Òkú ọ̀rọ̀ tí ìròyìn kan gbé jáde ní orí ẹ̀rọ ayélujára , nípa ọkùnrin Yorùbá kan tí wọ́n ní ó bẹ̀rẹ̀ sí ní mú orí àwọn ìran Ìgbò wú lòdì, nígbà tí ó ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ kan wípé, àwọn Ìgbò ni wọ́n kó ipa tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé gbogbo àgbáyé.

Ọkùnrin náà sọ ìdí tí àwọn ẹbí kan ní Amẹ́ríkà báyìí, fi dárapọ̀ mọ́ àti bá àwọn ìran Ìgbò ṣe àṣepọ̀.

Ó tún sọ síwájú síi wípé, ìbá ti dùn tó, tí Orílẹ̀-èdè akótilétà Nàìjíríà bá lè lo àǹfààní wíwà tí àwọn ìran Ìgbò wà láàrin wọ́n kí wọ́n fí ṣe àyípadà sí rere, kí ìlọsíwájú sì leè wà.

No to LGBTQ in Yorubaland | No to Vaccines in the Democratic Republic of the Yoruba

A rí ìròyìn yí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, ní òtítọ́, àwa Indigenous Yorùbá People, (I.Y.P.), tí jáde kúrò nínú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà láti ogúnjọ oṣù Bélú, Ẹgbàá ọdún ó-lé-méjì-lélógún, tí a tún tí bẹ̀rẹ̀ ìṣe’jọba ara ẹni tiwa, nígbà tí a ṣe ìbúra tán fún Olórí Adelé wa, bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ní ọjọ́ Kejìlá Oṣù Igbe, Ẹgbàá ọdún ó-lé-mẹ́rin-lé lógún, síwájú àkókò yìí ,kò yé wa ipa tí ọkùnrin yí wá ń sọ pé wọ́n kò o? ṣé ti àparútu wọn ni, àbí ti ìjínigbé pa’wó tí wọ́n jingíri nínú rẹ̀ ni wọ́n fi ń kó ipa nínú ìdàgbàsókè ni?

Àwa ọmọ Orílẹ̀ èdè Olómìnira Yorùbá Tiwantiwa, (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y.) ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ fún Olódùmarè tí ó fi màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, ṣe alágbàkalẹ̀ wa, kúrò láàrin àwọn agbésùnmọ̀mí, tí wọ́n mú wa padà sí orí ilẹ̀ àwọn bàbá wa.

Ọkùnrin tí ó sọ ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ lórí fọ́nrán náà, sọ ọ̀rọ̀ aláìlọ́pọlọ; nítorí ó hàn gbangba pé kò ní ìrònú tó jinlẹ̀; tó bá ní ìrònú tó jinlẹ̀ ni, ó yẹ kí ọpọlọ rẹ̀ lè sọ fun pé, gbogbo ohun tí ó ń sọ pé àwọn ìgbò nṣe ní ilẹ̀ Yorùbá, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣeé? Báwo ni wọ́n ṣe dé bẹ̀? Ìwà kí wọ́n máa jẹ gàba lórí ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá, òun ni wọ́n fi ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe! Ṣùgbọ́n, ó ti tán fún’wọn báyi o!

Ìran Ìgbò ti tẹ́ pátápátá ní ilẹ̀ Yorùbá; ìwọ tí o pe ara ẹ ní ọmọ Yorùbá, tí o sọ ọ̀rọ̀ aláìl’ọpọlọ yẹn, a rí ojú rẹ o, a mọ̀ ẹ́.

Kí gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ó fi ọkàn wa balẹ̀; lágbára Olódùmarè, a ti dé ibi t’a nlọ ná, inú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa káàkiri Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùba (D.R.Y) pẹ̀lú ìfọkànbalẹ̀, tí àwọn Ìjọba-Adelé wa máa tẹ̀ síwájú, lójú gbogbo wa, nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ní oṣù mẹ́rin-ààbọ̀ ó lé báyi; nígbà náà ni irọ́ kàbìtì tí àwọn ènìyàn rádaràda wọ̀nyí ń pa máa hàn sí ìgboro-ayé, tí ojú máa tì wọ́n pátápátá.