A ò mọ iye tabí ẹni tí ó lè jẹ́ Yorùbá nínú wọn o, ṣùgbọ́n ìròhìn tí a gbọ́ nínú fídíò kan fihàn pé àwọn ọkùnrin mẹ́ta-lé-lọ́gọ́run ni orílẹ̀-èdè Turkey ti dá padà o, ṣùgbọ́n àì mọ bóyá ọmọ Yorùbá wà lára wọn kò jẹ́ kí á mọ kíni a lè sọ.

Tí a bá rí ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá lára wọn, ẹ jọ̀wọ́ ẹni tí ó bá mọ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀, kí ó sọ fún wọn o, pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), kò sí lára Nàìjíríà mọ́ o, àti kí wọ́n má ṣe lọ ní àdéhùn kankan pẹ̀lú Nàìjíríà ní orí ilẹ̀ Yorùbá o!

Ọ̀rọ̀  tún rèé, fún gbgbo ọmọ Yorùbá tó wà ní òkè òkun: kí  á má ṣe gbára lé ohunkóhun tí wọ́n bá mú lé wa lọ́wọ́ ní ìlú tí a bá wà o! Ìgbàkúgbà ni wọ́n lè gba nkan wọn!

Ẹ jẹ́ kí á káràmásìkí Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y, kí á ṣe ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba-Adelé wa; kí á sì múra sílẹ̀ láti ṣe àjọyọ̀ ìtúsílẹ̀ tí Olódùmarè ti fún wa, nígbàtí àkókò bá to.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!