Ó ti wá “njọra” báyi o! – a ti nrí bí oríṣiríṣi ìwà-aburú tí àwọn tí ó pera wọn ní “Alágbáyé” (globalists) ngbé síta, bí ó ṣe so mọ́ ara wọn papọ̀!

Wọ́n fẹ́ kí gbogbo ayé tẹríba fún òjé (irọ́) wọn nípa àrùn mpox tí ó jẹ́ pé àwọn ló ko síta; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fẹ́ kí ọkùnrin àti ọkùnrin ó máa ní ìbálòpọ̀! Àṣé wọ́n tilẹ̀ ti ṣètò rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn nígbàtí ọ̀rọ̀ mpox yí kọ́kọ́ wáyé!

Nígbànáà lọ́hun, ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fi hàn gẹ́gẹ́bí àwọn àdàmọ̀dì-ọkùnrin tí wọ́n nbá ọkùnrin ẹgbẹ́ wọn lòpọ̀ ṣe jáde síta láti ṣe ìpolongo pé kí àwọn èèyàn lọ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára; wọ́n wá nsọ pé ọpẹ́lọpẹ́ àwọn oníbalòpọ̀ ọkùnrinsọ́kùnrin yí, tí ó jẹ́ kí àwọn èèyàn ó mọ̀ nípa gbígba abẹ́rẹ́-àjẹsára nípa mpox ọ̀ún nígbànáà! Kíni èyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé kí àwọn ènìyàn máṣe fi ojú burúkú wo àwọn ọkùnrin tó nbá ọkùnrin bí ti wọn lò pọ̀!

Inkan tí wọ́n fẹ́ tì sí ìgbésí ayé àwọn ọmọ-ènìyàn nìyẹn o! Kí wọ́n gba ìbálòpọ̀ ọkùnrinsọ́kùnrin, kí wọ́n dẹ̀ lọ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára mpox. Háà! Ayé àwọn àṣìtáánì ènìyàn wọ̀nyí ti bàjẹ́! Àpọ́nlé ti ẹ̀ ni pípè wọ́n ní ènìyàn! Ẹ̀mí Lúsíféérì ló wa nínú wọn!

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí Ó fún wa ní Ìránṣẹ́ Rẹ̀, ní àsìkò yí, Ìyá wa, Màmá Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ẹni tí Ẹlẹ́da wa nlò láti darí Ìran wa sí ipa-ọ̀nà òdodo, òtítọ́, ìfẹ́ Olódùmarè, àti Ìbọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́da, láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, sí ògo àwa Ìran ọmọ Yorùbá.

Ó ti wá nyéwa báyi, pé ohun ìbọ̀wọ̀-fún Ẹlẹ́dá, tí Èdùmàrè fẹ́ pe ọmọ ènìyàn sí, ó fẹ́ lo Ìran Yorùbá gẹ́gẹ́bí àwòkọ́ṣe! Gẹ́gẹ́bí wọ́n ti sọ fún wa, ní gbogbo àgbáyé, kò sí Ìran náà tó nsin Ọlọ́run, tó nyin Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, bí Ìran Yorùbá!

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!