ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

ÀṢẸ Èdùmàrè

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ńkan ló ń ṣẹlẹ̀ kí àwọn oúnjẹ àti ohun-èlò-ọbẹ̀ tí a ń rà ó tó dé ọ̀dọ̀ wa. A ò mọ èyí tí ó le mú aburú wá níbẹ̀ nítorí èyí, a níláti ṣọ́ra dáradára.

Obìnrin kan ni a gbọ́ wípé ó lọ sí ọjà láti lọ ra tòmátì; ṣe ló délé tán, tó ní kí òun bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ọbẹ̀, ló bá ríi pé, gbogbo tòmátì náà ni wọ́n ti gún ní nkan káàkiri.

Kíni wọ́n fi gun o, ṣé abẹ́rẹ́ ni? Eléyi ṣe wá ní kàyéfì. Èrèdí tí wọ́n fi gún tòmátì náà ní a kò mọ̀. Obìnrin yí ṣáà mọ̀ pé ọwọ́ ẹníkan tí a mọ irú wọn sí “àbókí” ni òun ti ràá. Ìgbà tó fi máa padà síbẹ̀, ṣe ni àbókí kàn ń kí gbé lásán, láìsọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. 

A mú ìròyìn yí wá sí etí ìgbọ́ ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá(Indigenous Yorùbá People IYP), kí a le máa ṣe àkíyèsí àwọn ohun tí a bá ń rà, pàápàá ní àkókò kúkurú tó kù báyi tí Olódùmarè máa bá wa sí ìdí àwọn agbésùnmọ̀mí, adúkokò-mọ́’ni, Nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa pátápátá.

Ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), kò sí àdàmọ̀dì ohunkóhun, ojúlówó irúgbìn àdáyébá ni D.R.Y f’ọwọ́ sí, àti ojúlówó oúnjẹ, pẹ̀lú èso, láìsí ìfòyà. Àwọn Nàìjíríà máa tó tẹ́ pẹ̀lú ìjẹgàba tí wọ́n ń ṣe lórí ilẹ̀ wa.

Kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olórun fún Ìyá wa, Ìyá-Ààfin Modupẹ́ Onítirí-Abiola, tí Olúwa lò láti yọ ilẹ̀ wa, D.R.Y kúrò nínú ìlú awáyé máṣerere Naijiria, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjì-lé-lógún, tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni wa, láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún. Ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, ibo ni à bá wà lónìí? 

No to LGBTQ in Yorubaland | No to Vaccines in the Democratic Republic of the Yoruba

Ìmọràn fún àwọn ìyálọ́jà àti àgbẹ̀ ni pé, kí wọ́n ṣọ́ra gidi fún ohun-ọ̀gbìn oko tí wón yóó máa rà fún títà àti gbígbìn fún àwọn ará-ìlú láti jẹ. Tòmátì la rí, tí wọ́n gún l’abẹ́rẹ́, àwọn ohun oúnjẹ erè-oko tó kù n kọ́? 

Enik’ẹni tí a bá ká irúgbìn ayédèrú mọ́ lọ́wọ́, kí á rántí pé ẹ̀sùn ìpànìyàn ni o.

Ìjọba afipá jẹgàba Nàìjíríà ,ẹ kúrò lórí àwọn ìpínlè wa méjèèje ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá DRY!

Ká Ìròyìn Síwájú sí: ỌGBỌ́N LÁTI FI OWÓ-ORÍ ṢE IBI FÚN ÁFRÍKÀ