Ìlú Nigeria jẹ́ ìlú ọ̀daràn l’ọpọ̀l’ọpọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó jẹ́ ìlú tí ó dá’jú. Tí kìí bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, kíni ó fa kí Nigeria ṣì wà l’orí ilẹ̀ orílẹ̀-èdè Yorùbá di òní yí?

Nigeria nṣe orí kunkun l’orí nkan tí kìí ṣe tiwọn. Nigeria ndókùkùlajà mọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá àti mọ́ orílẹ̀-èdè Yorùbá. Ohun tí Nigeria gb’ojú lé ni kò yé wa o!

Nigeria ndókùkùlajà mọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá

Ṣùgbọ́n, a mọ̀ wípé kìí ṣe Nigeria l’ó dá Yorùbá; Olódùmarè ni ó dá Yorùbá, àti ilẹ̀ Yorùbá fún ọmọ Yorùbá; l’aìpẹ́, l’aìjìnnà, ọmọ Yorùbá máa bọ́ pátápátá.

Kíni Nigeria ti’lẹ̀ fi ara wọn pè gan? Kínídé tí ó fi jẹ́ wípé Nigeria ní irúfẹ́ ìgbéraga báyi? Kò sí ohun tí ó fàá ju wípé ìpilẹ̀ṣẹ̀ Nigeria kò dára.

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ oko ẹrú gbáà ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ Nigeria Ṣé a ti mọ̀ wípé oko ẹrú ni àwọn tí ó kó Nigeria jọ, tí wọ́n fi ṣe l’ati ìgbà tí wọ́n ti ko jọ.

Àwọn ènìyàn sì ndàgbà nínú ọko ẹrú yi láì mọ̀ wípé oko ẹrú ni àwọn wà; nṣe ni wọ́n ti’lẹ̀ rò wípé nṣe ni àwọn òyìnbó ṣe wá l’oore, tí wọ́n rò wípé, ọpẹ́l’ọpẹ́ òyìnbó, a kì bá ti la’jú! Nítorí èyí l’ó ṣe jẹ́ wípé kàkà kí àwọn ènìyàn mọ̀ wípé oko ẹrú ni àwọn wà, nṣe ni wọ́n tún mpọ́n àwọn òyìnbó lé àfi bíi pé olóore wa ni òyìnbó jẹ́.

Ìdí ni’yí tí ó fi jẹ́ wípé ènìyàn bíi Tinubú á tún máa ṣe kúbẹ́ kúbẹ́ gẹ́gẹ́bí ẹrú òyìnbó.

Ọpẹ́l’ọpẹ́ Màmá Modúpẹ́ Onítirí aya Abíọ́lá tí ó jẹ́ wípé Olódùmarè yàn l’ati Ọ̀run wá wípé kí wọ́n tú ìran Yorùbá kúrò l’oko ẹrú.

Ṣùgbọ́n kíni ó wá dé báyi tí ó fi jẹ́ wípé ẹni tí ó pe’ra rẹ̀ ní ìran Yorùbá ni ó tún wá takú wípé Nigeria máa dúró s’orí ilẹ̀ Yorùbá, wípé kí ìjọba Yorùbá má ṣe r’ojú r’ayè ṣe àkóso orílẹ̀-èdè Yorùbá bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ?

Ìdí ni wípé ẹrú Òyìnbó ni Tinubú jẹ́; ẹrú Fúlàní náà l’ó sì jẹ́ pẹ̀lú; ìdí ni èyí tí ó fi wá jẹ́ wípé iṣẹ́ tí àwọn Fúlàní rán-an ni ó njẹ́; ṣùgbọ́n èyí kò bá wàhálà kankan dé fún àwa ìran Yorùbá, l’orí ilẹ̀ Yorùbá; ìdí èyí ni wípé a ti bábá gbé ìjọba wa wọ’lé; nítorí èyí, ó ti wá di ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè wàyí; èyí tí ó tú’mọ̀ sí wípé kí ọmọ Yorùbá ó f’ọkàn ba ‘lẹ̀; orílẹ̀-èdè Yorùbá mbá ‘ṣẹ́ lọ ní ìgboro Àgbáyé; ó ku díẹ̀ báyi tí Nigerià máa gb’oórùn ara wọn; nígbà náà ni ẹ̀sín wọn á tó hàn sí gbogbo àgbáyé.

Yorùbá, Mú’ra Fún Ọjọ́ Ògo Rẹ

Democratic republic of the yoruba

A ti gbé ìjọba wa wọ’lé, pẹ̀lú àtìl’ẹhìn Olódùmarè, bẹ́ẹ̀ náà ni olórí adelé wa ti sọ fún wa wípé kí a máa gb’ára dì fún ọjọ́ ògo náà, tí a máa lọ sí pápá ìṣeré tí ó bá tó’bi jùlọ ní gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ wa; ní’bẹ̀ ni a ti máa jó, tí a sì ti máa yọ̀, wípé, pátápátá, a ti gba ìṣ’àkóso ilẹ̀ wa kúrò l’ọwọ́ àwọn afi’pá-dúró-s’orí-ilẹ̀-ẹni, èyíinì, agbésùnmọ̀mí Nigeria.