Láìsí àní-àní, arungún àti amúnisìn pátápátá gbáà ni àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń fi agídí jẹgàba lórí Orílẹ̀-Èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba.

Nínú ìròyìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti rí ọkàn lára àwọn aláyé bàjẹ́ yí, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Matawallen ní ibùdó àwọn ọmọ ológun kan ní ìlú wọn lọ́hùn-ún, níbẹ̀ ni àwọn ọmọ ológun náà sì ti ń ká’wọ́ sókè tí wọ́n sì ń sọ pé bàbá a wà níbí, a wà níbí bàbá. Ń ṣe ni Matawallen wọ inú ọkọ̀ rẹ̀ tí ó sì kó owó tí ó pọ̀ níye jáde fún àwọn ọmọ ológun náà.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. pín sórí àgbàgbé ti X (Twitter)

Ẹ wo bí àwọn olè yí ṣe ń ṣe owó tí ó yẹ kí wọ́n fún àwọn ará ìlú tí ìyà ńjẹ, àwọn òṣìṣẹ́ kò tíì rí owo oṣù gbà, ọ̀pọ̀ ń kú láìtọ́jọ́ nítorí àìríjẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ti kú látàrí àìrí owó san ní ilé ìwòsàn, àwọn ọ̀dọ́ àti èwe tí kò lóǹkà ni ó wà ní ojú pópó tí wọ́n ń sùn kiri bí ẹyẹ láìsí ìrètí ọjọ́ ọ̀la tí ó dára, gbogbo ohun tí àwọn ará ìlú ń làkọjá kò kan àwọn ajẹnirun wọ̀nyí, níwọ̀n ìgbà tí àwọn àti ẹbí wọn bá sáà ti ń gbé ní ìrọ̀rùn.

Wọ́n ti wá rí ara wọn bíi Olódùmarè tí a gbọ́dọ̀ máa wárìrì fún, ìdí nìyí tí wọn kò fi lèè ṣe dáadáa fún àwọn ará ìlú wọn, ipò ẹrú ni wọ́n fi gbogbo wọn sì tí àwọn sì ń jayé ọlọ́ba.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ṣé ẹ ti ríi ara àwọn ǹkan tí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla máa ń sọ fún wa wípé, ní ìsèjọba Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹnikẹ́ni kò ní káwọ́ sókè fún ẹnikẹ́ni, nítorí wípé gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni a ó rí ògo wa lò, tí ẹnìkan kò sì ní ṣe ẹrú fún ẹlòmíràn nítorí pé ọmọ aládé ni gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, gbogbo wa sì ni adé wà lórí wa.

Nítorínáà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ láti fọwọsowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé wa láti àkókò yí lọ, kí àwọn ìgbádùn wọ̀nyí lè bẹ̀rẹ̀ síi tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní kété tí àwọn Adelè wa bá ti wọ oriko ìṣèjọba wa láìpẹ́ jọjọ.

Nítorí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla pẹlú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn Adelé wa ń gbé àwọn ìgbésẹ tí ó lágbára ní àgbáyé láti lé àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kúrò lórí ilẹ̀ wa, kí àwọn ìjọba wa sì bọ́ sípò láti tẹ̀síwájú iṣẹ́ fún àwa ọmọ Aládé.