Ààrẹ ìlú Burkina Faso, Akọgun Ibrahim Traore, sọ pé láti ọdún mẹ́ta-lé-lọgọ́ta tí orílẹ̀-èdè àwọn ti ngba “ìrànlọ́wọ́” láti ọ̀dọ̀ àwọn Faransé, kò sí ìdàgbàsókè kankan tí ó mú bá wọn; nítorí èyí, ó ní àwọn ò lè kú tí àwọn ò bá gba ìrànlọ́wọ́ Faransé mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, nṣe ló máa jẹ́ kí àwọn ó ṣiṣẹ́ láti yí ohun padà sí rere ní ìlú wọn.
Ọ̀rọ̀ akọni ni eléyi jẹ́; ẹni tí kò bá dájú àwọn òyìnbó amúnisìn máa jìyà kú lábẹ́ wọn ni. Kò sí ẹni tí ó fi òyìnbó ṣe ọ̀gá àgbáyé.
Àwọn tí wọ́n gbọ́ nkan tí Màmá wa nsọ, Ìránṣẹ́ Olódùmarè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí wọ́n dẹ̀ tí bẹ̀rẹ̀ sí mu lò, wọ́n ti ngba ara wọn sílẹ̀; mélo-mélo ni àwa, ní kété tí a bá ti gbé iṣẹ́ ìjọba wọ’nú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba náà káàkiri ìpínlẹ̀ wa méjèèje, àrà merírí ni ó máa jẹ́: gẹ́gẹ́bí a ti gbọ́ tẹ́lẹ̀, àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ba nkan jẹ́ débi pé, kò sí nkankan nílẹ̀; a ṣìṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti ilẹ̀ ni; nítorí èyí, a máa ṣiṣẹ́ gidi, ṣùgbọ́n a ti mọ̀ pé gbogbo èrè ẹ̀, ti Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ni, fún orílẹ̀-èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Ká Ìròyìn Síwájú sí:
- Ìbálòpọ̀ Ọkùnrin-S’ọkùnrin, Rárá O!!
- ỌMỌ-ẸGBẸ́ APC NI ÒPÒNÚ ÌGBÒ ÀNÁ
- Òyìnbó Njowú Ìṣẹ̀dá Aláwọ̀dúdú
- Ewu Tí Ó Wà Nínú Oúnjẹ Irúgbìn Tí A Ti Yípadà Yàtọ̀ Sí Oúnjẹ Irúgbìn Àbáláyé.
- Ọlọ́pa Nàìjíríà Dójúti Orílẹ̀-Èdè Wọn!
- Wọ́n Ṣe Àwárí Òkúta Amúnáwá Lórílẹ̀ Èdè Congo