Olódùmarè bùkún Orílẹ̀-èdè Zimbabwe púpọ̀ nípasẹ̀ ètò ọ̀gbìn,tí àwọn ènìyàn wọn sì ń jẹ àjẹyó àti àjẹsẹ́kù, débi wípé wọ́n ń tà sí ilẹ̀ òkèèrè, ṣùgbọ́n àwọn amùnisìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí mú irúgbìn ayédèrù wa sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn èso tí kò dára rárá fún àgọ́ ara ènìyàn, àwọn irúgbìn náà léwu fún ilẹ̀, èròngbà wọn ni láti pa ìran adúláwọ̀ run ní gbogbo ọ̀nà, kí gbogbo ilẹ̀ Áfríkà pẹ̀lú àwọn àlùmọ́ọ́nì tí Olódùmarè fún wa bàa leè di ti àwọn aláwọ̀ funfun yí níkan.

Àwọn irúgbìn tí àwọn ènìyàn búburú yii kó wá sí Áfríkà kò le hu ju ìgbà kan lọ, bẹ́ẹ̀ni irúgbìn àbáláyé kò leè hù mọ́ lórí ilẹ̀ tí wọ́n tí gbin ayédèrù sí, ó wá di dandan kí àwọn àgbẹ̀ lọ máa fi owó gọbọi ra irúgbìn míràn lọ́wọ́ àwọn amúnisìn yí, ní àfikún, irugbin náà tún nsọ ilẹ̀ náà di aṣálẹ̀, àpapọ̀ èyí ni o ṣe okùnfà àìsí oúnjẹ, oríṣìríṣì aìsàn, pẹ̀lú ikú àìt’ọ́jọ́ ní orílẹ̀ èdè Zimbabwe báyìí.

Ọpẹ́ ni fún Olódùmarè tí Ó ṣiṣẹ́ itú sílẹ̀ fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nípa lílo màmá wa olóríire, ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla láti gba  wa kúrò lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá-ọdún ó-lé-méjìlélógún, tí a sì bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún nígbàtí a búra wọlé fún bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ gẹ́gẹ́bí olórí ìjọba Adelé wá.

Àlàkalẹ ètò ìṣèjobà Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá tí Ọlọ́run gbé lé màmá wa lọ́wọ́ kò ní fi ààyè gba irú ìwà ìbàjẹ̀ àti àrékérekè bí irú èyí ní orílẹ̀-èdè wa.

Àlàkalẹ ètò ìṣèjobà wa yóò ṣe àtìlẹ́yìn gidi fún àwọn àgbẹ̀, òfin D.R.Y kò sì ní fí ààyè silẹ̀ fún ohun tí ó leè ṣe ìpalára fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), láti wọlé sí Orílẹ̀-Èdè wa.

Ní kété tí àwọn Adelè wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa ní a ó bẹ̀rẹ̀ síí jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ̀ tí àwọn ìjọba Adelé wa tí nṣe láti ọjọ́ yi wá.

Ọjọ́ náà kò pẹ́ mọ́, nítorí Olódùmarè yóò bá wa lé àwọn ìkà agbèsùnmọ̀mí Naijiria tó ńjẹgàba lórí ilẹ̀ wa kúrò,òjò ẹ̀sín wọn ti sú, ó sì máa tó rọ̀ láìpẹ́.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!