Nígbà tí wọ́n mú ọ̀dọ́ yí wá sí iwájú adájọ́, tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn ìdàlúrú kàn-án, nṣe ni ó la ẹnu láti sọ̀rọ̀ ọkàn rẹ̀, ó sì fi gbogbo ara sọ̀rọ̀ báyi, ó ní:

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

“Mo fẹ́ rí àyípadà ní ìlú yí; mo ṣetán láti kú fún òmìnira ará ìlú; mo ṣe tán láti kú fún ìdájọ́-òdodo. À ò lè máa gbé ìgbé-ayé ẹrú ní ìlú wa, ní orí-ilẹ̀ àwọn baba wa! Àwọn baba wa fi ayé àti ẹ̀mí wọn lé’lẹ̀, fún orílẹ̀-èdè yí; láti fún wa ní ìtúsílẹ̀ kúrò nínú àjàgà amúnisìn àwọn òyìnbó.

Ìjọba amúnisìn ti òyìnbò kò fi ìgba kankan kúrò nílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yí. Ilé-ẹjọ́ tí ẹ gbé mi wá yí, pàápàá, òfin òyìnbó amúnisìn ni ẹ nlò níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ wípé wọn ò lè dá ìdájọ́ òdodo fún mí, ní àwọn ilé-ẹjọ́ wọ̀nyí.

“Mo ní láti fi ẹnu mi sọ ọ̀rọ̀ ìgbèjà fún ara mi. Àkókò náà máa ndé ní ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ wípé, o ní láti fi ẹnu rẹ ṣe àlàyé ara rẹ – ẹlòmíràn kò lè bá ọ ṣe eléyi.

 

Ọ̀dọ́ Kenya Sọ̀rọ̀ Tó Lágbára Jáde, Nígbàtí Wọ́n Mu Wá Sílé Ẹjọ́ Wípé Ó Ndàlúrú, Látàrí Ìfẹ̀hónú Hàn Ní Ìlú Kenya!

 

“Ó ti sú mi pátápátá, láti máa gbé bí ẹrú nínú orílẹ̀-èdè tí mo pè ní tèmi! Mo ti sọ eléyi ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ṣe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ inkan, láti lè jẹ́ kí àyípadà kí ó wá sí orílẹ̀-èdè yí. Nìtorí à kò lè tẹ̀síwájú pẹ̀lú irúfẹ́ ìṣèjọba eléyi, tí ó jẹ́ wípé àwọn tí ara wọn kò dá ni ó nṣe ìjọba lé wa lórí – àwọ́n tí ó jẹ́ alárùn ọpọlọ!

Àwọn òpùrọ́ àti olè, tí wọ́n sì nṣekú pa wá! Irúfẹ́ àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí ni wọ́n nṣe ìjọba ní Kenya, àti ní Africa. Irúfẹ́ ipò tí a wà nìyẹn; ìdí dẹ̀ ni eyí tí ó fi jẹ́ wípé àwọn ènìyàn nkú, tí kò sì sí ẹni tí ó ṣe bíi wípé ó kan òun! Àwọn òtòṣì njìyà, kò kúkú kan ẹnikẹ́ni!

“Kí wá ni iṣẹ́ ìjọba gan-gan-gan o? Mo fẹ́ mọ̀, l’oní yí, kíni iṣẹ́ ìjọba? Ṣé láti dáàbò bo ará ìlú ni? tàbí láti máa pa àwọn ará ìlú; tàbí kí wọ́n máa fi ìyà jẹ ará ìlú?

“Èmi rò wípé a ti kùnà ojúṣe wa sí àwọn ènìyàn wa. Ìjọba ti kùnà ojúṣe rẹ̀ sí àwọn ará ilú. Gbogbo wa ni a ti kùnà yí. Àwa gan-an ti kùnà ojúṣe wa sí ara wa! Ẹ̀rí-ọkàn mi kò lè gbà mí láyè láti dákẹ́.

“Èmi ò mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ yí le dé ibikíbi tí ó lè dé; ṣùgbọ́n tèmi ni wípé, a níláti jóko sọ ọ̀rọ̀ yí: a níláti ṣe àròyé yí fún àwa’rawa. A ò lè máa tẹ̀síwájú láti máa gbé nínú ìbẹ̀rù! Mo rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀rù bíbà ní orílẹ̀-èdè yí, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀rù bíbà nínú àwọn ilé-ìgbẹ́jọ́. L’aná òde yí ni a rí adájọ́ tí ọlọ́pa yin ìbọn lù!”

Nígbàtí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ náà nlàkàkà láti ṣáà dá ọ̀rọ̀ tí o nsọ mọ́ ọ lẹ́nu, kò gbà fún wọn; ó ní, “Mo fẹ́ sọ̀rọ̀, ẹ̀yin ará, mo fẹ́  sọ̀rọ̀, nítorí nígbàtí ẹ bá ngbìyànjú láti sọ fún mi wípé kí ndákẹ́, ọkàn mi ngbóná; ó ngbóná tìtorí bí orílẹ̀-èdè yí ṣe rí, nítorí, fún ọgọ́ta ọdún báyi, ni a ti ngbé ìgbé-ayé bíi wípé a kìí ṣe ọmọ ènìyàn; bíi wípé ààbọ̀ ènìyàn ṣá la jẹ́!

Eléyi kò lè máa lọ bẹ́ẹ̀, rárárárá! Àwọn péréte ni wọ́n njẹgàba lé wa lórí, tí wọ́n sì nhù’wà kòkànmí, ohun ìbáàwù kí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ará ìlú tókù!

Òpùrọ́ àti olè ni àwọn olóṣèlú, wọ́n sì ti jà wá lólè òmìnira wa, wọ́n ti jà wá lólè ìrònú wa; wọ́n ti jà wá lólè àwọn ilẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti jà wá lólè ọjọ́-iwájú wa.

say no to gmo foods, seed, crop. yoruba warns african

Àwọn òsèlú wọ̀nyí mọ̀ púpọ̀ nípa irọ́ pípa àti ní yíyẹ àdéhùn. Irọ́, àìmú-àdéhùn-ṣẹ, ìrètí-tí-kò-lọ́jọ́, àti dída ẹni sí kòròfo, ni ohun tí wọ́n ti dà lé wa láyà, fún ọgọ́ta ọdún wọ̀nyí.”

Ó tún wá sọ síwájú, wípé, “Mi ò mọ ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ o; mi ò mọ̀ bóyá ẹ máa jù mí sẹ́wọ̀n  ni; ṣùgbọ́n mo ṣe tán láti lọ sẹ́wọ̀n fún ọgọ́run ọdún pàápàá; ṣùgbọ́n èmi kò ní dákẹ́ láti máa sọ òtítọ́, títí di ọjọ́ náà tí mo máa jáde kúrò láyé yi. A ò lè máa tẹ̀síwájú bí eléyi.

Ká Ìròyìn Síwájú sí:

Ẹ̀yin ará nínú ilé-iṣẹ́ ìgbẹ́jọ́ yi, àwa ará ìlú níláti kọ ìyà yí; kíkọ-ìyà ni ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo fún orílẹ̀-èdè yí, àti fún gbogbo Áfríkà pẹ̀lú. Àwọn ènìyàn nkú, níbi gbogbo – ní Congo pàápàá, ìyà njẹ àwọn àrá ìlú, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ kí á lẹ́nu ọ̀rọ̀. A ti kùnà gẹ́gẹ́bí ọmọ ènìyàn; a ti kùnà, pátápátá.

Mi ò mọ ìdí tí a fi npe ara wa ní krístẹ́nì, àbí tí a fi npe ara wa ní ọ̀làjú àti ẹni tí ó kàwé?! Nítorí a ò kì-ín ṣe ọ̀làjú rárárárá! Òpè pátápátá gbáà ni wá! Òpè tí a jẹ́ yi sì npa wá lọ! Eléyi ti búrú jù! A ò lè máa báa lọ bẹ́ẹ̀. Ìjọba yí gbọ́dọ̀ jáde..” Wọn kò jẹ́ kí ó párí ọ̀rọ̀ náà nígbàtí wọ́n múu kúrò níbi tí ó ti nfèsì sí ìbéèrè tí wọ́n bèrè lọ́wọ́ rẹ, wípé, “o jẹ̀bi, tàbí óò jẹ̀bi?”

Gẹ́gẹ́bí a ti ṣe gbọ́ọ nínú fídíò tí ó tẹ̀lé ìròhìn náà wá, ó fi han gbangba wípé, àwọn ọ̀dọ́ aláwọ̀dúdú ṣe tán láti fi ọwọ́ ara wọn tún ìgbé-ayé Áfríkà ṣe. A ṣe àkíyèsí wípé wọ́n ti fi ẹ̀wọ̀n-ọ̀wọ́ (hand-cuff) de ọ̀dọ́ yí kí ó tó dé ilé ẹjọ́!