Ilé ìfowópamọ́ àgbáyé ṣá ti gbọ́ wípé àwa Í.Y.P. (Indigenous Yorùbá People) kò sí ní ara Nàìjíríà mọ́ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹ́rin ẹgbàá ọdún ó-lé-mẹ́rin-lé-logún, nítorí gbogbo àgbáyé ló ti gbọ́, kí wọ́n tó máa fún Engr. Makinde ní owó tí ó bèèrè fún láti fi ṣe àtúnṣe àwọn ilé ẹ̀kọ́ káàkiri Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́! 

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

ÌWỌ̀N ẸRÙ TÍ O BÁ LÈ GBÉ NI KÍ O DÌ, ìwọ ENGR. MAKINDE

Àlùwàlà ológbò, ọgbọ́n àti k’ẹran jẹ́ ni. 

Ọjọ́ wo ló tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà? Àwa ọmọ IYP ti orílẹ̀-èdè DRY kò rán an ní’sẹ́ o. Ilé onílé tí ó fẹ́ tún ṣe láì gba ṣẹ lọ́wọ́ onílé, iye gbèsè tí o bá lè san ni kí o jẹ o.

Àwọn Ìròyìn Tun-tun: