Nigbatí nwọ́n ṣe àjọ àpérò ìlọsíwájú Áfíríkà, Traórè sọ wípé àwọn òyìnbó fún wa ní òmìnira arúmọ́jẹ́, nwọ́n máa ń gbé àwọn tí nwọ́n ma lò láti ṣiṣẹ́ ibi fún nwọn sí ipò olórí, wọ́n ń ka àwa tí a wà ní Afíríkà sí ẹrú tí kò gbọdọ̀ kúrò ní ẹrú láé láé.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Nwọ́n á máa kó gbogbo ọrọ̀ àlùmọ́nì wa lọ fi tún ilú ti wọn ṣe, fún ogójì ọdún, nwọn ń kó Ùráníùm láti Nìéè lọ fi fún ara nwọ́n ni inà mọ̀nà mọ̀nà nígbàtí kò sí iná ni Nìjéè.

Nwọ́n ní kò sí owó ní Áfíríkà, a ní kí nwọ́n fi Áfíríkà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n nwọ́n sì kọ̀ láti lọ, nítorínà ni a ṣe gba ìjọba wa ní ọwọ́ wọn láti má ṣe àkóso orílẹ̀èdè wa, àwọn tí òyìnbó fi ṣe olórí ń jẹ gàba lórí ọmọ ìlú, àwọn olè, wọ́n tún máa jí owó wa kó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òyìnbó, gẹ́gẹ́ bí àwọn wèrè ọ̀jẹ̀lú tí nwọ́n wa ní ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wa, tí nwọ́n ń jẹ gàba lórí orílẹ̀ èdè náà, àwọn agbésùnmọ̀mí ti nwọ́n takú sórí ilẹ̀ ọmọ Yorùbá.

 

Òkò Ọ̀rọ̀ Ìbínú Tí Captain Traore Sọ Ní Nìjèè Nínú Àpérò Ìlọsíwájú Áfíríkà.

Awọ́n òyìnbó ní àwọn fẹ́ fi ìlú Ajíríyà ba àwa Nìjéè jà, ṣùgbọ́n àwọn kó ní gbà fún àwọn olórí kankan tí ó bá fẹ́ bá orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú kankan jà kí a mà dá síi, àwọn olórí orílè-èdè tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wa tí ń jẹ́ Nàìjíríà jẹ ara àwọn tí òyìnbó nlò, nítorínà ni nwọ́n ṣe takú sórí ilẹ̀ wa tí nwọ́n ń jí alùmọ́nì orílẹ̀ èdè wa kó lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlùmọ́nì wa ní àwọn ọ̀jẹ̀lú yìi jẹ́ kí àwọn ọ̀gá nwọn, òyìnbó, jí kó lọ tí wọ́n ń lọ fi tún orílẹ̀ èdè tiwọn ṣe, nígbàtí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè tiwa kò rí nǹkankan lò.

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Ọ̀rọ̀ rèé o, àwa IYP (Indegenous Yorùbá People), àwa ni Olódùmarè jogún ilẹ̀ DRY (Democratic Republic of Yorùbá) fún, ẹ jẹ́ kí a jáde, kí á tí màmá wa MOA (Modupeola Onitiri-Abiola) lẹ́yìn bí’gba eké tií f’ọwọ́ ti’lé, ẹ jẹ́ kí a jáde lọ́pọ̀ yanturu kí àwọn olè wọ̀nyí lè kúrò lórí ilẹ̀ wa, ẹrú òyìnbó ni nwọ́n, ti ara wọn níkan ni wọ́n mọ̀.