sínú  pańpẹ́ wọn.

Síwájú síi, lára ohun tí akéde ìjọba Ajíríyà sọ ni wípé, àwọn ìlú Ajíríyà ti ń kó oúnjẹ lọ sí orílẹ̀ èdè Nìjéè, àti pé, ìyẹn ni ó dífá fún ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ní ilẹ̀ Ajíríyà, tí orílẹ̀ èdè Yorùbá sí ní ìpín nínú rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, nítorí àwọn ọ̀jẹ̀lú ìlú Ajíríyà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ Yorùbá, ńṣe ìdíwọ́ fún bíbẹ̀rẹ̀ isẹ́ ìjọba àwọn adelé ní orílẹ̀ èdè Yorùbá, ní sansan. 

Haaaa! enu òpùrọọ́ kìí ṣẹ̀jẹ̀. Ṣé wọ́n bí babanlá ìjọba Ajíríyà dára, kí wọ́n wọ inú orílẹ̀ èdè Nìjéè? Orílẹ̀ èdè tí kòsé wọ̀, tí kò sé gbà kọjá fún àrẹ Ajíríyà, bàbá Abirùn. Èyí ni ẹ ó fi wá mọ̀ kedere wípé, olùkéde ìlú Ajíríyà ti fọ́ lójú, ó ti ya adití, ó tún jẹ́ òpè àti akíndanidání ẹ̀dá, tàbí kí ó mọ̀ọ́mọ̀ fé se bí aláìríran, aláìgbọ́ràn, afọ́jú, níti ìjọba adelé Yorùbá, DRY, tí ó ti wà lórí ilẹ̀ IYP, tí Ọlọ́run ti ti ọwọ́ ìyá wa, MÓÀ, gbà fún àwa ọmọ bíbí orílẹ-èdè olómìnira ilẹ̀ Yorùbá, IYP.

Lakòtáń, àwa ọmọ aládé ilẹ̀ Yorùbá, kí a má se fòyà, kí a máse bẹ̀rù; nítorípé, àwọn ọlọ́ṣà àti àwọn adigunjàlè tí a ńrí lónìí, lórí ilẹ̀ Yorùbá, DRY, akì yóò rí wọn mọ́ láéláé, gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe sọ fún àwọn ọmọ israel, pé, àwọn Egíbítì, ọ̀tá wọn, tí wọ́n rí lónìí, wọn kì yóò tún rí wọn mọ́. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Ọlọ́run ti gba ẹnu ìyá wa, Olóyè MÓÀ, sọ pé, àwa kí yóò rí wọn mọ́ láéláé nípa agbára tí Ọlọ́run fi dá ayé àti Ọ̀run.