Fatima ni orúkọ̀ ìyàwó Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sierra-Leone, ó dẹ̀ sọ pé gẹgẹbí Fatima ni òun ṣe sọ̀rọ̀, òun ò ṣe abẹnugan fún ìjọba Sierra-Leone, òun ò ti ẹ̀ ṣe abẹnugan fún bàálé òun pàápàá, ààrẹ Sierra Leone, ó ní ṣùgbọ́n lórúkọ ara òun ni òun fi nṣọọ́ o, pé, irúfẹ́ òbítíbitì àlùmọ́nì ilẹ̀ tí àwọn ni, ní orílẹ̀-èdè Sierra-Leone, kò yẹ kí á rí ẹyọ ẹnikan ṣoṣo tí ó máa jẹ́ tálákà láarin wọn!

O ní, ṣùgbọ́n, nṣe ni àwọn òyìnbó amúnisìn di àwọn lọ́wọ́ mú, tí wọn ò fi àyè gba àwọn láti ṣe àkóso àlùmọ́nì ilẹ̀ wọn!

Ó ní, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, gbogbo ilé-iṣẹ́-ìwakùsà ní Sierra-Leone, ọwọ́ àwọn òyìnbó ló wà! – òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì, òyìnbó Amẹ́ríkà, òyìnbó Ṣáínà! Tí wọ́n bá wa kùsà ọ̀ún tán, ní bíi kí wọ́n kó ọgọ́run mílíọ̀nù dọ́là lọ sí ìlú wọn, tí ó sì jẹ́ pé bíi ẹgbẹ̀rún-mẹ́wa dọ́là ni wọ́n máa san fún Sierra-Leone!

Obìnrin yí sọ pé òun ò mọ ìdí tí àwọn fi nṣe àjọ̀dún òmìnira, nítorí àwọn ò ní òmìnira kankan. Ó ní ìdí dẹ̀ ni èyí, tí ilẹ̀ Áfríkà kò ṣe ní ìlọsíwájú.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Njẹ́ ènìyàn le gbọ́ irúfẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí obìnrin yí sọ, kí ó má rántí pé Oore gidi mà ni Olódùmarè ṣe fún Ìran Yorùbá, tí ó fi rán ìránṣẹ́ rẹ̀ sí wa, – Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, pé, ní déédé àsìkò yí, ní déédé ìgbà yí, kí a kúrò l’oko ẹrú; kí á kọ̀ láti máa sìn òyìnbó!

Ohun tí a ní tó wa íjẹ! Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, kúrò lórí ilẹ̀ wa!