A ta bàbà, a fowó-o bàbà ra baba
Ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, kò sí ojú-ìṣáájú o, bẹ́ẹ̀ ni kò sí kí á f’ọwọ́ ra ẹnikẹ́ni l’orí.
Ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti orí ẹ̀rọ ayélujára fi hàn gbangba pé ìkan nínú àwọn ọmọ bàbá wa MKO Abíọ́lá, ìyẹn Jamiu Abíọ́lá, tún ti bẹ̀rẹ̀ ìhùwàsí ọmọ-alè rẹ̀ o.
Ṣé a ò gbàgbé ní àkókò díẹ̀ s’ẹhìn báyi, tí Jámíù yí sọ ọ̀rọ̀ irọ́ gbáà, ọ̀rọ̀ àlùfànsá, nípa Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, opó bàbá wa Abíọ́lá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí Ìran Yorùbá.
Ìròhìn tí a tún wá gbọ́ báyi, ṣe àfihàn ibi ti Jamíu yí ti sọ pé Olódùmarè lọ́wọ́ nínú ìyà tí ó njẹ àwọn ará-ìlú Nàìjíríà, ìlú tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wá.
Ṣé ìyẹn kò tiẹ̀ kàn wá tí kìí bá nṣe jíjẹgàba tí Nàìjíríà njẹ gàba lórí ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ní àkókò yí, èyí tí ó mú kí ìyà tí Tinubú àti ìjọba Nàìjíríà wọn fi njẹ àwọn ará-ìlú Nàìjíríà, kí ó máa ta bá Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá àti Orílẹ̀-Èdè Yorùbá bákannáà.
Èyí túmọ̀ sí pé Jamiu, òpònú ọmọ yí, nsọ pé Ọ́lọ́run lọ́wọ́ sí ìyà tí ó njẹ ọmọ Yorùbá !
Àà, Jamiu, ti ẹ ti bá ẹ! Àṣé ẹni onínú-rere bí bàbá wa MKO Abíọ́lá le ṣèṣì bí òpònú àti adójútini ọmọ! Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè, ẹni tí ó gbé Olùgbàlà dìde fún wa – ìyá wa MOA, nípa Ìyá wa ni Ẹlẹ́da ti nṣiṣẹ́ ìdándè, tí ó sì ti ṣeé láṣepé, pẹ̀lú iràpadà ọmọ Yorùbá kúrò nínú oko ẹrú; nípa èyí tí a nṣe ìrántí Bàbá wa MKO lóni, ẹni tí ó ní ìfẹ́ ọmọ ènìyàn, tí ó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, pé kí ìyà kí ó má jẹ ará-ìlú; àti nípasẹ̀ èyí tí Màmá wa, MOA, fi rin ìrìn-àjò ìgbésí-ayé tí ó wá já sí Ìgbàlà fún ọmọ Yorùbá lóni ! A ò r’ohun f’ayọ̀ bí?
Ṣùgbọ́n ní ti alárùn ọpọlọ Jamiu yí, ẹni tí kò fi ìwà jọ bàbá rẹ̀, Ọlọ́rún ni ó ndán àwọn ènìyàn wò nípa ìyà tí Nàìjíríà dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn báyi !
Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikan, nínú ìròhìn náà, rán àwọn olùgbọ́ létí, pé, bẹ́ẹ̀ náà ni Jamiu sọ ní okòó-lé-l’ẹgbàá ọdún pé Buhari, ààrẹ ìlú Nàìjíríà nígbànáà, ní irúfẹ́ ìran àti àfojúsùn bí ti bàbá òun, MKO Abíọ́lá !! Hàà, ẹ gbà wá, ènìyàn! Irú ọ̀rọ̀ burúkú wo ni eléyi?
Èyí tí a kàn fẹ́ mú wá sí etí ìgbọ́ yín, ẹ̀yin Ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ni pé, ọmọ Àlè pọ̀ gidi, tí wọ́n npe’ra wọn ní ọmọ ọkọ! A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidi fún wọn.
Ẹ jẹ́ kí á máa rántí, nígbà gbogbo, pé Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí Ìran Yorùbá, Ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ni a ntẹ̀lé o, kí á sì fojú sí ibi tí Ìyá wa ní kí á kọ’jú sí; Ọlọ́run ò ní ṣe ẹni bíi Jamíù ayíradà yí ní ìkan nínú wa.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÀMERICA TI F’ỌWỌ́ SÍ ỌSIN ADÌẸ LÁTI YÀRÁ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀
- ẸGBẸ̀RÚN MÁRUN NÁÍRÀ NI ÀWỌN ARÁ ÌLÚ NÀÌJÍRÍÀ FI DA’LẸ̀ ARA WỌN !
- ÀNFÀÀNÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ
- ÒFÉGÈ ÌRÀNLỌ́WỌ́: ọmọ Yorùbá, máṣe yà sí’bẹ̀ !
- ỌMỌKÙNRIN KAN ṢE’KÚ PA BÀBÁ TÓ BÍ BÀBÁ RẸ̀ NÍTORÍ OKO
- JAMIU ABÍỌ́LÁ NHU ÌWÀ ỌMỌ ALÈ