Lati ọwọ́ Dókítà Solomoni Ẹkúndayọ̀. Ọlọ́run nìkan ló mọ irúfẹ́ amúnimúyè tí wọ́n lò sí gbogbo wa ní ilẹ̀ Yorùbá. A ti sọ ara wa di ẹrú àwọn ará òkè ọya àti àwon onísòwò ẹyà Ìgbò. Níṣe ni akàn nrà tí a nrà lasán laìta ohunkóhun ju ilẹ̀ wa àti ohùn ìní wà fún wọn.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ariwisi wa nípa àìkòsí ààbò tí ó péye jẹ́ ọ̀rọ̀ rírùn lásán. Àìsí ààbò tí ó péye yí pọ̀ ní òkè ọya ju ọ̀dọ̀ wa lọ, síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n n pèsè erèé oko lọpọ̀ yanturu tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n rí tà fún wa.

say no to gmo foods, seed, crop. yoruba warns african

Àwa tí a n gbìn àwọn Igi owó l’oko ẹgàn tí a sì tún n ta èso wọn sí ilẹ̀ òkèèrè nígbàkan rí wá di ẹnití kò leè gbìn tomato àti ata lásán. Ọrọ ìtìjú rèé o! Àwọn àgbààgbà sì nwò wá níran.

Nkan bi ọ̀tàlélẹ́ẹdẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́waa (750) mílíọ̀nù ni iye tomato àti ata tí wọ́n máa n rà jẹ ní ìpínlẹ̀ Èkó lojoojúmọ́. Laárín oṣù kan péré okòó lé méjì àbọ̀ ẹgbẹ̀lẹgbẹ̀ naira ni ìpínlẹ̀ Èkó n ná lorí tomato àti ata. 

Àwọn àgbẹ̀ òkè ọya kò ka bí o ọ̀nà ṣe jìn tó, tí wọ́n sì nkó àwọn erè oko wọn wá fún títà ní Èkó, tí wọ́n á sì padà lọ sílẹ̀ wọn pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye náírà. Síbẹ̀síbẹ̀ gbogbo ìpínlẹ̀ Yorùbá tó kù káwọ́ gbera, wọ́n n’wò laìṣe nkan kan bí ẹnití kò ní olùrànlọ́wọ́.

Ó dámilojú wípé kò sí ìpínlẹ̀ kan ní ilẹ̀ Yorùbá tí kò ní máa pa tó ọgbọ̀n bílíọ̀nù náírà losooṣù tí wọ́n bá lè ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ ọ̀gbìn erè oko tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé wọn kò jìnnà sí ipínlẹ̀ Èkó rárá. N’ise ni a kàn jókòó lásán, a nṣe àwọn nkan tí kò ní ìtumọ̀ kankan.

Ẹ wo iye ẹgbẹgbẹ̀rún sarè ilẹ̀ tí a jókòó lé lorí tí ó lọrá dáadáa tí ó sì ṣeé dáko. N’iṣe ni a kàn jókòó tí a nkigbe wípé “ebi n pa wá o’. Ọ̀rọ̀ rírùn pátápátá gbáà ni.

say no to gmo seeds

Nkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wa màlu ní wọ́n npa ní Èkó ní ojoojúmọ́. Ẹ jẹ́ kí á fi ẹgbẹ̀rún lọnà irinwó náírà ṣe òṣunwọ̀n. Èyí yóò jẹ́ bílíọ̀nù mẹ́rin náírà lojojúmọ́ àti n’kan bí bílíọ̀nù lọnà okòó lélọgọ́run lọ losù kan.

Ẹ tilẹ̀ wá gbọ́ ná, kínní nkan bàbàrà tí ó wà nínú kí a sin màlúú nínú ọgbà àkámọ́ tí a kòlè ṣe ní orílẹ̀ èdè Yorùbá pẹ̀lú àwọn mùdùnmúdùn míràn tí o ṣeéṣe kí ó ti ibẹ̀ jáde? Gàárì di Góòlù.

Gẹ́gẹ́bí ìfọ́síwẹ́wẹ́ ọ̀rọ̀ lati ẹnu Dókítà Solomoni Ekundayo ṣe fihàn, ó ní ìpínlẹ̀ òun ni Èkìtì tí o kéré jùlọ ní gbogbo orílẹ̀ èdè Yorùbá. Saarè ilẹ̀ tí Ekiti ní jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọnà ọ̀ọ́dúnrún (300,000) nígbàtí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìlọ́po márun jù ti Èkìtì lọ.

Bẹ́ẹ̀ sì ni a ò nílò ju ìdá mẹ́ta péré nínú ọgọ́ọ̀rún láti ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn tó péye. A jókòó gelete, a káwọ́ gbera, a n wò bí olúndù. Ọ̀rọ̀ ìtìjú rèé o. Nígbàtí ó n bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, Dokita Solomoni wòye wípé láìka ìpínlẹ̀ Èkó, gbogbo ìpínlẹ̀ Yorùbá tó kù ju ẹgbẹ̀rún lọnà àádọ́rin lé mẹ́rin ibùsọ̀ ní àyípo.

Ẹ jẹ́ ká ṣe ìrántí wípé orílẹ̀ èdè Israel kò ju okòó léméjì ibùsọ̀ ní àyípo lọ. Tí a bá ròó papọ̀, gbogbo ìpínlẹ̀ Yorùbá ní, ní àpapọ̀, iye ilẹ̀ tí ó ṣeé dá’ko tó jẹ́ nkan bí ẹgbẹ̀rún lọnà ẹgbẹ̀rin lọnà mẹ́ta saarè ilẹ̀. Kí ó le yéwa dáadáa, saarè ilẹ̀ kan tó ilẹ̀ ìkọ́lé mẹ́ẹdogún (15 plots) tàbí éékà (acre) méjì àbọ̀.

Sarè ilẹ̀ kan á fún wa ní àádọ́ta àpò ìrẹsì tàbí ọgọ́run àpò gààrí. A wá lè fi òye mọ iye agbọ̀n tomato àti ata tí a máa rí nínú saarè ilẹ̀ kan (1 hectare).

Bẹ́ẹ̀ sì ni a ní tó ẹgbẹ̀rún lọnà ẹgbẹ̀rún méta saarè ilẹ̀. Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Dokita Solomoni ṣàkíyèsí wípé gbogbo ìpínlẹ̀ tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Yorùbá bayìí ní nkan bí ọ̀tàdínlaádóje ìjọba ìbílẹ̀. Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ó ní èyítí ó pọ̀jù nínú àwọn ìjọba ìbílẹ̀ wọ̀nyí.

Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yí ni ọ̀wọ́ kẹ́ta ìṣèjọba ní orílẹ̀-èdè Yorùbá. Tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ àgbẹ̀ la’rugẹ tí wọ́n sì ná nkan bí ìdá mẹẹdogún owó nínú owó tí ó nwọlé sí wọn lọwọ́ loṣooṣù sórí iṣẹ́ àgbẹ̀, wọ́n á pa tó biliọnu méjìlélaádọrin (72 billiọn) lọ́dọọdún.

Tí ó bá ríbẹ́ẹ̀, njẹ́ oúnjẹ á di ọ̀wọ́n gógó bí ó ti rí lóníì yìí? Ṣé kìí ṣe pé iṣẹ́ ṣíṣe á pọ̀ yanturu fún àwọn ọ̀dọ́ wa tí àwọn ilé iṣẹ́ nlánlá àti kékèké á gbéra sọ.

Dípò èyi, n’isẹ ni a kàn jókòó tẹtẹrẹ tí a sì nṣe àwáwí asán bí òkú àgàn. Ṣé a nretí kí ẹnìkan wá bá wa dáko kí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ́n ata àti tomato káàkiri ilẹ̀ wa ni? Dókítà Solomon Ẹkúndayọ̀.

Nígbàtí wọ́n fí ọ̀rọ̀ wáa lénu wò nípa ibití Orílẹ̀ èdè Yorùbá tò sí nínú ètò ìṣúná àti orò ajé ilẹ̀ Naijiria ti wón wà tẹ́lẹ̀. Ilẹ̀ Yorùbá wà ní ìsàlẹ̀ àtẹ̀gùn pátápátá. Wọn ò ṣe nkankan rárá yàtọ̀ sí títà n’kan ìní wọn — ìpínlẹ̀ kwara ni ó tún farajọ awọn ìpínlẹ̀ Yorùbá tí o kù.

Àwọn tí ó jẹ́ wípé wọ́n ní irúfé isarasihuwa bíi tí àwọn ìpínlẹ̀ tí o kù. Ìpínlè tí o lọrá dáadáa pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó tẹ́ pẹrẹsẹ tí ó sì ní ojú ọjọ́ tí ó fanimọ́ra; ilẹ̀ tí ó jókòó ní ìhà agbègbè odò ọya. Ìpínlẹ̀ kwara nìkanṣoṣo le pèsè ìdá mẹ́ẹdọgbọ̀n nínú ọgọ́run ìwọ̀n oúnjẹ ìresì tí gbogbo ìlú Ajiriya nilo.

Ìjọba ìbílẹ̀ kanṣoṣo ní ìpínlẹ̀ kwara tóbi ju gbogbo ìpínlẹ̀ Èkìtì àti ìpínlẹ̀ Èkó lápapọ̀. Kíni wọ́n fi gbogbo ilẹ̀ yí ṣe o? Ìjọba ìbílẹ̀ tí mo ní lọkàn yí ní èyítí ó ju ẹgbààárun lọnà ẹ̀ẹ́dẹgbẹ̀rin sarè ilẹ̀ lọ.

Ọmowé Solomoni sọ síwájú síi wípé òún ti fí ìgbàkan rí gbé lọdọ̀ mọ̀lẹ́bí òun kan ní bárékè Sobi tí ó wà ní ìlú Ilorin. Ìgbà náà ni òun mọ bí wọ́n ṣe nṣe ọ̀gbìn ìrẹsì. Wọ́n máa nrí tó àpò ìrẹsì nlánlá márùn láti inú oko kékeré tí wọ́n máa ndá nígbànáà. Gẹ́gẹ́bí ó ṣe sọ, wọn ò ju méjì péré lọ.

Àwọn nkán tí wọ́n máa nrà l’ọjà nígbànáà kò ju iyọ̀, epo pupa àti àwọn kékèké  míràn. Àwọn Gomina wá ní isẹ́ púpọ̀ láti ṣe níwòn ìgbà tí ó jẹ́ pé òfin ìjọba ológun tí ọdún 1978 lórí bí a ṣe lè lo ilẹ wà ni ikawo wón. [Èyíinì, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ṣe rí kí a tó kúrò nínú Nàìjíríà.

Ṣùgbọn nísiìyí, a ti kúrò; ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá sì ní àwọn ohun rere fún wa nípa ti ọ̀pọ̀yanturu oúnjẹ]