Nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, máa nbá wa sọ, gbólóhùn kan sábà máa nwáyé: èyíinì ni “Ògo Ọlọ́run.” Wọ́n sábà máa nsọ fún wa pé, “Ní dédé àsìkò yí, ní dédé ìgbà yí, Ọlọ́run fẹ́ kí a pàdà sí Orísun wa, kí á kúrò ní oko ẹrú, kí á lè ṣe àkóso ohun tí Ọlọ́run fún wa, kí ògo wa kí ó le búyọ, kí á lè máa yin Ọlọ́run lógo, kí Ògo rẹ̀ kí ó le búyọ ní ìgbèsí ayé wa.” Irúfẹ́ ọ̀rọ̀ báyi ni Màmá máa nbá wa sọ ní ìgbà gbogbo. Paríparì ọ̀rọ̀ wọn nígbà gbogbo ni pé kí Ògo ọmọ Yorùbá ó le búyọ.

Kíni a npè ní ògo? Ògo jẹ́ oun tí a lè pè ní àyànmọ́ ẹwà àti gbígbé-nkan-rere ṣe ni ayé wa, gẹ́gẹ́bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, èyí tí Èdùmàrè ti kọ mọ́ wa pé kí á wá ṣe láyé, ṣùgbọ́n tí ìbàjẹ́ àti ìkà ọmọ ènìyàn, tàbí àìbìkítà àwa fúnra wa, lè ṣe ìdínà fún, kí ògo yí máṣe farahàn.

Gbogbo ohun tí Màmá máa nbá wa sọ, dá lórí kí a lè rí ògo wa lò, pàápàá àwọn ọdọ́ wa, àti gbogbo wa bákannáà.

Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, wọ́n ti máa nsọ fún wa pé, nípa ètò ìwòsàn, àwọn àìlera tí àgbàyé kò tilẹ̀  tíì mọ ọ̀nà àbáyọ rẹ̀, tí ó jẹ́ pé lórí ilẹ̀ Yorùbá, nípasẹ̀ ọmọ Yorùbá, a máa ṣe ohun tí ó jẹ́ pé àbáyọ dẹ̀ máa wà!

Bákannáà ni Màmá ti fẹnu ba àwọn nkankan nínú Àlàkalẹ̀ tí Èdùmàrè gbé kalẹ̀ fún ìran ọmọ Yorùbá – gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, ní Ètò Ẹ̀kọ́ – tí wọ́n dẹ̀ ti sọ fún wa pé àrà ọ̀tọ̀ ni ní àgbáyé yí!

Wọ́n tilẹ̀ ti sọ fún wa pé, kí àwọn ọ̀dọ́ wa gbàdúrà pé “mo rí ògo mi lò, fún ògo Ọlọ́run.” Ẹlẹ́da wa ló yan ògo náà mọ́ ẹnikọ̀ọ̀kan wa, pé kí á le jẹ́ kí ó búyọ; bẹ́ẹ̀ náà ni, gẹ́gẹ́ bí Ìran Yorùbá, gbogbo wa lápapọ̀ tún ní Ògo tí Èdùmàrè yàn mọ́ Ìran Yorùbá, tí ó dẹ̀ máa búyọ, fún Ìgbélékè Orílẹ̀-Èdè wa, àti kí gbogbo àgbáyé le rí Ògo Ọlọ́run fúnra Rẹ̀, lára Ìran Yorùbá.

A ti kúrò nínú oko Ẹrú báyi, àkókò kí ògo wa gẹ́gẹ́bí ẹnikọ̀kan, àti lápapọ̀ gẹ́gẹ́bí Ìràn Yorùbá, kí ó bú yọ, títí ayé, ni a wà yí!

Benefit for Indigenous People of Yoruba IYP in the Democratic Republic of the Yoruab
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ká Ìròyìn Síwájú sí: