Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

 

Ní Orílè-Èdè Yorùbá, A Máa Ran Ara Wa Lọ́wọ́ Láti Gbé Ọrọ̀ Ajé Wa Ga Ni O.

Ẹ̀kọ́ pàtàkì ni fún àwa ọmọ Yorùbá Olómìnira pé a ní láti s’owọ́ pọ̀ láàrín ara àwa tí a jọ jẹ́ aláwọ̀ dúdú, nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, èyí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbé Yorùbá ní gbọn’wọ́ tí ó máa fi ẹsẹ̀ ọrọ̀ ajé wa mú’lẹ̀.

Àwọn ọmọ IYP (Indigenous Yorùbá People) ló máa kọ́kọ́ jẹ ànfàní nínú gbogbo nǹkan pátápátá kí á tó fún ẹ̀yà míràn ní ààyè, kí ó tó kàn àjèjì yálà nínú: gbígbani sí’ṣẹ́ ni, nínú ẹ̀kọ́ tàbí láti ní’lé lórí ni, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí pé, lẹ́yìn Ọlọ́run, Yorùbá ní o.

Bákannáà, gbogbo òpópó’nà, ojú ọ̀nà ọkọ̀ t’órinlẹ̀, ilé-ìwé, àwọn ilé-iṣẹ́, ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú, àwọn olú ilé-iṣẹ́ àwọn ọmọ ológun, ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ gbọ́, kò ní sí ohun tó ń jẹ́ Murtala Mohammed Airport mọ́, Tafawa Balewa Square, Ozumba Nbadiwe Street, Azikiwe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, gbogbo rẹ̀ pátá pátá ni a máa fún ní orúkọ Yorùbá o.

Kí ló dé o, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo owó tí a bá ń pa wọlé, à fi kí a máa náa tán sí òkè òkun? Irú bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí ọrọ̀ ajé irú orílẹ̀-èdè náà fi ẹsẹ̀ mú’lẹ̀. Ohun tí a bá ń pèsè ní orílẹ̀-èdè wa náà ni a máa lò.

Ẹ jẹ́ kí a kíyèsí pé: Asia kò ní jẹ́ kí dollars tí wọ́n bá pa, jáde kúrò ní inú ìlú wọn láì jẹ́ pé ó lo ọjọ́ méjì dín-ló gbọn. Àwọn Jewish, tiwọn máa lo ọjọ́ mọ́kàn-dín-lógún. Àwọn funfun, tiwọn máa lo ọjọ́ mẹ́tà-dín-lógún. Ṣùgbọ́n àwa orílè-èdè aláwọ̀ dúdú, tiwa máa lo wákàtí mẹ́fà péré.

say no to gmo foods, seed, crop. yoruba warns african

Ìpín àádọ́rùn-ún (90%) ọrọ̀ ajé tó ń wọ’lé ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ni à ń ná sí òkè òkun. Ohun tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun ti kó sí wa lórí nìyẹn pé, ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti wọn nìkan ni ó dára ju tiwa lọ. Ìdí tí wọ́n fì ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni wípé kí ọrọ̀ ajé dúdú kankan má baa gbé’rí.

Ṣùgbọ́n, ní ti àwa IYP (Indigenous Yorùbá People) ní orílẹ̀-èdè D.R.Y (Democratic Republic of the Yorùbá), a ní àgbékalè fún ọrọ̀ ajé tiwa. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yókù ló máa wá fi wá ṣe àwòkọ́se ohun rere.