ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI.
OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.
ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ.
ÀṢẸ Èdùmàrè
Inúnibíni kò kan tí àìmọ̀ ìwà hù. Èyí ló d’ífá fún bí àwọn ẹni-ibi òyìnbó-amúnisìn ṣe ńfi ojojúmọ́ wá ọ̀nà láti fí Áfríkà sí abẹ́ ìsìnrú wọn láì sí ẹ̀ṣẹ̀ kankan tí Áfríkà ṣẹ̀ wọ́n. Òyìnbó ṣáà ń bínú wa.
Àbí kí ló kan òyìnbó pẹ̀lù owó-orí àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira ní ilẹ̀ adúláwọ̀? Tani kò mọ̀ pé àlùwàlá ológbò, ọgbọ́n láti k’ẹ́ran jẹ ni.
Ọkùnrin aláwọ̀-funfun kan ló gbé aṣírí ọ̀nà àrékérekè tí àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn aláwọ̀-funfun tún fẹ́ gbà láti máa kó owó ní Áfríkà lọ sí ìlú tiwọn síta. Wọ́n pé ètò náà ní Agbowó-Orí Tí kò ní Ibodè.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti tan àwọn olórí-ìlú ní Áfríkà láti yá owó lọ́wọ́ Ilé ìfowópamọ́ Àgbáyé, àti Àjọ Ìṣètò-Owó nì Agbáyé, tí gbèsè ti wá wọ ìṣúná wọn l’ọ́rùn tán, àwọn òyìnbó amúnisìn yí wá dìde pé kí àwọn olórí-ìjọba ní Áfríkà wá kọ́ ọ̀nà tí wọ́n fi ń gba owó-orí lọ́wọ́ ará ìlú, kí àwọn ìjọba wọ̀nyí lè gba owó-orí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tiwọn ní Áfríkà láti lè san gbèsè tí wọ́n jẹ aláwọ̀-funfun. Ọ̀nà láti da òyìnbó kún ilẹ̀ Áfríkà! Oko-ẹrú tààràtà l’ẹlẹ́ẹ̀ kejì!
Ọkùnrin náà sọ̀rọ̀ síwájú nípa bí èyí ṣe jẹ́ ọgbọ́n àyínìke láti kó ọrọ̀ ènìyàn dúdú lọ sí ìlú aláwọ̀-funfun, kí Áfríkà le tẹ̀síwájú nínú oko-ẹ́rú ìgbàlódé lábẹ̀ òyìnbó.
Ní ìparí ohun gbogbo, ìmọ̀ràn ọkùnrin náà ní kí gbogbo olórí-ìjọba ní Áfríkà má ṣe bá àwọn àjọ ayánilówó àgbáyé méjèjì náà da òwò pọ̀ mọ́, kí wọ́n má báà tẹ̀síwájú nínú oko-ẹrú lábẹ́ àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí.
Ni Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), àwa dúpẹ́ fún òmìnira wa kúrò lábẹ́ ẹrúsìn gbèsè, nípa ominira wa kúrò nínú ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà, tí Ọlọ́run lo màmá wa Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla fún, ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlélógún, àti ìbúra-wọlé fún bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, gẹ́gẹ́bí olórí ìjọba Adelé wa, ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa.
Pẹ̀lú ìdánilójú àlàkalẹ ètò-ìṣèjobà tí Olódùmarè ti gbé lé Màmá wa lọ́wọ́, àwa kò ní lọ sí oko gbèsè.
Màmá wa alálùbáríkà, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla, ti jẹ́ k’a mọ̀ pé, a ó pèsè ohun tí a bá nílò, a ó sì lo ohun tí a bá pèsè. Àwọn agbaṣẹ́ṣe, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti onímọ̀-ẹ̀rọ tí wọ́n jẹ́ Indigenous Yorùbá People (I.Y.P) ni iṣẹ́ máa wà fún lọ́pọ̀lọpọ̀. Orílẹ̀-Èdè D.R.Y kò ní lọ sí oko-ẹrú gbèsè láíláí.