Òdodo ní gbóríléèdè lékè o, ká fì’mọ̀ ṣ’ọ̀kan, ká jọ gbógo Yorùbá ga, olórin wa kan ló kọọ́ lórin.

Ẹyin ọ̀dọ́ wa ní Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yorùbá, ẹyin ni ogo wa lónìí, lọ́lá àti títí láé, gẹ́gẹ́ bí ìyá wa, ìyá ìrọ̀rùn, ìyá adúláwò, ìyá ìran, ìyá ìmọ́lẹ̀, ìyá Yorùbá, ìyá Ọ̀DỌ́, ìyá talk-and-do, olórúkọ rẹpẹtẹ, see máa ń sọ ọ́, a kí yín kú oríre pé ní àsìkò ti yín ní olùgbé’jà wá dé, màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abíọ́lá (MOA), ìyá tó ṣe ètò ìrọ̀rùn fún yín, ẹyin ọ̀dọ́ Indigenous Yorùbá People (I.Y.P.), lẹ́ẹ̀kan síi, mo tún kí yín kú oríire, nítorí ìgbà ọ̀tun yín ti dé, ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyá ìrọ̀rùn, abiyamọ tòótọ́, tí wọ́n rí tiyín rò, tí wọ́n sì ṣeé ní àṣeyọrí.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP).… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

Tí kìí bá ṣe ìyá ẹyin ọ̀dọ́, tí wọ́n jẹ́ kí á mọ̀ pé òní ni ọjọ́ ayẹyẹ ẹyin ọ̀dọ́ ni àgbáyé, ta ló rántí yín rí nínú àwọn àgbà ìyà, àwọn ató kú má kú, a mọ ọ̀nà ọ̀run má lọ, tí wọ́n ń pè yín ní asíwájú ọlá ní ojojúmọ́ títí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín fi di àgbà tán, ṣùgbọ́n síbẹ̀, tí wọ́n kò sì fi àyè sílẹ̀ fún yín.

Ẹyin ọ̀dọ́ IYP, àsìkò yín ní ìyá wá tí jà, tí wọ́n sì ti gba ẹ̀tọ́ yín fún yín, ìyá wa, MOA, talk-and-do, wí bẹ́ẹ̀, jẹ́ bẹ́ẹ̀, lóòótọ́, ti Oluwa ni, ṣùgbọ́n, ìránṣẹ́ Olódùmarè, tí ó ṣèlérí fún yín ní ọdún méjì sẹ́yìn, tí mú ìlérí ọjọ́ pípẹ́ náà ṣẹ fún yín báyìí, àlá yín tí wá sí ìmúṣẹ, ẹwo Olórí Adélé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ọ̀dọ́ ni, ìyá wa wípé, kí àwa àgbà lọ ṣẹ́mpẹ́ o, kí ẹ lè rí ògo yín lò.

Báwo ni ẹyin ọ̀dọ́. I.Y.P. kò ṣe ní d’ójú tí ìyá ìmọ́lẹ̀ báyìí?, nítorí, Yorùbá bọ̀, wọ́n wí pé, tí a bá torí igi gb’odì, a su’ná fún ni yá.

Gbogbo àwọn àgbà oníranù ni ilẹ̀ Yorùbá ti gbógun ti ìyá wa nítorí tiyín, kí àlá yín le wá sí ìmúṣẹ, a bẹ̀ yín, kí ẹ má dójúti màmá wa o, torí náà, ẹ dìde ẹyin ọ̀dọ́, ẹ pe àwọn ẹlẹgbẹ́ yín tí kò tíì gbọ́, kí ẹ bẹ̀rẹ̀ gbé iṣẹ́ Orílẹ̀-Èdè wa D.R.Y lárugẹ. 

À ṢE YÍ Ṣ’ÀMỌ́DÚN OOO.