Hmmm, nǹkan ń kán, mẹ́wàá ń ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá! Àjálù iná tó jó ilé ní Erékùṣù Èkó ní ọdún k’ọ̀la ṣe wá ní kàyéfì. Ṣùgbọ́n àwọn bàbá wa bọ̀, wọ́n wí pé “Bí nǹkan kò ba ṣe ẹ̀sẹ́, ẹ̀sẹ́ kìí déédéé sẹ́.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ṣé Olójú kò ní r’ójú e ni’le, kó sọ pé kó fọ́, àjókòó-dìde lórí àlééfà ọmọ Yorùbá, èyí tí ìjọba agbésùnmọ̀mí àwọn Gómìnà-Nigeria aláìmọra tó sì ń bẹ láwọn Olú-ilé-isẹ́ wa káàkiri Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ló ṣe okùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ ilé jíjó náà.

Mẹ́wàá Nṣẹlẹ̀ Nílẹ̀ Yorùba!

 

Ó ti wá dójú ẹ̀ báyìí fún wa láti tẹ̀síwájú ni gbogbo ọ̀nà tá o fi ríi pé wọn fi àga wa sílẹ̀. A ti gbé ìjọba wa wọ’lé.

Ká Ìròyìn: Orúkọ Àmútọ̀runwá Nílẹ̀ Yorùbá

Màmá wa àti Olórí Ìjọba Adelé wa, ti ṣisẹ́ takuntakun, wọ́n ti ṣe àwọn ètò amáyédẹrùn fún gbogbo Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ṣùgbọ́n àwọn Ọ̀jẹ̀lú àti ọ̀tá ìlú tí ń sè’jọba agbésùnmọ̀mí ìlú Nàìjíríà kò jẹ́ ká r’áyè ṣe ojúṣe wa.

Ká Ìròyìn: Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Nka Yorùbá Mọ́ Naìjíría! Hábà!

Ọmọ Akin ni wá, a kò gbọ́dọ̀ ṣ’ojo, iṣẹ́ ti di ṣíṣe fún gbogbo wa. 

A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa lati ríi pé àwọn Gómìnà-Nigeria tí wọ́n jẹ́ gúnnugún awonkoko morí ẹyin ẹlẹ́yin kúrò lórí àlééfà wa.

Kí gbogbo wa lọ́mọdé àti lágbàlagbà ká jígìrì ká túbọ̀ ṣe gudugudu méje òun yààyà mẹ́fà lórí bá ó ṣe lé àwọn agbésùnmọ̀mí wọ̀nyí kúrò l’orí ilẹ̀ wa.

Ká Ìròyìn: Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá

Iṣẹ́ gbogbo wa ni, ojúṣe gbogbo wa ni, iṣẹ́ ìgbọ̀nsẹ̀ ni, kò ṣe é fi rán ẹlòmíràn.