Ìsẹ̀lẹ̀ aburú nlá kan ṣẹlẹ̀, ní orílẹ̀-èdè Namibia ní ilẹ̀ aláwọ̀dúdú wa níbí,ní nǹkan bíi ọgọ́fà ọdún sẹ́yìn.
Àwọn òyìnbó Germani ni amúnisìn tí ó mú àwọn ènìyàn Namibia sábẹ́ nígbà tí wọn wá ṣe iṣẹ́ ibi wọn ní Áfríkà.
NÍ ẹgbẹ̀rún ọdún, ó dín mẹ́rin-dínlọ́gọ́rún, àwọn ìran Herero ní ilú Namibia fárígá fún àwọn Germani amúnisìn yí, nítorí wọ́n ti jí ilẹ̀ wọn àti ẹran-ọ̀sìn wọn. Ní ọdún tí ó tẹ̀le, àwọn ìran Nama náà tún fárígá.
Kíni àwọn amúnisìn Germani yí wá ṣe? Nṣe ni olórí-ogun Germani kan wá ṣe òfin o, pé kí wọ́n pa àwọn ẹ̀yà méjèèjì run, kúrò lórí ilẹ̀ ayé! Olè ṣe ìdájọ́ fún oníǹkan.
Wọ́n lé àwọn ẹ̀yà méjèèjì yí kúrò ní ìlú; wọ́n lé wọn sínú aṣálẹ̀. Níbẹ̀ ni ebi ti pa wọ́n nípa ìyà, tí wọ́n tún nkú.
Àwọn tí wọ́n gbìyànjú láti padà sínú ìlú ni wọ́n tún pa. Èyí tí wọn ò pa, wọ́n fi wọ́n sí àgọ́-aláìnílé. Wọ́n fi tipá bá àwọn obìnrin wọn lòpọ̀. Wọ́n fi ìyà jẹ wọ́n gidi.
Nṣe ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wá ku kìkìdá egungun. Ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn Herero ló kú, ti ìdajì àwọn Nama sì kú, láarín ọdún mẹ́rin tí wàhálà yí ti bẹ̀rẹ̀.
Ìròyìn tí ó fi èyí hàn wá, sọ pé ó tó bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́run àwọn ènìyàn wọ̀nyí tó kú.
Nṣe ni àwọn ẹni-ibi Germani wọ̀nyí tún fi àwọn òkú wọ̀nyí ṣe ìwádi-ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ amúnisìn wọn! Àwọn kan á dẹ̀ máa sọ pé àwọn wèrè òyínbó wọ̀nyí ni wọ́n wá là wá lójú ní Áfríkà!
Ó mà ṣe ò; Áfríkà kò mọ ìtàn ara rẹ̀! Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, ti sọ pé, ní kété tí a bá ti rẹ́yìn àwọn agbésùnmọ̀mí ajẹgàba nàìjíríà tí ìṣe wọn kò yàtọ̀ sí ti àwọn ẹni ibi wọ̀nyí, a máa tún ìtàn wa kọ, ìtàn Yorùbá gẹ́gẹ́bí òtítọ́ rẹ̀ ti rí gan-an, kìí ṣe ìtàn irọ́ tí wọ́n ti gbé lé wa lọ́wọ́.
Nṣe ni àwọn ọmọ ológun Germani wọ̀nyẹn gé orí àwọn òkú ará Namibia náà, tí wọ́n sì wá fi tipá mú àwọn obìnrin aláwọ̀dúdú tí wọ́n ti mú, pé kí wọ́n se àwọn orí wọ̀nyí, kí wọ́n wá fi ọ̀bẹ ha wọ́n, kí ó ku egungun agbárí nìkan. Wọ́n sì kó àwọn egungun agbárí wọ̀nyí ránṣẹ́ sí ìlú Germani kí wọ́n fi ṣe ìwádi ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àwọn àṣìtáánì òyìnbó wọ̀nyí.
Àwọn agbári ọmọ aláwọ̀dúdú náà wà ní Germani fún ọdún pípẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti dá eegun náà padà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, ṣùgbọ́n ìròyìn náà sọ pé ó ṣeé ṣe kí ọgọọgọ́run àwọn egungun ọmọ ìlú Namibia wọ̀nyí ṣì wà ní Germani.
Títí di òní, Germani kò bẹ̀bẹ̀ fún ìwà ìkà tí wọ́n hù yí, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ṣe “gbà-má-bínú” kankan, wọ́n kàn ṣáà sọ pé àwọn gbà pé aìṣedéédé àwọn ni, bí ìgbà tí a bá sọ pé “ẹ̀hẹn, kí lẹ wá fẹ́ ṣe si.” Ìgbéraga àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí, ó lé kenkà, àmọ́, ọjọ́ àtubọ̀tán ń bọ̀.
Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), kí a má ṣe rò pé òyìnbó amúnisìn ní èrò rere kankan sí wa o! Ojú lalákàn fi nṣọ́rí ni ọ̀rọ̀ wa o!
Ẹ jẹ́ kí á kíyèsára ní ìgbà gbogbo, kí á sì ríi dájú pé a ntẹ̀lé Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè tí gbé fún Ìran wa, Ìran Yorùbá, nípasẹ̀ Màmá wa, kí á máṣe gba ìgbàkugbà, kí á má dẹ̀ ṣe ojú àànú tó leè fa ìpalára fún ara wa; ìbáà ṣe amúnisìn òyìnbó, ìbáà ṣe ajagungbalẹ̀ Fulani, tàbí agbéraga Íbò; ẹnikẹ́ni yóò wù kó jẹ́, a ò gbọdọ̀ fún wọn láàyè láti tún kó ọmọ Yorùbá sí oko ẹrú; gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa nsọ, a ò ní kúrò lóko ẹrú kan, kí á tún wá bọ́ sí òmíràn!
Àwọn ọmọ àlè Yorùbá, àwọn akótilétà, àwọn ọ̀dàlẹ̀, a ò gbọdọ̀ fún wọn láàyè iṣẹ́ ibi wọn. Wọn ìbáà pe ara wọn ní Ọ̀mọ̀wé, ìwé àti ìwà amúnisìn tí àwọn òyìnbó wọ̀nyíi ti kó síwọn lọ́pọlọ ni wọ́n nru apá sókè sí; a ò gbọdọ̀ gbà fún wọn.