Ọkùnrin òyìnbó kan fi àìdùnnú rẹ̀ hàn nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára covid 19, ó wí pé, ìdí tí àwọn ìjọba wọn fi mú àwọn ènìyàn ni dandan láti gba abẹ́rẹ́ ọ̀hún kò yé òun rárá nítorí pé kò sí iṣẹ́ kankan tí ó ṣe láti dènà àìsàn náà.
Ó tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, gẹ́gẹ́ bí òun náà ti ṣe jẹ́ oníṣègùn òyìnbó, kò sí ìwúlò kankan tí abẹ́rẹ́ náà ni, àfi oríṣiríṣi àìsàn tó ń fà sí àgọ́ ara, ṣùgbọ́n àwọn ìjọba lo ọgbọ́n àrékérekè pẹ̀lú ẹ̀rù láti fi dandan mú ará ìlú gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà.
Bí ẹnikẹ́ni bá gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ tako ìgbésẹ̀ náà, wọ́n á dún ‘kokò mọ pé yíò pàdánù iṣẹ́ rẹ̀, ọkùnrin náà rí ọ̀rọ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára covid gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbàjẹ́ láàrín àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ìpoògùn àti àwọn ìjọba.
Nítorí náà àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ẹ jẹ́ kí a kíyèsára gidigidi, kí a má ṣe gba abẹ́rẹ́ àjẹsára kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni kí a ṣọ́ra fún oògùn lílò, ìránṣẹ́ ikú ni àwọn amúnisìn wọ̀nyí, àwọn olóṣèlú káàkiri ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ni wọ́n ńlò láti ṣe iṣẹ́ náà, ọ̀nà láti dín iye àwọn ènìyàn tó wà ní àgbáyé kù ni, pàápàá àwa aláwọ̀ dúdú.
Ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹlẹ́dàá àwa ìran Yorùbá tó kó wa yọ nínú ewú, nípa bí ó ṣe lo màmá wa alálùbáríkà, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla láti gba òmìnira kúrò nínú ìlú agbèsùnmọ̀mí Naijiria ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun, a sì ti di orílẹ̀ èdè aṣèjọba ara ẹni nígbà tí a ti búra wọle fún olórí ìjọba Adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, fún ìdí èyí, àwa Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y) ti ní àgbàrá láti kọ ohun tí ó lè fa ìpalára fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, màmá wa ti jẹ́ kí a lóyè pé a máa lo ewé àti egbò wa náà fún ìtọ́jú ará wa, a ó sì máa ṣe àyẹ̀wò dáradára sí gbogbo òògùn tàbí abẹ́rẹ́ kí àwọn ènìyàn wa tó lò wọ́n, ní kété tí a bá ti lé àwọn àjẹgaba ìjọba agbésùnmọ̀mí Naijiria kúrò lórí ilẹ̀ wa, tí àwọn Adelè wá bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa ni àwọn ìgbésẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ láì fi àkókò ṣòfò rárá.
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- ÀBÁMỌ̀ NÍÍ GBẸ̀YÌN Ọ̀RÀN
- AGBÉRAGA T’Ó PE’RA RẸ̀ L’Ọ́BA
- ORÍLẸ̀ ÈDÈ BURUNDI LÙGBÀDÌ ÀÀRÙN MONKEY POX
- ÀWỌN OLÓṢÈLÚ NÀÌJÍRÍÀ ONÍMỌ̀T’ARA ẸNI NÌKAN
- SÁTẸ́LÁÌTÌ PẸ̀LÚ 5G, Ọ̀KAN LÁRA IRIN IṢẸ́ BILL GATES NI